ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 4/98 ojú ìwé 7
  • Àwọn Ìfilọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìfilọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
km 4/98 ojú ìwé 7

Àwọn Ìfilọ̀

◼ April àti May: Gbogbo èdè—Àsansílẹ̀ owó fún Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Àwọn ìwé ìròyìn ẹlẹ́ẹ̀mejì lóṣù fún ọdún kan: ₦280. Ẹlẹ́ẹ̀kan lóṣù fún ọdún kan tàbí ẹlẹ́ẹ̀mejì lóṣù fún oṣù mẹ́fà: ₦140. June: Èyíkéyìí nínú àwọn ìwé olójú ewé 192 tí ó tẹ̀ lé e yìí tí ìjọ lè ní lọ́wọ́: Àìléwu Kárí-Ayé Labẹ “Ọmọ-Aládé Alaafia,” Ayọ̀—Bi A Ṣe Lè Rí I, Fifetisilẹ si Olukọ Nla na, Igba Ewe rẹ—Bi o ṣe le Gbadun rẹ Julọ, Isopọṣọkan ninu Ijọsin Ọlọrun Tootọ Kanṣoṣo Naa, “Jẹ́ Kí Ijọba Rẹ Dé,” àti Lilaaja Sinu Ilẹ-ayé Titun. ÀKÍYÈSÍ: Kí àwọn ìjọ tí yóò bá nílò àwọn ìwé ìgbétáásì tí a mẹ́nu kàn lókè yìí béèrè fún wọn lórí Literature Order Form (S-14) olóṣooṣù wọn ti oṣù tí ń bọ̀. July àti August: A lè lo èyíkéyìí nínú àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 tí ó tẹ̀ lé e yìí: Awọn Ẹlẹrii Jehofah—Nfi Pẹlu Isopọṣọkan Ṣe Ifẹ-Inu Ọlọrun Yíká-Ayé, Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?, Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, “Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun,” Why Should We Worship God in Love and Truth?, àti Will There Ever Be a World Without War? Pẹ̀lúpẹ̀lù, kí a fún àwọn òbí níṣìírí láti gba àwọn ìwé pẹlẹbẹ náà, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti Ìmọ̀ Ẹ̀kọ́ àti Awọn Ẹlẹrii Jehofah—Nfi Pẹlu Isopọṣọkan Ṣe Ifẹ-Inu Ọlọrun Yíká-Ayé, kí wọ́n sì jẹ́ kí àwọn olùkọ́ àwọn ọmọ wọn mọ̀ nípa ìsọfúnni tí ó wà nínú wọn. Igbo—A lè lo èyíkéyìí nínú àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 tí ó tẹ̀ lé e yìí: Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá, Awọn Ẹlẹrii Jehofah—Nfi Pẹlu Isopọṣọkan Ṣe Ifẹ-Inu Ọlọrun Yíká-Ayé, Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?, àti “Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun.” Yorùbá—Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá, Awọn Ẹlẹrii Jehofah—Nfi Pẹlu Isopọṣọkan Ṣe Ifẹ-Inu Ọlọrun Yíká-Ayé, àti Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae.

◼ Nígbà tí àwọn akéde bá ń ṣiṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ tí a kò yàn fúnni, wọ́n lè fi ìwé Ìmọ̀ tàbí ìwé pẹlẹbẹ Béèrè lọni. A lè fi ìtẹ̀jáde èyíkéyìí mìíràn lọni bí onílé bá ti ní àwọn ìtẹ̀jáde méjì wọ̀nyí tẹ́lẹ̀. Kí gbogbo akéde kó onírúurú ìwé àṣàrò kúkúrú dání nítorí àwọn kò-sí-nílé tàbí àwọn mìíràn tí kò gba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́. Kí a fún àwọn onílé ní Ìròyìn Ìjọba No. 35 èyíkéyìí tí àwọn akéde tàbí ìjọ bá ṣì ní lọ́wọ́. Kí a sapá láti padà ṣiṣẹ́ lórí ọkàn-ìfẹ́, pàápàá níbi tí àwọn ìjọ tí ó wà nítòsí bá ti lè dé àwọn ìpínlẹ̀ tí a kò pín fúnni.

◼ Bí oṣù May ti ní òpin ọ̀sẹ̀ márùn-ún kíkúnrẹ́rẹ́, ó jẹ́ àkókò rírọgbọ fún ọ̀pọ̀ láti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́.

◼ Ní May 30, 1998, a óò ti ilé Bẹ́tẹ́lì pa. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ má ṣe wá ṣèbẹ̀wò, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe wá ra ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ní déètì yìí.

◼ Bí èyíkéyìí nínú àwọn ará bá fẹ́ rìnrìn àjò lọ sí United States tí wọ́n sì fẹ́ ilé ìbùwọ̀ ní hòtẹ́ẹ̀lì nítòsí Bẹ́tẹ́lì, ẹ jọ̀wọ́, ẹ kọ̀wé sí ẹ̀ka ti Nàìjíríà, a ó sì fún un yín ní ìsọfúnni lọ́ọ́lọ́ọ́.

◼ Àwọn Ìtẹ̀jáde Tuntun Tí Ó Wà:

Igbesi-aye ninu Aye Titun alalaafia kan

(Ìwé Àṣàrò Kúkúrú No. 15)—Urhobo

Ireti Wo ni Ó Wà fun Awọn Ololufẹ Tí wọn Ti Kú?

(Ìwé Àṣàrò Kúkúrú No. 16)—Edo, Itsekiri, Ogoni

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́