Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run Fún 1998
Àwọn Ìtọ́ni
Ní 1998, àwọn ohun tí ó tẹ̀ lé e yìí ni yóò jẹ́ ìṣètò fún dídarí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run.
ÀWỌN ÌWÉ ÌKẸ́KỌ̀Ọ́: Bíbélì, Ilé Ìṣọ́ [w-YR], Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun [kl-YR], Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé [fy-YR], àti Awọn Akori Ọrọ Bibeli fun Ijiroro [td-YR] ni àwọn ibi tí a óò gbé iṣẹ́ àyànfúnni kà.
A gbọ́dọ̀ bẹ̀rẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ náà LÁKÒÓKÒ, pẹ̀lú orin, àdúrà, àti àwọn ọ̀rọ̀ ìkíni káàbọ̀, kí a sì tẹ̀ síwájú gẹ́gẹ́ bí ó ṣe tẹ̀ lé e yìí:
IṢẸ́ ÀYÀNFÚNNI NO. 1: Ìṣẹ́jú 15. Alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ni kí ó bójú tó èyí, a óò sì gbé e ka Ilé Ìṣọ́. Kí a ṣe iṣẹ́ àyànfúnni yìí gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ìtọ́ni oníṣẹ̀ẹ́jú 15, láìsí àtúnyẹ̀wò aláfẹnusọ. Ète rẹ̀ kò gbọ́dọ̀ jẹ́ láti wulẹ̀ kárí ibi tí a yàn fúnni, bí kò ṣe láti pa àfiyèsí pọ̀ sórí ìwúlò gbígbéṣẹ́ tí ó wà nínú ìsọfúnni tí a ń jíròrò, ní títẹnu mọ́ ohun tí yóò ṣe ìjọ láǹfààní jù lọ. Níbi tí a kò bá ti yan ẹṣin ọ̀rọ̀, kí a yan ọ̀kan.
Àwọn arákùnrin tí a yan ọ̀rọ̀ àsọyé yìí fún ní láti ṣọ́ra láti má ṣe kọjá àkókò tí a fún wọn. A lè fúnni ní ìmọ̀ràn ìdákọ́ńkọ́ bí ó bá pọn dandan tàbí bí olùbánisọ̀rọ̀ náà bá béèrè fún un.
ÀWỌN KÓKÓ PÀTÀKÌ LÁTI INÚ BÍBÉLÌ KÍKÀ: Ìṣẹ́jú 6. Èyí ni kí a bójú tó láti ọwọ́ alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí yóò mú àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ náà bá àwọn àìní àdúgbò mu lọ́nà tí ó gbéṣẹ́. Èyí kò ní wulẹ̀ jẹ́ àkópọ̀ lórí ibi tí a yàn fún kíkà. A lè fi ṣíṣe àtúnyẹ̀wò gbogbo orí tí a yàn fúnni láàárín ààbọ̀ ìṣẹ́jú sí ìṣẹ́jú kan kún un. Bí ó ti wù kí ó rí, olórí ète náà ni láti ran àwùjọ lọ́wọ́ láti lóye ìdí tí ìsọfúnni náà fi ṣeyebíye fún wa àti bí ó ti ṣeyebíye tó fún wa. Lẹ́yìn náà, alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò yọ̀ǹda àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ láti lọ sí kíláàsì wọn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.
IṢẸ́ ÀYÀNFÚNNI NO. 2: Ìṣẹ́jú 5. Èyí jẹ́ Bíbélì kíkà lórí ibi tí a yàn fúnni tí arákùnrin kan yóò bójú tó. Èyí yóò rí bẹ́ẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ kìíní àti ní àwọn àwùjọ yòó kù tí ó jẹ́ àfikún. Ìwé kíkà tí a yàn fúnni sábà máa ń mọ níwọ̀n láti yọ̀ǹda fún akẹ́kọ̀ọ́ náà láti ṣe àlàyé ṣókí ní ìbẹ̀rẹ̀ àti ní ìparí ọ̀rọ̀ rẹ̀. A lè fi ìtàn tí ó yí àwọn ẹsẹ náà ká, ìjẹ́pàtàkì àsọtẹ́lẹ̀ tàbí ẹ̀kọ́ inú rẹ̀, àti bí àwọn ìlànà rẹ̀ ṣe kàn wá kún un. A gbọ́dọ̀ ka gbogbo ẹsẹ tí a yàn fúnni pátá, láìdánudúró lágbede méjì. Àmọ́ ṣáá o, níbi tí àwọn ẹsẹ tí a óò kà kò bá ti tẹ̀ léra, akẹ́kọ̀ọ́ náà lè sọ ẹsẹ tí ó ti ń bá kíkà náà lọ.
IṢẸ́ ÀYÀNFÚNNI NO. 3: Ìṣẹ́jú 5. Arábìnrin ni a óò yan èyí fún. A óò gbé kókó ẹ̀kọ́ iṣẹ́ yìí ka ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé, tàbí Awọn Akori Ọrọ Bibeli fun Ijiroro. A lè gbé e kalẹ̀ lọ́nà ìjẹ́rìí aláìjẹ́-bí-àṣà, ìpadàbẹ̀wò tàbí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé, àwọn tí ń kópa sì lè jókòó tàbí kí wọ́n dúró. Ọ̀nà tí akẹ́kọ̀ọ́ gbà ran onílé lọ́wọ́ láti ronú lórí àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀, kí ó sì lóye rẹ̀, àti bí ó ṣe lo àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ni yóò jẹ alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ lọ́kàn jù lọ. Akẹ́kọ̀ọ́ tí a yan iṣẹ́ yìí fún gbọ́dọ̀ mọ̀wéékà. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò ṣètò fún olùrànlọ́wọ́ kan ṣoṣo, ṣùgbọ́n a lè lo olùrànlọ́wọ́ mìíràn ní àfikún. Akẹ́kọ̀ọ́ náà lè pinnu bóyá òun yóò jẹ́ kí onílé ka àwọn ìpínrọ̀ kan nínú ìwé náà, tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́ nígbà tí ó bá ń ṣàgbéyẹ̀wò ìwé Ìmọ̀ tàbí Ayọ̀ Ìdílé. Ọ̀nà tí ó gbéṣẹ́ tí a gbà lo àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ ni kí a fún ní àfiyèsí pàtàkì, kì í ṣe ọ̀nà tí a gbà gbé e kalẹ̀.
IṢẸ́ ÀYÀNFÚNNI NO. 4: Ìṣẹ́jú 5. Nígbà tí a bá gbé iṣẹ́ àyànfúnni yìí karí Awọn Akori Ọrọ Bibeli fun Ijiroro, a óò yàn án fún arákùnrin tàbí arábìnrin. Nígbà tí a bá gbé e karí Ayọ̀ Ìdílé, a óò yàn án fún arákùnrin. Fún iṣẹ́ àyànfúnni kọ̀ọ̀kan a ti pèsè ẹṣin ọ̀rọ̀ sínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ yìí. Nígbà tí a bá yàn án fún arákùnrin, kí ó sọ ọ́ ní ọ̀rọ̀ àsọyé fún gbogbo àwùjọ pátá. Yóò dára jù lọ lọ́pọ̀ ìgbà bí arákùnrin náà bá múra ọ̀rọ̀ àsọyé rẹ̀ sílẹ̀ ní níní àwùjọ inú Gbọ̀ngàn Ìjọba lọ́kàn, kí ó baà lè kún fún ẹ̀kọ́ ní tòótọ́, kí ó sì ṣe àwọn tí ń gbọ́ ọ láǹfààní ní ti gidi.
*ÀFIKÚN ÌTÒLẸ́SẸẸSẸ BÍBÉLÌ KÍKÀ: A fi èyí sínú àwọn àkámọ́ lẹ́yìn nọ́ńbà orin fún ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan. Nípa títẹ̀ lé ìtòlẹ́sẹẹsẹ yìí, ní kíka nǹkan bí ojú ìwé mẹ́wàá lọ́sẹ̀, a lè ka Bíbélì látòkè délẹ̀ ní ọdún mẹ́ta. A kò gbé apá kankan nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ilé ẹ̀kọ́ tàbí àtúnyẹ̀wò alákọsílẹ̀ karí àfikún ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìwé kíkà yí.
Ọ̀RỌ̀ ÀKÍYÈSÍ: Fún àfikún ìsọfúnni àti ìtọ́ni lórí ìmọ̀ràn, ìdíwọ̀n àkókò, àtúnyẹ̀wò alákọsílẹ̀, àti mímúra àwọn iṣẹ́ àyànfúnni sílẹ̀, jọ̀wọ́ wo ojú ìwé 3 nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti October 1996.
ÌTÒLẸ́SẸẸSẸ
Jan. 5 Bíbélì kíkà: Ìṣe 7 àti 8
Orin 162 [*Jẹ́nẹ́sísì 1 sí 9]
No. 1: ‘Fífi Ọwọ́ Títọ̀nà Mú Ọ̀rọ̀ Òtítọ́’ (w96-YR 1/1 ojú ìwé 29 sí 31)
No. 2: Ìṣe 7:44-60
No. 3: Máa Ṣègbọràn sí Aláṣẹ Onípò Àjùlọ Nígbà Gbogbo (kl-YR ojú ìwé 130 àti 131 ìpínrọ̀ 1 sí 6)
No. 4: td-YR 47B Jésù Jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run àti Ọba Tí A Yàn
Jan. 12 Bíbélì kíkà: Ìṣe 9 àti 10
Orin 14 [*Jẹ́nẹ́sísì 10 sí 18]
No. 1: Jẹ́ Onígboyà Olùpòkìkí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run (w96-YR 1/15 ojú ìwé 24 àti 25)
No. 2: Ìṣe 9:1-16
No. 3: Wà Lábẹ́ Àwọn Aláṣẹ Onípò Gíga (kl-YR ojú ìwé 131 sí 133 ìpínrọ̀ 7 sí 10)
No. 4: td-YR 47D Ìdí Tí A Fi Gbọ́dọ̀ Ní Ìgbàgbọ́ Nínú Jésù Kristi
Jan. 19 Bíbélì kíkà: Ìṣe 11 sí 13
Orin 187 [*Jẹ́nẹ́sísì 19 sí 24]
No. 1: Wò Kọjá Ohun Tí O Rí! (w96-YR 2/15 ojú ìwé 27 sí 29)
No. 2: Ìṣe 13:1-12
No. 3: Fi Ìmọrírì Hàn fún Ìṣètò Ọlọ́run fún Ọlá Àṣẹ Nínú Ìdílé (kl-YR ojú ìwé 134 sí 136 ìpínrọ̀ 11 sí 18)
No. 4: td-YR 47E Àwọn Iṣẹ́ Gbọ́dọ̀ Bá Ìgbàgbọ́ Nínú Kristi Rìn
Jan. 26 Bíbélì kíkà: Ìṣe 14 sí 16
Orin 163 [*Jẹ́nẹ́sísì 25 sí 30]
No. 1: Gbígbé ní Ìbámu Pẹ̀lú Ẹ̀jẹ́ Ìgbéyàwó Rẹ (w96-YR 3/1 ojú ìwé 19 sí 22)
No. 2: Ìṣe 16:1-15
No. 3: Ọlá Àṣẹ Nínú Ìjọ—Ìpèsè Onífẹ̀ẹ́ Láti Ọ̀dọ̀ Jèhófà (kl-YR ojú ìwé 137 sí 139 ìpínrọ̀ 19 sí 25)
No. 4: td-YR 24B Ohun Tí Ìjọba Ọlọ́run Yóò Ṣe fún Aráyé
Feb. 2 Bíbélì kíkà: Ìṣe 17 sí 19
Orin 97 [*Jẹ́nẹ́sísì 31 sí 36]
No. 1: Jèhófà—Olùfẹ́ Òdodo àti Ìdájọ́ Òdodo (w96-YR 3/15 ojú ìwé 21 sí 23)
No. 2: Ìṣe 18:1-11
No. 3: Bí Ìdúróṣinṣin Ṣe Ń Fi Kún Ìgbéyàwó Aláyọ̀ (kl-YR ojú ìwé 140 àti 141 ìpínrọ̀ 1 sí 6)
No. 4: td-YR 24C Ìṣàkóso Ìjọba Bẹ̀rẹ̀ Nígbà Tí Àwọn Ọ̀tá Kristi Ṣì Ń Gbéṣẹ́ Ṣe
Feb. 9 Bíbélì kíkà: Ìṣe 20 àti 21
Orin 103 [*Jẹ́nẹ́sísì 37 sí 42]
No. 1: Máa Kó Ẹrù Ìnira Rẹ Sára Jehofa Nígbà Gbogbo (w96-YR 4/1 ojú ìwé 27 sí 30)
No. 2: Ìṣe 21:1-14
No. 3: Ipa Ṣíṣe Kókó Tí Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ Ń Kó Nínú Ìgbéyàwó (kl-YR ojú ìwé 142 àti 143 ìpínrọ̀ 7 sí 9)
No. 4: td-YR 24E Ìjọba Ọlọ́run Kì Yóò Wá Nípasẹ̀ Àwọn Ìsapá Ènìyàn
Feb. 16 Bíbélì kíkà: Ìṣe 22 sí 24
Orin 107 [*Jẹ́nẹ́sísì 43 sí 49]
No. 1: “Ìgba Dídákẹ́, àti Ìgba Fífọhùn” (w96-YR 5/15 ojú ìwé 21 sí 23)
No. 2: Ìṣe 22:1-16
No. 3: Fi Ọlá àti Ọ̀wọ̀ Hàn fún Alábàáṣègbéyàwó Rẹ (kl-YR ojú ìwé 143 àti 144 ìpínrọ̀ 10 sí 14)
No. 4: td-YR 52A Ohun Tí “Òpin Ayé” Túmọ̀ Sí Ní Ti Gidi
Feb. 23 Bíbélì kíkà: Ìṣe 25 àti 26
Orin 89 [*Jẹ́nẹ́sísì 50 sí Ẹ́kísódù 7]
No. 1: Kí Ni Ó Túmọ̀ Sí Láti Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run? (w96-YR 6/15 ojú ìwé 4 sí 7)
No. 2: Ìṣe 25:1-12
No. 3: Fi Àpẹẹrẹ Rere Lélẹ̀ Kí O sì Fi Ìfẹ́ Hàn sí Àwọn Ọmọ Rẹ (kl-YR ojú ìwé 145 sí 146 ìpínrọ̀ 15 sí 18)
No. 4: td-YR 52B Wà Lójúfò sí Ẹ̀rí Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn
Mar. 2 Bíbélì kíkà: Ìṣe 27 àti 28
Orin 92 [*Ẹ́kísódù 8 sí 13]
No. 1: w90-YR 5/15 ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 1 sí 4 (àti àwọn àpótí tí ó wà ní ojú ìwé 25 àti 26.)
No. 2: Ìṣe 27:33-44
No. 3: Ohun Tí Ìbáwí Onífẹ̀ẹ́ àti Ìgbìmọ̀ Ọgbọ́n Lè Ṣàṣeparí (kl-YR ojú ìwé 148 àti 149 ìpínrọ̀ 19 sí 23)
No. 4: td-YR 44B Ọlọ́run Ṣèlérí Ìyè Àìnípẹ̀kun fún Aráyé Onígbọràn
Mar. 9 Bíbélì kíkà: Róòmù 1 sí 3
Orin 79 [*Ẹ́kísódù 14 sí 20]
No. 1: w90-YR 8/1 ojú ìwé 23 àti 24 ìpínrọ̀ 3
No. 2: Róòmù 1:18-32
No. 3: Ìdí Tí A Fi Fẹ́ Láti Sún Mọ́ Ọlọ́run (kl-YR ojú ìwé 150 sí 152 ìpínrọ̀ 1 sí 5)
No. 4: td-YR 44D Kì í Ṣe Gbogbo Ènìyàn Ni Yóò Lọ Sí Ọ̀run
Mar. 16 Bíbélì kíkà: Róòmù 4 sí 6
Orin 36 [*Ẹ́kísódù 21 sí 27]
No. 1: “Ẹ Máa Mọyì Irú Àwọn Ènìyàn Bẹ́ẹ̀” (w96-YR 6/15 ojú ìwé 28 sí 30)
No. 2: Róòmù 4:1-15
No. 3: Àwọn Ohun Tí A Béèrè fún Láti Sún Mọ́ Ọlọ́run (kl-YR ojú ìwé 152 àti 153 ìpínrọ̀ 6 sí 9)
No. 4: td-YR 44E Ìyè Àìnípẹ̀kun Ni A Ṣèlérí fún Àìníye Àwọn “Àgùntàn Mìíràn”
Mar. 23 Bíbélì kíkà: Róòmù 7 sí 9
Orin 84 [*Ẹ́kísódù 28 sí 33]
No. 1: Ohun Tí Àwọn Ẹ̀dá “Tí Wọ́n Gbọ́n Lọ́nà Ìtẹ̀sí Ìwà Àdánidá” Lè Kọ́ Wa (w96-YR 7/15 ojú ìwé 21 sí 23)
No. 2: Róòmù 9:1-18
No. 3: Bá Ọlọ́run Sọ̀rọ̀ Kí Ó sì Gbọ́ (kl-YR ojú ìwé 154 àti 155 ìpínrọ̀ 10 sí 14)
No. 4: td-YR 22B Ìdè Ìgbéyàwó Ni A Gbọ́dọ̀ Pa Mọ́ Ní Ọlọ́lá
Mar. 30 Bíbélì kíkà: Róòmù 10 sí 12
Orin 165 [*Ẹ́kísódù 34 sí 39]
No. 1: Àwọn Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n Láti Ilẹ̀ Ìlérí (w96-YR 8/15 ojú ìwé 4 sí 8)
No. 2: Róòmù 10:1-15
No. 3: Máa Forítì Nínú Àdúrà Kí O sì Fetí Sílẹ̀ (kl-YR ojú ìwé 156 sí 159 ìpínrọ̀ 15 sí 20)
No. 4: td-YR 22C Ìlànà Ipò Orí Ni Àwọn Kristẹni Ní Láti Bọ̀wọ̀ Fún
Apr. 6 Bíbélì kíkà: Róòmù 13 sí 16
Orin 175 [*Ẹ́kísódù 40 sí Léfítíkù 7]
No. 1: w90-YR 8/1 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 4 títí dé ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 3 (àti àwọn àpótí)
No. 2: Róòmù 13:1-10
No. 3: Rí Ààbò Tòótọ́ Láàárín Àwọn Ènìyàn Ọlọ́run (kl-YR ojú ìwé 160 àti 161 ìpínrọ̀ 1 sí 4)
No. 4: td-YR 22D Ẹrù Iṣẹ́ Àwọn Kristẹni Òbí sí Àwọn Ọmọ
Apr. 13 Bíbélì kíkà: Kọ́ríńtì Kíní 1 sí 3
Orin 173 [*Léfítíkù 8 sí 13]
No. 1: w90-YR 9/15 ojú ìwé 24 àti 25 ìpínrọ̀ 1 (yàtọ̀ sí àwọn àpótí)
No. 2: Kọ́ríńtì Kíní 1:10-25
No. 3: Bí Jèhófà Ṣe Ń Pèsè Oúnjẹ Tẹ̀mí (kl-YR ojú ìwé 162 àti 163 ìpínrọ̀ 5 sí 8)
No. 4: td-YR 22E Àwọn Kristẹni Gbọ́dọ̀ Fẹ́ Kìkì Àwọn Kristẹni Ẹlẹgbẹ́ Wọn
Apr. 20 Bíbélì kíkà: Kọ́ríńtì Kíní 4 sí 6
Orin 170 [*Léfítíkù 14 sí 19]
No. 1: Bíbélì Ha Fi Ìgbàgbọ́ Nínú Àyànmọ́ Kọ́ni Bí? (w96-YR 9/1 ojú ìwé 4 sí 7)
No. 2: Kọ́ríńtì Kíní 4:1-13
No. 3: Ohun Tí Ó Túmọ̀ Sí Láti Fi Ìfẹ́ Wọ Ara Wa Láṣọ (kl-YR ojú ìwé 163 sí 166 ìpínrọ̀ 9 sí 14)
No. 4: td-YR 22F Àwọn Kristẹni Tòótọ́ Kì í Ṣe Akóbìnrinjọ
Apr. 27 Àtúnyẹ̀wò Alákọsílẹ̀. Parí Ìṣe 7 sí Kọ́ríńtì Kíní 6
Orin 26 [*Léfítíkù 20 sí 25]
May 4 Bíbélì kíkà: Kọ́ríńtì Kíní 7 sí 9
Orin 152 [*Léfítíkù 26 sí Númérì 3]
No. 1: Ó Ha Yẹ Kí O Tọrọ Àforíjì Ní Tòótọ́ Bí? (w96-YR 9/15 ojú ìwé 22 sí 24)
No. 2: Kọ́ríńtì Kíní 7:10-24
No. 3: Ìjọ—Ibi Ààbò Kan (kl-YR ojú ìwé 167 sí 169 ìpínrọ̀ 15 sí 20)
No. 4: td-YR 26A Màríà Kì í Ṣe “Ìyá Ọlọ́run”
May 11 Bíbélì kíkà: Kọ́ríńtì Kíní 10 sí 12
Orin 185 [*Númérì 4 sí 9]
No. 1: Padà Di Erùpẹ̀—Báwo? (w96-YR 9/15 ojú ìwé 29 sí 31)
No. 2: Kọ́ríńtì Kíní 11:1-16
No. 3: Fara Wé Jésù—Sin Ọlọ́run Títí Láé (kl-YR ojú ìwé 170 àti 171 ìpínrọ̀ 1 sí 6)
No. 4: td-YR 26C Bíbélì Fi Hàn Pé Màríà Kì í Ṣe “Wúńdíá Títí Lọ”
May 18 Bíbélì kíkà: Kọ́ríńtì Kíní 13 àti 14
Orin 55 [*Númérì 10 sí 15]
No. 1: Ìpènijà Pípèsè fún Agbo Ilé Ẹni (w96-YR 10/1 ojú ìwé 29 sí 31)
No. 2: Kọ́ríńtì Kíní 14:1-12
No. 3: Àwọn Ìgbésẹ̀ Ṣíṣe Kókó Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè (kl-YR ojú ìwé 173 sí 175 ìpínrọ̀ 7 sí 9)
No. 4: td-YR 33A Ohun Tí Ìwé Mímọ́ Wí Nípa Ìṣe Ìrántí
May 25 Bíbélì kíkà: Kọ́ríńtì Kíní 15 àti 16
Orin 158 [*Númérì 16 sí 22]
No. 1: w90-YR 9/15 ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 2 sí 6 (àti àwọn àpótí tí ó wà ní ojú ìwé 24 àti 25)
No. 2: Kọ́ríńtì Kíní 16:1-13
No. 3: Ìdí Tí Batisí Fi Pọn Dandan (kl-YR ojú ìwé 175 àti 176 ìpínrọ̀ 10 sí 12)
No. 4: td-YR 33B Ayẹyẹ Máàsì Kò Bá Ìwé Mímọ́ Mu
June 1 Bíbélì kíkà: Kọ́ríńtì Kejì 1 sí 4
Orin 58 [*Númérì 23 sí 29]
No. 1: w90-YR 9/15 ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 1 (àti àpótí)
No. 2: Kọ́ríńtì Kejì 4:1-12
No. 3: Batisí—Ohun Tí Ó Ṣe Pàtàkì Jù Lọ Nínú Ìgbésí Ayé Rẹ (kl-YR ojú ìwé 176 àti 177 ìpínrọ̀ 13 sí 16)
No. 4: td-YR 7A Ìdí Tí A Fi Ń Ṣe Inúnibíni sí Àwọn Kristẹni Tòótọ́
June 8 Bíbélì kíkà: Kọ́ríńtì Kejì 5 sí 8
Orin 102 [*Númérì 30 sí 35]
No. 1: Ìwàláàyè Lẹ́yìn Ikú—Báwo, Níbo, Nígbà Wo? (w96-YR 10/15 ojú ìwé 4 sí 7)
No. 2: Kọ́ríńtì Kejì 7:1-13
No. 3: Ohun Tí Ó Túmọ̀ Sí Láti Gbé Ní Ìbámu Pẹ̀lú Ìyàsímímọ́ àti Batisí Rẹ (kl-YR ojú ìwé 178 sí 180 ìpínrọ̀ 17 sí 22)
No. 4: td-YR 7C Aya Kò Gbọ́dọ̀ Fi Àyè Sílẹ̀ fún Ọkọ Láti Ya Òun Nípa sí Ọlọ́run
June 15 Bíbélì kíkà: Kọ́ríńtì Kejì 9 sí 13
Orin 43 [*Númérì 36 sí Diutarónómì 4]
No. 1: w90-YR 9/15 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 1 sí 4 (àti àpótí)
No. 2: Kọ́ríńtì Kejì 10:1-12
No. 3: Múra Sílẹ̀ Nísinsìnyí fún “Ìyè Tòótọ́” (kl-YR ojú ìwé 181 àti 182 ìpínrọ̀ 1 sí 5)
No. 4: td-YR 7D Ọkọ Kò Gbọ́dọ̀ Jẹ́ Kí Aya Dí Òun Lọ́wọ́ Sísin Ọlọ́run
June 22 Bíbélì kíkà: Gálátíà 1 sí 3
Orin 127 [*Diutarónómì 5 sí 11]
No. 1: w90-YR 11/15 ojú ìwé 23 ìpínrọ̀ 1 sí 3
No. 2: Gálátíà 1:1-12
No. 3: Lẹ́yìn Amágẹ́dọ́nì—Párádísè Ilẹ̀ Ayé Kan (kl-YR ojú ìwé 182 sí 184 ìpínrọ̀ 6 sí 11)
No. 4: td-YR 1A Àwọn Àdúrà Tí Ọlọ́run Máa Ń Gbọ́
June 29 Bíbélì kíkà: Gálátíà 4 sí 6
Orin 98 [*Diutarónómì 12 sí 19]
No. 1: w90-YR 11/15 ojú ìwé 23 ìpínrọ̀ 4 sí 6 (àti àpótí)
No. 2: Gálátíà 6:1-18
No. 3: Àlàáfíà Níbi Gbogbo àti Àjíǹde Àwọn Òkú (kl-YR ojú ìwé 184 sí 187 ìpínrọ̀ 12 sí 18)
No. 4: td-YR 1C Ìdí Tí Àwọn Àdúrà Kan Kò Fi Lẹ́sẹ̀ Nílẹ̀
July 6 Bíbélì kíkà: Éfésù 1 sí 3
Orin 71 [*Diutarónómì 20 sí 27]
No. 1: w90-YR 11/15 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 1 sí 4
No. 2: Éfésù 1:1-14
No. 3: Ohun Tí Ìjẹ́pípé Yóò Túmọ̀ Sí, àti Bí A Ṣe Lè Gbádùn Rẹ̀ (kl-YR ojú ìwé 187 sí 191 ìpínrọ̀ 19 sí 25)
No. 4: td-YR 9A A Kò Yan Àyànmọ́ fún Ènìyàn
July 13 Bíbélì kíkà: Éfésù 4 sí 6
Orin 214 [*Diutarónómì 28 sí 32]
No. 1: w90-YR 11/15 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 5 sí 8 (àti àpótí)
No. 2: Éfésù 6:1-13
No. 3: td-YR 31A Ìwàláàyè Jésù Bí Ènìyàn Jẹ́ “Ìràpadà fún Gbogbo Ènìyàn”
No. 4: Ìdílé Wà Nínú Yánpọnyánrin (fy-YR ojú ìwé 1 sí 9 ìpínrọ̀ 1 sí 14)
July 20 Bíbélì kíkà: Fílípì 1 sí 4
Orin 123 [*Diutarónómì 33 sí Jóṣúà 6]
No. 1: w90-YR 11/15 ojú ìwé 25 (àti àpótí)
No. 2: Fílípì 1:1-14
No. 3: Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé (fy-YR ojú ìwé 10 sí 12 ìpínrọ̀ 15 sí 23)
No. 4: td-YR 31B Ìdí Tí Jésù Fi Lè San Ìràpadà Náà
July 27 Bíbélì kíkà: Kólósè 1 sí 4
Orin 64 [*Jóṣúà 7 sí 12]
No. 1: w90-YR 11/15 ojú ìwé 26 (àti àpótí)
No. 2: Kólósè 4:1-13
No. 3: td-YR 32A Bí A Ṣe Lè Dá Ìsìn Tòótọ́ Kan Ṣoṣo náà Mọ̀
No. 4: Ìwọ Ha Ti Múra Sílẹ̀ fún Ìgbéyàwó Bí? (fy-YR ojú ìwé 13 sí 15 ìpínrọ̀ 1 sí 6)
Aug. 3 Bíbélì kíkà: Tẹsalóníkà Kíní 1 sí 5
Orin 35 [*Jóṣúà 13 sí 19]
No. 1: w91-YR 1/15 ojú ìwé 22 (àti àpótí)
No. 2: Tẹsalóníkà Kíní 2:1-12
No. 3: Ìdí Tí Ó Fi Yẹ Kí O Mọ Ara Rẹ Kí O sì Ní Ojú Ìwòye Tòótọ́ (fy-YR ojú ìwé 16 sí 18 ìpínrọ̀ 7 sí 10)
No. 4: td-YR 32C Ó Ha Burú Láti Dẹ́bi fún Àwọn Ẹ̀kọ́ Èké Bí?
Aug. 10 Bíbélì kíkà: Tẹsalóníkà Kejì 1 sí 3
Orin 10 [*Jóṣúà 20 sí Àwọn Onídàájọ́ 1]
No. 1: w91-YR 1/15 ojú ìwé 23 (àti àpótí)
No. 2: Tẹsalóníkà Kejì 1:1-12
No. 3: td-YR 32E Ìgbà Tí Ọlọ́run Fọwọ́ Sí Yíyí Ẹ̀sìn Pa Dà
No. 4: Àwọn Ànímọ́ Tí Ó Yẹ Kí O Wá Lára Alábàáṣègbéyàwó Kan (fy-YR ojú ìwé 20 sí 22 ìpínrọ̀ 11 sí 15)
Aug. 17 Bíbélì kíkà: Tímótì Kíní 1 sí 3
Orin 221 [*Àwọn Onídàájọ́ 2 sí 7]
No. 1: w91-YR 1/15 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 1 sí 3
No. 2: Tímótì Kíní 1:3-16
No. 3: Àwọn Nǹkan Tí O Ní Láti Gbé Yẹ̀wò Kí O Tó Kó Wọnú Iṣẹ́ Àìgbọ́dọ̀máṣe Wíwà Pẹ́ Títí (fy-YR ojú ìwé 22 sí 24 ìpínrọ̀ 16 sí 19)
No. 4: td-YR 32G Ọlọ́run Ha Ń Rí Rere Nínú Gbogbo Ẹ̀sìn Bí?
Aug. 24 Bíbélì kíkà: Tímótì Kíní 4 sí 6
Orin 30 [*Àwọn Onídàájọ́ 8 sí 13]
No. 1: w91-YR 1/15 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 4 sí 8 (àti àpótí)
No. 2: Tímótì Kíní 4:1-16
No. 3: td-YR 3A Ta Ni A Óò Jí Dìde Kúrò Nínú Òkú?
No. 4: Ẹ Jẹ́ Kí Ìfẹ́sọ́nà Yín Lọ́lá, Kí Ẹ sì Wò Ré Kọjá Ọjọ́ Ìgbéyàwó (fy-YR ojú ìwé 24 sí 26 ìpínrọ̀ 20 sí 23)
Aug. 31 Àtúnyẹ̀wò Alákọsílẹ̀. Parí Kọ́ríńtì Kíní 7 sí Tímótì Kíní 6
Orin 59 [*Àwọn Onídàájọ́ 14 sí 19]
Sept. 7 Bíbélì kíkà: Tímótì Kejì 1 sí 4
Orin 46 [*Àwọn Onídàájọ́ 20 sí Rúùtù 4]
No. 1: w91-YR 1/15 ojú ìwé 31 (àti àpótí)
No. 2: Tímótì Kejì 3:1-13
No. 3: Àwọn Ìlànà Bíbélì Tí Ó Lè Ṣèrànwọ́ fún Ọ Láti Múra Sílẹ̀ fún Ìgbéyàwó Aláṣeyọrí (fy-YR ojú ìwé 26 àpótí àtúnyẹ̀wò)
No. 4: td-YR 3B Ibo Ni A Óò Jí Àwọn Òkú Dìde Sí?
Sept. 14 Bíbélì kíkà: Títù 1 sí Fílémónì
Orin 155 [*Sámúẹ́lì Kíní 1 sí 8]
No. 1: w91-YR 2/15 ojú ìwé 22 àti 23 (àti àwọn àpótí)
No. 2: Títù 3:1-14
No. 3: td-YR 29A Ìpadàbọ̀ Kristi Kò Ṣeé Fojú Rí
No. 4: Kọ́kọ́rọ́ Àkọ́kọ́ sí Ìgbéyàwó Wíwà Pẹ́ Títí (fy-YR ojú ìwé 27 sí 29 ìpínrọ̀ 1 sí 6)
Sept. 21 Bíbélì kíkà: Hébérù 1 sí 3
Orin 149 [*Sámúẹ́lì Kíní 9 sí 14]
No. 1: w91-YR 2/15 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 1 sí 6 (yàtọ̀ sí àpótí)
No. 2: Hébérù 3:1-15
No. 3: Kọ́kọ́rọ́ Kejì sí Ìgbéyàwó Wíwà Pẹ́ Títí (fy-YR ojú ìwé 30 àti 31 ìpínrọ̀ 7 sí 10)
No. 4: td-YR 29B Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Tí Ó Ṣeé Fojú Rí Ni A Fi Mọ Ìpadàbọ̀ Kristi
Sept. 28 Bíbélì kíkà: Hébérù 4 sí 7
Orin 51 [*Sámúẹ́lì Kíní 15 sí 19]
No. 1: Èé Ṣe Tí Ó Fi Yẹ Kí A Fún Jèhófà Ní Nǹkan? (w96-YR 11/1 ojú ìwé 28 sí 30)
No. 2: Hébérù 6:1-12
No. 3: td-YR 53A Àwọn Kristẹni Kò Sí Lábẹ́ Iṣẹ́ Àìgbọ́dọ̀máṣe Láti Pa Sábáàtì Mọ́
No. 4: Ipò Orí Ọkùnrin Gbọ́dọ̀ Dà Bíi Ti Kristi (fy-YR ojú ìwé 31 sí 33 ìpínrọ̀ 11 sí 15)
Oct. 5 Bíbélì kíkà: Hébérù 8 sí 10
Orin 143 [*Sámúẹ́lì Kíní 20 sí 25]
No. 1: Fara Wé Àìṣojúsàájú Jèhófà (w96-YR 11/15 ojú ìwé 25 sí 27)
No. 2: Hébérù 8:1-12
No. 3: Bí Aya Ṣe Lè Jẹ́ Àṣekún Ọkọ Rẹ̀ (fy-YR ojú ìwé 34 àti 35 ìpínrọ̀ 16 sí 19)
No. 4: td-YR 53B A Kò Fún Àwọn Kristẹni ní Òfin Sábáàtì
Oct. 12 Bíbélì kíkà: Hébérù 11 sí 13
Orin 108 [*Sámúẹ́lì Kíní 26 sí Sámúẹ́lì Kejì 2]
No. 1: w91-YR 2/15 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 7 (àti àpótí) títí dé ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 3
No. 2: Hébérù 11:1-10
No. 3: td-YR 53D Ìgbà Tí Sábáàtì Ìsinmi Ọlọ́run Bẹ̀rẹ̀ Tí Ó sì Dópin
No. 4: Ohun Tí Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ Dídán Mọ́rán Túmọ̀ Sí Ní Ti Gidi (fy-YR ojú ìwé 35 sí 38 ìpínrọ̀ 20 sí 26)
Oct. 19 Bíbélì kíkà: Jákọ́bù 1 sí 5
Orin 144 [*Sámúẹ́lì Kejì 3 sí 10]
No. 1: w91-YR 3/15 ojú ìwé 23 (àti àpótí)
No. 2: Jákọ́bù 5:1-12
No. 3: Àwọn Ìlànà Bíbélì Tí Ó Lè Ràn Yín Lọ́wọ́ Láti Gbádùn Ìgbéyàwó Aláyọ̀, Tí Ó Wà Pẹ́ Títí (fy-YR ojú ìwé 38 àpótí àtúnyẹ̀wò)
No. 4: td-YR 21B Ọlọ́run Ń Fúnni Ní Ìgbàlà Kìkì Nípasẹ̀ Kristi
Oct. 26 Bíbélì kíkà: Pétérù Kíní 1 sí 5
Orin 54 [*Sámúẹ́lì Kejì 11 sí 15]
No. 1: w91-YR 3/15 ojú ìwé 30 (àti àpótí)
No. 2: Pétérù Kíní 4:1-11
No. 3: td-YR 21D “Ìgbàlà Lẹ́ẹ̀kan, Ìgbàlà Gbogbo Ìgbà” Kò Bá Ìwé Mímọ́ Mu
No. 4: Ṣe Bí O Ti Mọ (fy-YR ojú ìwé 39 sí 41 ìpínrọ̀ 1 sí 6)
Nov. 2 Bíbélì kíkà: Pétérù Kejì 1 sí 3
Orin 177 [*Sámúẹ́lì Kejì 16 sí 20]
No. 1: w91-YR 3/15 ojú ìwé 31 (àti àpótí)
No. 2: Pétérù Kejì 3:1-13
No. 3: Títọ́jú Agbo Ilé Jẹ́ Ojúṣe Ìdílé (fy-YR ojú ìwé 42 sí 44 ìpínrọ̀ 7 sí 11)
No. 4: td-YR 21E “Ìgbàlà Gbogbo Aráyé” Kò Bá Ìwé Mímọ́ Mu
Nov. 9 Bíbélì kíkà: Jòhánù Kíní 1 sí 5
Orin 114 [*Sámúẹ́lì Kejì 21 sí Àwọn Ọba Kìíní 1]
No. 1: w91-YR 4/15 ojú ìwé 29 (àti àpótí)
No. 2: Jòhánù Kíní 5:1-12
No. 3: td-YR 18A Ohun Tí Ẹ̀ṣẹ̀ Jẹ́
No. 4: Ìdí Tí Jèhófà Fi Béèrè Pé Kí A Wà ní Mímọ́ (fy-YR ojú ìwé 45 sí 49 ìpínrọ̀ 12 sí 20)
Nov. 16 Bíbélì kíkà: Jòhánù Kejì sí Júúdà
Orin 22 [*Àwọn Ọba Kìíní 2 sí 6]
No. 1: w91-YR 4/15 ojú ìwé 30 àti 31 (àti àwọn àpótí)
No. 2: Jòhánù Kejì 1:1-13
No. 3: Ohun Tí Ìgbóríyìn àti Ìmoore Olóòótọ́ Inú Lè Ṣe fún Ìdílé (fy-YR ojú ìwé 49 àti 50 ìpínrọ̀ 21 àti 22)
No. 4: td-YR 18B Ìdí Tí Gbogbo Ènìyàn Fi Ń Jìyà Láti inú Ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù
Nov. 23 Bíbélì kíkà: Ìṣípayá 1 sí 3
Orin 195 [*Àwọn Ọba Kìíní 7 sí 10]
No. 1: w91-YR 5/1 ojú ìwé 21 (àti àpótí) títí dé ojú ìwé 22 ìpínrọ̀ 4
No. 2: Ìṣípayá 3:1-11
No. 3: td-YR 18C Kí Ni Èso Tí A Kàléèwọ̀ Náà Jẹ́?
No. 4: Ojú Ìwòye Bíbélì Nípa Àwọn Ọmọ àti Ẹrù Iṣẹ́ Ìdílé (fy-YR ojú ìwé 51 àti 52 ìpínrọ̀ 1 sí 5)
Nov. 30 Bíbélì kíkà: Ìṣípayá 4 sí 6
Orin 168 [*Àwọn Ọba Kìíní 11 sí 15]
No. 1: Ìwọ Yóò Ha Ti Dá Mèsáyà Náà Mọ̀ Bí? (w96-YR 11/15 ojú ìwé 28 sí 31)
No. 2: Ìṣípayá 5:1-12
No. 3: Ohun Tí Ó Túmọ̀ Sí Láti Kájú Àìní Ọmọ (fy-YR ojú ìwé 53 sí 55 ìpínrọ̀ 6 sí 9)
No. 4: td-YR 18F Kí Ni Ẹ̀ṣẹ̀ Sí Ẹ̀mí Mímọ́ Jẹ́?
Dec. 7 Bíbélì kíkà: Ìṣípayá 7 sí 9
Orin 53 [*Àwọn Ọba Kìíní 16 sí 20]
No. 1: Èé Ṣe Tí Ó Fi Yẹ Kí A “Máa Rántí Àwọn Ọjọ́ Tí Ó Ti Kọjá”? (w96-YR 12/1 ojú ìwé 29 sí 31)
No. 2: Ìṣípayá 8:1-13
No. 3: td-YR 55A Kí Ni Ọkàn Jẹ́?
No. 4: Gbin Òtítọ́ Sínú Ọmọ Rẹ (fy-YR ojú ìwé 55 sí 57 ìpínrọ̀ 10 sí 15)
Dec. 14 Bíbélì kíkà: Ìṣípayá 10 sí 12
Orin 34 [*Àwọn Ọba Kìíní 21 sí Àwọn Ọba Kejì 3]
No. 1: Ojú Ìwòye Ọlọ́run Nípa Ọtí Líle (w96-YR 12/15 ojú ìwé 25 sí 29)
No. 2: Ìṣípayá 10:1-11
No. 3: Kọ́ Ọmọ Rẹ Ní Àwọn Ọ̀nà Jèhófà (fy-YR ojú ìwé 58 àti 59 ìpínrọ̀ 16 sí 19)
No. 4: td-YR 55B Báwo Ni Ọkàn àti Ẹ̀mí Ṣe Yàtọ̀ Síra?
Dec. 21 Bíbélì kíkà: Ìṣípayá 13 sí 15
Orin 60 [*Àwọn Ọba Kejì 4 sí 9]
No. 1: Ìrètí Tí Ó Sàn Jù fún Ọkàn (w96-YR 8/1 ojú ìwé 4 sí 8)
No. 2: Ìṣípayá 13:1-15
No. 3: td-YR 17A Kí Ni Ẹ̀mí Mímọ́ Jẹ́?
No. 4: Àìní Ṣíṣe Kókó fún Ìbáwí ní Onírúurú Ọ̀nà (fy-YR ojú ìwé 59 àti 60 ìpínrọ̀ 20 sí 23)
Dec. 28 Àtúnyẹ̀wò Alákọsílẹ̀. Parí Tímótì Kejì 1 sí Ìṣípayá 15
Orin 212 [*Àwọn Ọba Kejì 10 sí 15]