Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run
Àtúnyẹ̀wò pípa ìwé dé lórí àkópọ̀ ẹ̀kọ́ tí a kárí nínú àwọn iṣẹ́ àyànfúnni Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run fún àwọn ọ̀sẹ̀ January 5 sí April 20, 1998. Lo abala tákàdá ọ̀tọ̀ láti fi kọ ìdáhùn sí púpọ̀ nínú àwọn ìbéèrè náà, bí ó bá ti lè ṣeé ṣe fún ọ tó, ní ìwọ̀n àkókò tí a yàn.
[Àkíyèsí: Lákòókò àtúnyẹ̀wò alákọsílẹ̀, Bíbélì nìkan ni a lè lò láti dáhùn ìbéèrè èyíkéyìí. Àwọn ìtọ́kasí tí ó tẹ̀ lé àwọn ìbéèrè wà fún ìwádìí fúnra rẹ. Nọ́ńbà ojú ìwé àti ìpínrọ̀ lè má fara hàn nínú gbogbo àwọn ìtọ́ka tí a ṣe sí Ilé Ìṣọ́.]
Dáhùn Òtítọ́ tàbí Èké sí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn gbólóhùn tí ó tẹ̀ lé e yìí:
1. Nínú Ìṣe 15:29, gbólóhùn ọ̀rọ̀ náà, “Kí ara yín ó le o,” jẹ́ ìlérí kan tí ó túmọ̀ sí pé, ‘Bí ẹ bá ta kété sí ẹ̀jẹ̀ àti sí àgbèrè, ẹ̀yin yóò ní ìlera tí ó sàn jù.’ [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w91-YR 6/15 ojú ìwé 9 ìpínrọ̀ 7 àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé.]
2. Ní ìbámu pẹ̀lú Éfésù 5:33, níní tí aya kan ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ọkọ̀ rẹ̀ kò túmọ̀ sí pé òun kò lè sọ èrò rẹ̀ síta, pàápàá jù lọ bí ohun kan bá ń dà á láàmú. [kl-YR ojú ìwé 144 ìpínrọ̀ 12, 13]
3. Lójú àwọn ará Íjíbítì, Fáráò ni a kà sí Horus ní àwọ̀ ènìyàn, ọlọ́run àjúbàfún aborí-bí-ti àṣá. [w96-YR 1/15 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 1]
4. Ọ̀rọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì náà, “simony,” èyí tí a mú jáde láti inú ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kọ sínú Ìṣe 8:9-24, tọ́ka sí iṣẹ́ idán pípa. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w90-YR 6/1 ojú ìwé 17 ìpínrọ̀ 8.]
5. Nínú Róòmù 8:6, 7, “ẹran ara” ń tọ́ka sí ipò ẹ̀ṣẹ̀ wa gẹ́gẹ́ bí ènìyàn aláìpé tí ó ti jogún àwọn ìtẹ̀sí tí ó kún fún ẹ̀sẹ̀. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w91-YR 3/1 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 4.]
6. Níwọ̀n bí Jèhófà ti tẹ́wọ́ gba àwọn ọrẹ ọkà àti àwọn èso ilẹ̀ mìíràn lẹ́yìn náà, ó hàn gbangba pé a kọ ọrẹ Kéènì nítorí pé ohun kan ṣàìtọ́ nínú ọkàn-àyà rẹ̀. (Jẹ́n. 4:3-5) [w96-YR 6/15 ojú ìwé 4 ìpínrọ̀ 8]
7. Bí Kristẹni kan ṣe ń fi àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n ìwà híhù àti tẹ̀mí tí ó wà nínú Bíbélì sílò nínú ìgbésí ayé rẹ̀, Ọ̀rọ̀ Jèhófà ń wẹ̀ ẹ́ mọ́, ó ‘ń sọ ọ́ di mímọ́’ kúrò nínú gbogbo ìṣe tí Jèhófà Ọlọ́run kórìíra. (1 Kọ́r. 6:9-11) [w96-YR 1/1 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 4]
8. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fúnra rẹ̀ ni ó batisí agbo ilé Sítéfánásì ní Kọ́ríńtì. [w96-YR 6/15 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 2]
9. Nínú Ìṣe 20:20, gbólóhùn ọ̀rọ̀ náà, “láti ilé dé ilé,” tọ́ka sí kìkì ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn nínú ilé àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ ẹni nítorí pé àyíká ọ̀rọ̀ náà fi hàn pé Pọ́ọ̀lù ń bá àwọn àgbà ọkùnrin tí ó wà nínú ìjọ náà sọ̀rọ̀. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w91-YR 1/15 ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 5.]
10. Bí a bá dá ọkàn-àyà wa lẹ́kọ̀ọ́ láti mọrírì àwọn nǹkan tẹ̀mí, kí a gbàdúrà fún ẹ̀mí Ọlọ́run láti ràn wá lọ́wọ́ ní ṣíṣe èyí, nígbà náà, a ó yẹra fún “gbígbé èrò inú ka ẹran ara.” (Róòmù 8:6, 7) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w91-YR 3/1 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 5.]
Dáhùn àwọn ìbéèrè tí ó tẹ̀ lé e yìí:
11. Àkọsílẹ̀ wo nínú ìwé Ìṣe ni ó fi hàn pé wíwulẹ̀ ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti kíkà á fúnra ẹni nìkan kò tó láti jèrè ìmọ̀ pípéye tí ń mú ẹnì kan bọ́ sójú ọ̀nà ìyè? [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w91-YR 9/1 ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 16.]
12. Kí ni ó yẹ kí ó mú wa yẹra fún dídá àwọn ará wa nípa tẹ̀mí lẹ́jọ́ lọ́nà líle koko? [w96-YR 3/15 ojú ìwé 22 ìpínrọ̀ 6]
13. Nínú Ìṣe 11:26, èé ṣe tí Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun fi lo gbólóhùn ọ̀rọ̀ náà, “tipasẹ̀ ìdarí àtọ̀runwá pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn ní Kristẹni,” nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn ìtumọ̀ Bíbélì yòókù kò fi èrò “ìdarí àtọ̀runwá” kún un? [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w90-YR 6/1 ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 19.]
14. Kí ni yóò ran Kristẹni aya kan lọ́wọ́ láti ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀? (Éfé. 5:33) [w96-YR 3/1 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 5]
15. Kí ni a fi hàn nípa òtítọ́ náà pé Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Àwọn ọlá àṣẹ tí ó wà ni a gbé dúró sí àwọn ipò wọn aláàlà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run”? (Róòmù 13:1) [kl-YR ojú ìwé 131 ìpínrọ̀ 7]
16. Nínú lẹ́tà rẹ̀ sí àwọn Kristẹni ní Róòmù, kí ni Pọ́ọ̀lù fìdí rẹ̀ múlẹ̀ dáadáa nípa àwọn Júù àti àwọn tí kì í ṣe Júù? [w90-YR 8/1 ojú ìwé 23]
17. Ní ìbámu pẹ̀lú Róòmù 12:2, báwo ni agbára Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe ń yí ànímọ́ àwọn Kristẹni padà tó? [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w90-YR 4/1 ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 3.]
18. Kí ni “àṣírí ọlọ́wọ̀” tí Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kàn nínú Róòmù 11:25? [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w84-YR 2/15 ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 16.]
19. Èé ṣe tí ó fi tọ́ kí ìjọ Kristẹni máa yọ àwọn oníwà àìtọ́ tí kò ronú pìwà dà lẹ́gbẹ́? (1 Kọ́r. 5:11, 13) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo g96-YR 9/8 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 2, 3.]
20. Báwo ni kíkó òkìtì ẹyín iná lé elénìní lórí yóò ṣe ṣèrànwọ́ ní ṣíṣẹ́gun ibi? (Róòmù 12:20, 21) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo g89-YR 2/8 ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 5.]
Pèsè ọ̀rọ̀ tàbí àpólà ọ̀rọ̀ tí a nílò láti parí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn gbólóhùn tí ó tẹ̀ lé e yìí:
21. Fílípì ṣàlàyé fún ìwẹ̀fà ará Etiópíà náà bí àsọtẹ́lẹ̀ inú _________________________ ṣe ní ìmúṣẹ, lẹ́yìn tí a sì ti là á lóye, ẹni yìí fi ìrẹ̀lẹ̀ béèrè fún _________________________. (Ìṣe 8:28-35) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀]
22. Nígbà tí àríyànjiyàn ṣẹlẹ̀ lórí ọ̀ràn _________________________, _________________________ ti ìpinnu rẹ̀ lẹ́yìn nípa sísọ pé: “Ọ̀rọ̀ àwọn Wòlíì sì bá èyí mu, gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ̀.” (Ìṣe 15:15-18) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀]
23. Ànímọ́ ________________________ ń ràn wá lọ́wọ́ láti ‘máa kà á sí pé àwọn ẹlòmíràn lọ́lá jù wá lọ,’ nígbà tí ________________________ ń mú kí a lè ‘kó ara wa ní ìjánu lábẹ́ ibi.’ (Fílí. 2:3; 2 Tím. 2:24, 25) [w96-YR 5/15 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 5]
24. Ní ìbámu pẹ̀lú àkàwé Pọ́ọ̀lù nípa igi ólífì ìṣàpẹẹrẹ nínú Róòmù orí 11, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà Ísírẹ́lì 12 ti pẹ̀ka láti ọ̀dọ̀ Ábúráhámù nípasẹ̀ Ísákì, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yà 12 ________________________ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ ṣe pẹ̀ka láti ọ̀dọ̀ ________________________ nípasẹ̀ ________________________. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w84-YR 2/15 ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 15.]
25. Bí Jèhófà ṣe mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n dó sí Aginjù _______________________ dúró, òun lè mú wa dúró nínú _______________________. [w96-YR 8/15 ojú ìwé 7 ìpínrọ̀ 1, 2]
Mú ìdáhùn tí ó tọ̀nà nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn gbólóhùn tí ó tẹ̀ lé e yìí:
26. Pẹ̀lú ọgbọ́n, Pọ́ọ̀lù fi àwíyé rẹ̀ nínú Ìṣe orí 17 fìdí (ipò ọba aláṣẹ; òdodo; ìfẹ́) Ọlọ́run alààyè múlẹ̀. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀]
27. (Pọ́ọ̀lù; Pétérù; Lúùkù) fi ọ̀yàyà gbóríyìn fún àwọn ènìyàn (Bèróà; Makedóníà; Jerúsálẹ́mù) nítorí bí wọ́n ṣe ń fi aápọn ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́. (Ìṣe 17:11) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w95-YR 5/1 ojú ìwé 14 ìpínrọ̀ 3.]
28. Irọ́, tàbí èké, tí a mẹ́nu kàn nínú Róòmù 1:25 ń tọ́ka sí (ìbọ̀rìṣà; ìṣe ìbálòpọ̀ aláìmọ́; fífi irọ́ pípa ṣèwàhù). [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w91-YR 11/15 ojú ìwé 6 ìpínrọ̀ 7.]
29. Ní tòótọ́, lọ́pọ̀ ìgbà, (àwọn ènìyàn; Ọlọ́run àti Kristi; Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù) ni ó yẹ kí a máa dá lẹ́bi nígbà tí nǹkan bá ṣẹlẹ̀. [w96-YR 9/1 ojú ìwé 5 ìpínrọ̀ 3]
30. Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́ sí àwọn ará Kọ́ríńtì nígbà tí ó wà ní (Róòmù; Éfésù; Kọ́ríńtì) ní nǹkan bí ọdún (52; 55; 56) Sànmánì Tiwa. [w90-YR 9/15 ojú ìwé 24]
So àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí ó tẹ̀ lé e yìí mọ́ àwọn gbólóhùn tí a tò lẹ́sẹẹsẹ sí ìsàlẹ̀ yìí:
Òwe 17:27; Oníw. 9:11; Mát. 10:16; Ìṣe 10:34, 35; 2 Kọ́r. 4:18
31. Gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jèhófà, ojú tí òun fi ń wo gbogbo àwùjọ ẹ̀yà ìran ni ó yẹ kí a máa fi wò ó. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w88-YR 5/15 ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 6.]
32. Ó yẹ kí a máa wò ré kọjá àwọn àyíká ipò wa ti lọ́ọ́lọ́ọ́, kí a tẹ ojú wa mọ́ àbájáde aláyọ̀ tí ipa ọ̀nà Kristẹni yóò mú wá. [w96-YR 2/15 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 3, 4]
33. Ìfòyemọ̀ àti ìfẹ́ ará yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ṣàkóso ìháragàgà wa láti sọ àwọn ohun tí ó lè fa ìbínú jáde. [w96-YR 5/15 ojú ìwé 22 ìpínrọ̀ 7]
34. Nígbà tí a bá dojú kọ inúnibíni, àwọn Kristẹni tòótọ́ ní láti pa ọgbọ́n inú pọ̀ mọ́ ìjẹ́mímọ́ ní pípolongo ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà fún àwọn ẹlòmíràn. [w96-YR 7/15 ojú ìwé 22 ìpínrọ̀ 5]
35. Kò sí ìdí kankan láti gbà gbọ́ pé Ẹlẹ́dàá ni ó wà lẹ́yìn àwọn jàǹbá tàbí ni ó ń ṣokùnfà pé kí àwọn tí jàǹbá ṣẹlẹ̀ sí jìyà lọ́nà kan ṣáá. [w96-YR 9/1 ojú ìwé 5 ìpínrọ̀ 4]