Fífi Ìdùnnú Kúnjú Àìní Ìkórè Náà
1 Dájúdájú, àkókò ìkórè nìyí. Nísinsìnyí, a wà ní ìparí ètò àwọn nǹkan, gẹ́gẹ́ bí Jésù sì ṣe sọ nínú ọ̀kan lára àwọn òwe àkàwé rẹ̀, “Ìkórè ni ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mát. 13:39) Ní Jòhánù 5:17, Jésù sọ pé: “Baba mi ti ń bá a nìṣó ní ṣíṣiṣẹ́ títí di ìsinsìnyí, èmi náà sì ń bá a nìṣó ní ṣíṣiṣẹ́.” Nínú ìgbòkègbodò àkókò ìkórè yìí, ọwọ́ àwọn ènìyàn Jèhófà dí, kì í ṣe fún wíwàásù ìhìn rere Ìjọba náà nìkan ni, ṣùgbọ́n nínú pípèsè àwọn ibi ìjọsìn pẹ̀lú. Nísinsìnyí ju ti ìgbàkígbà rí lọ, a nílò àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba. Àwọn ìròyìn tí a rí gbà ní lọ́ọ́lọ́ọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn alábòójútó àyíká fi hàn pé ó ju 2,000 àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tí a ń kọ́ lọ́wọ́, díẹ̀ nínú wọn sì ti wà fún ọ̀pọ̀ ọdún. Èyí tí ó ju 300 ìjọ ń lo àwọn ilé tí a háyà. Nǹkan bí 400 Gbọ̀ngàn Ìjọba ni ó hàn gbangba pé a ti parí ṣùgbọ́n tí a kò tíì yà wọ́n sí mímọ́ síbẹ̀. A dúpẹ́ pé, Jèhófà ti sún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ adúróṣinṣin láti yọ̀ǹda òye iṣẹ́ wọn nínú kíkọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba. Kì í ṣe kìkì pé wọ́n ń ṣiṣẹ́ kára nìkan ni, ṣùgbọ́n wọ́n tún ń fi ẹ̀mí ìdùnnú hàn.
2 Bí ó ṣe rí ní ọjọ́ Nehemáyà nígbà tí ọwọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dí ní kíkọ́ ògiri Jerúsálẹ́mù ni ó ṣe rí báyìí. Nehemáyà 4:6 sọ pé “àwọn ènìyàn . . . ń bá a lọ láti ní ọkàn-àyà fún iṣẹ́ ṣíṣe.” Kí ni àṣírí irú ipò ọkàn-àyà rere bẹ́ẹ̀? A mẹ́nu kàn án lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn ní Nehemáyà 8:10 pé: “Nítorí ìdùnnú Jèhófà ni odi agbára yín.” Dájúdájú, a ní ìdí gbogbo láti jẹ́ òṣìṣẹ́ onídùnnú. A ní ìbùkún Jèhófà. A ní ẹ̀mí Jèhófà, ìdùnnú sì jẹ́ apá kan èso ẹ̀mí yẹn.—Gál. 5:22.
3 Ẹ Tètè Kàn sí Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn: Nígbà tí àwọn ìjọ bá ń ronú nípa bíbẹ̀rẹ̀ àtúnkọ́ tàbí bíbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìkọ́lé tuntun, kí àwọn alàgbà àdúgbò kàn sí Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn ní ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà. Society ti pèsè ìtọ́sọ́nà fún àwọn Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn, àwọn arákùnrin wọ̀nyí sì ní ọ̀pọ̀ ìrírí tí yóò ṣèrànwọ́ láti yẹra fún àwọn ọ̀fìn nígbà tí ẹ bá ń ra ilẹ̀ àti nígbà tí ẹ bá ń wéwèé iṣẹ́ ìkọ́lé. Bí ẹ bá fún wọn ní ìsọfúnni lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ nípa gbogbo iṣẹ́ tí ó wà ní àgbègbè tí a yàn fún wọn, ìgbìmọ̀ ẹlẹ́kùnjẹkùn lè ṣètò àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni kí ó lè jẹ́ pé gbogbo iṣẹ́ náà ni a óò parí láìkò fi iṣẹ́ pá àwọn òṣìṣẹ́ tí wọ́n ní òye iṣẹ́ lórí.
4 Àwọn Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn ń fi ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ hàn ní ọ̀pọ̀ ọ̀nà, irú bí rírìnrìn àjò gígùn láti bẹ àwọn ìjọ tí ó ké sí wọn wò. Ó yẹ kí àwọn alàgbà máa fi ìmọrírì hàn fún ìsapá wọn nípa dídúró ní ọjọ́ tí wọ́n pinnu láti pàdé pẹ̀lú wọn. Kí àwọn alàgbà fi sọ́kàn pé àwọn àbá tí Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn bá pèsè ni a gbé karí ìtọ́sọ́nà tí a fún wọn. Nítorí náà, wọ́n gbọ́dọ̀ máa fara balẹ̀ ṣàkíyèsí àwọn àbá tí ìgbìmọ̀ bá fún wọn.
5 Àwọn ìjọ kan ti pinnu láti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn láìbá Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn fikùnlukùn kìkì nítorí pé wọ́n rò pé àwọn àbá láti ọ̀dọ̀ ìgbìmọ̀ ń náni lówó púpọ̀. Àwọn mìíràn ti ra ilẹ̀ láìjẹ́ kí Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn lọ́wọ́ nínú rẹ̀ láti ṣàyẹ̀wò, wọ́n sì ti tipa báyìí lọ ra inú irà tàbí lọ ra ilẹ̀ tí ó kéré púpọ̀. Lọ́nà ọgbọ́n, àwọn ìjọ lè jàǹfààní láti inú àkíyèsí tí àwọn alàgbà tí a yàn láti sìn nínú Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn bá ṣe nípa kíkàn sí wọn ní ìbẹ̀rẹ̀, tipẹ́tipẹ́ ṣáájú kí a tó ra ilẹ̀ èyíkéyìí.—Òwe 15:22.
6 Àwọn Ẹlòmíràn Ń Wò Ó: Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wí pé: “Àwa ti di ìran àpéwò ní gbọ̀ngàn ìwòran fún ayé, àti fún àwọn áńgẹ́lì, àti fún àwọn ènìyàn.” (1 Kọ́r. 4:9) Àwọn Kristẹni wà lójútáyé lónìí, èyí sì jẹ́ òtítọ́ ní pàtàkì ní àkókò kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Iṣẹ́ tí a ń ṣe àti ẹ̀mí ìdùnnú àwọn òṣìṣẹ́ kò ṣàìgba àfiyèsí. Fún ìdí èyí, àwọn òǹwòran ti sọ ìmọ̀lára wọn jáde ní onírúurú ọ̀nà. Ní Ozubulu, Ìpínlẹ̀ Anambra, lẹ́yìn kíkíyèsí oríṣiríṣi ènìyàn tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ ní ibi ilẹ̀ náà, obìnrin kan tí ń ta àkàrà nítòsí béèrè ibi tí àwọn òṣìṣẹ́ náà ti wá. A sọ fún un pé wọ́n wá láti oríṣiríṣi ìlú láàárín ìpínlẹ̀ náà. Ìṣọ̀kan tí ó wà láàárín Àwọn Ẹlẹ́rìí mú orí rẹ̀ wú, ó sì sọ pé: “Láti inú àkíyèsí mi, ayé tuntun tí ẹ ń wàásù rẹ̀ jẹ́ òtítọ́ gidi.”
7 Nígbà tí àwọn ará ń ṣiṣẹ́ ní ọjọ́ kan níbi iṣẹ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba, ẹnì kan tí ó ń kọjá lọ sún mọ́ wọn, ó sí sọ pé: ‘Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi kì í ṣe Ẹlẹ́rìí, mo ní ọkàn-ìfẹ́ nínú iṣẹ́ yín. Mo ti ná owó tí ó wà lọ́wọ́ mi tán ṣùgbọ́n, ẹ jọ̀wọ́, ẹ wá sí ilé mi ní ọjọ́ Saturday, kí ẹ sì gba ọrẹ ₦5,000 tèmi ní ìtìlẹyìn iṣẹ́ náà.’ Ó ṣe ìtọrẹ náà gẹ́gẹ́ bí ó ṣe ṣèlérí. Níbi iṣẹ́ kan náà yẹn, opó kan wá síbẹ̀ lẹ́yìn tí ó sì ti fi ayọ̀ rẹ̀ hàn, ó fún wọn ní ₦20. Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn kan sọ pé inú àwọn dùn nítorí títẹ̀lé ìṣètò iṣẹ́ àwọn láìka ojú ọjọ́ tí kò dára sí. Wọ́n ròyìn pé: ‘Nígbà tí iṣẹ́ ìkọ́lé ń lọ lọ́wọ́, ẹnì kan sọ pé níwọ̀n bí a ti ń sún mọ́ ìgbà òjò, ó yẹ kí a sún iṣẹ́ náà síwájú di àkókò tí ìgbà ẹ̀rùn bá bẹ̀rẹ̀. Àmọ́ ṣáá o, a ń bá iṣẹ́ náà nìṣó. Ó múni láyọ̀ pé, ní gbogbo ọjọ́ iṣẹ́ tí a ṣètò ní ibi iṣẹ́ náà, òjò kò rọ̀ rárá. Láìpẹ́ àwọn ará ìlú bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé: “Bí ẹnì kan bá ní ayẹyẹ kan láti ṣe, kí ó fi sí ọjọ́ tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò ṣiṣẹ́ lórí gbọ̀ngàn wọn, nítorí òjò kò ní rọ̀.”’
8 Ìjọ kan ní Calabar ronú pé ó yẹ kí àwọn kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tí ó túbọ̀ tóbi. Ẹni tí ó ni ilẹ̀ tí wọ́n rí gbà láti ta ilẹ̀ náà fún wọn ní ₦280,000. Kí àwọn ará tó lè rí iye yẹn kó jọ, ọkùnrin oníṣòwò kan wá, ó sì sọ pé òun yóò san ₦300,000 fún ilẹ̀ kan náà. Ṣùgbọ́n onílẹ̀ náà fi ọgbọ́n ṣàlàyé fún ìyàwó rẹ̀ pé: “Ó sàn jù kí a já ọkùnrin yẹn kulẹ̀ ju kí a já Ọlọ́run kulẹ̀ lọ.” Ó kọ iye owó tí ó pọ̀ jù náà, lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn ó sì dín iye náà kù fún ìjọ láti ₦280,000 sí ₦180,000. Ó wí pé: “Ẹ jẹ́ kí ₦100,000 jẹ́ ọrẹ tèmi fún ìkọ́lé náà.”
9 Ìyọ̀ǹda Ìrànwọ́ Onífẹ̀ẹ́: Ọ̀pọ̀ òṣìṣẹ́ títóótun ṣètọrẹ àkókò àti òye iṣẹ́ wọn láti ṣèrànwọ́ ní ti ríra ilẹ̀, yíyàwòrán ilé, kíkọ́lé àti ṣíṣe iṣẹ́ ẹ̀rọ, ṣíṣẹ̀ṣọ́, títún ìrísí ojú ilẹ̀ ṣe, bíbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lórí ilẹ̀, ríra nǹkan, ìpèsè oúnjẹ, ààbò, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn ará ṣètọrẹ lílo àwọn irinṣẹ́ àti ohun èlò wọn lórí àwọn iṣẹ́ wọ̀nyí. Ẹ wo bí èyí ti gbọ́dọ̀ mú Baba wa, Jèhófà, láyọ̀ tó nígbà tí ó ń rí wọn tí wọ́n ń lo àwọn ohun ìní àti agbára wọn lọ́nà onífẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀!—Fi wé 1 Tẹsalóníkà 2:6-9 àti 2 Tẹsalóníkà 3:8b.
10 Pẹ̀lú bí àwọn ìjọ ṣe ń pọ̀ sí i, àìní wà fún ọ̀pọ̀ Gbọ̀ngàn Ìjọba sí i. A nílò àfikún ìnáwó àti àwọn òṣìṣẹ́ láti kúnjú ohun tí a ń béèrè yìí. Ní ọdún iṣẹ́ ìsìn tí ó kọjá, iye àwọn ìjọ ní Nàìjíríà fí 203 pọ̀ sí i, a sì ń fẹ́ ọ̀pọ̀ Gbọ̀ngàn Ìjọba sí i láti pèsè àyè lílò fún àwọn ìjọ tuntun wọ̀nyí.
11 Nígbà tí ó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ arákùnrin àti arábìnrin ń bá a nìṣó láti máa ṣèrànwọ́ nínú kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba, tí wọ́n ń yọ̀ǹda àkókò àti ìsapá wọn lọ́fẹ̀ẹ́, ìpè wà fún ìrànwọ́ sí i gan-an gẹ́gẹ́ bí àìní ti wà fún ọ̀pọ̀ òṣìṣẹ́ sí i nínú pápá ìkórè. (Mát. 9:37, 38) Ọ̀pọ̀ jù lọ ìgbìmọ̀ ẹlẹ́kùnjẹkùn ròyìn pé níní àfikún àwọn òṣìṣẹ́ tí wọ́n múra tán lárọ̀ọ́wọ́tó fún iṣẹ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba yóò mú kí ẹrù àwọn tí ó ti ń gbé ẹrù iṣẹ́ yìí fúyẹ́.—Aísá. 6:8; Gál. 6:2.
12 Ta Ní Tóótun: Nígbàkigbà tí a bá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba, àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni láti inú ìjọ tàbí inú àwọn ìjọ tí yóò máa lo ilé tuntun tàbí èyí tí a tún kọ́ náà, àti láti inú àwọn ìjọ tí ó wà nítòsí ni ó máa ń pèsè àwọn òṣìṣẹ́ ní gbogbogbòò. A máa ń dá díẹ̀ lára àwọn wọ̀nyí lẹ́kọ̀ọ́ lẹ́yìn náà tí wọn yóò sì tóótun gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó nírìírí tàbí gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ tí ó ní òye iṣẹ́ pàápàá, kí wọ́n lè fi fọ́ọ̀mù Kingdom Hall Construction Worker Questionnaires lélẹ̀.
13 Ní pàtó, àwọn tí Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn nílò lóṣooṣù ni àwọn tí wọ́n ní ìrírí nínú iṣẹ́ ìkọ́lé, tí wọ́n sì yọ̀ǹda láti ṣèrànwọ́ nínú kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tí a nílò. Àwọn wọ̀nyí gbọ́dọ̀ ní ìdúró rere nínú ìjọ kí ẹgbẹ́ àwọn alàgbà àdúgbò sì fọwọ́ sí wọn. Bí o bá wà ní ìsọ̀rí yìí, o ha lè ṣètò àlámọ̀rí rẹ̀ láti ṣèrànwọ́ nínú apá iṣẹ́ ìsìn Jèhófà yìí bí? (Neh. 4:6) Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, gba fọ́ọ̀mù Kingdom Hall Construction Worker Questionnaire kan lọ́wọ́ alábòójútó olùṣalága tàbí akọ̀wé ìjọ rẹ kí o sì fi í lélẹ̀ lójú ẹsẹ̀.
14 Ní àfikún sí i, àwọn arákùnrin tí wọ́n dàgbà dénú nípa tẹ̀mí wà tí wọ́n ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí wọ́n sì lè ṣe àbójútó. Bí ìrírí iṣẹ́ ìkọ́lé tí wọ́n ní tilẹ̀ kéré, àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú lè fi fọ́ọ̀mù lélẹ̀. Ọ̀pọ̀ tí wọ́n wà ní ìsọ̀rí yìí ń ṣèrànwọ́ ní àwọn ẹ̀ka tí kì í ṣe ti ìkọ́lé. A ń dá àwọn mìíràn lẹ́kọ̀ọ́ kí a lè lò wọ́n lọ́nà gbígbòòrò ní ọjọ́ iwájú. A fún àwọn alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ níṣìírí láti ronú jinlẹ̀ bóyá wọ́n lè mú ara wọn wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún iṣẹ́ yìí tí ń mú ìyìn wá fún Baba wa, Jèhófà.—Fi wé 1 Sámúẹ́lì 3:8; Mátíù 4:20.
15 Gbogbo Wa Lè Nípìn-ín: Gbogbo wa lè fi ẹ̀mí rere hàn sí ìgbòkègbodò pàtàkì yìí nípa bíbójútó àyè tí ó bá yọ ọ́ lẹ̀ nínú ìjọ nígbà tí àwọn kan bá ń ṣiṣẹ́ lórí iṣẹ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ní òpin ọ̀sẹ̀ kan. Dájúdájú, kò sí ẹnikẹ́ni nínú wa tí yóò fẹ́ láti kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn òṣìṣẹ́ olùyọ̀ǹda ara ẹni wọ̀nyí lọ́nàkọnà nípa sísọ pé iṣẹ́ onífẹ̀ẹ́ wọn nínú kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kì í ṣe iṣẹ́ ọlọ́wọ̀. (Òwe 24:10; Héb. 6:10) Àmọ́ ṣáá o, a nílò ìwàdéédéé, ìdí sì nìyẹn tí àwọn Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn fi ń ṣiṣẹ́ kára láti ṣe àwọn ètò kí àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni máa bàa kúrò ní ìjọ wọn nílé fún àkókò pípẹ́ jù.
16 Àní bí àwọn ipò àyíká kò bá lè fàyè gba yíyọ̀ǹda ara wa ní ìsopọ̀ pẹ̀lú iṣẹ́ ìkọ́lé gan-an, apá ìhà ṣíṣe kókó kan wà nínú ọ̀ràn náà tí gbogbo wa ti lè ṣàjọpín. Èwo nìyẹn? Fífi “ohun ìní” wa “tí ó níye lórí” bọlá fún Jèhófà. (Òwe 3:9) A lè ní ìgbọ́kànlé pé inú Jèhófà ń dùn gidigidi nígbà tí a bá fún kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba púpọ̀ sí i ní ìtìlẹyìn wa onífẹ̀ẹ́ ní ti ìnáwó. A mọrírì ṣíṣètọrẹ fún Owó Àkànlò Society fún Gbọ̀ngàn Ìjọba gidigidi, bí a sì ṣe ń dá ọ̀pọ̀ ìjọ sílẹ̀ sí i, àìní fún àwọn ilé tuntun àti èyí tí a mú sunwọ̀n sí i ń bá a nìṣó. (Ìṣe 20:35; 2 Kọ́r. 9:6, 7) Ní ọ̀rúndún kìíní, nígbà tí àìní dìde, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún àwọn ará Kọ́ríńtì níṣìírí pé: “Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ ti pọ̀ gidigidi nínú ohun gbogbo, nínú ìgbàgbọ́ àti ọ̀rọ̀ àti ìmọ̀ àti gbogbo ẹ̀mí ìfitaratara-ṣe-nǹkan àti nínú ìfẹ́ wa yìí fún yín, kí ẹ pọ̀ gidigidi nínú ìfúnni onínúrere yìí pẹ̀lú.”—2 Kọ́r. 8:7.
17 Àwọn Àǹfààní Tí Ó Lọ Jìnnà: Ní tòótọ́, Jèhófà ń ràn wá lọ́wọ́ lọ́nà gíga lọ́lá láti kọ́ ọ̀pọ̀ ilé ìjọsìn sí ìyìn rẹ̀. Ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ ń sún àwọn arákùnrin àti arábìnrin ṣiṣẹ́. Èyí gan-an ni irú ìfẹ́ tí Jésù sọ pé yóò fi ojúlówó àwọn ọmọlẹ́yìn òun hàn kedere. (Jòh. 13:34, 35) Gan-an gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe fi ire àwọn ẹlòmíràn ṣáájú tirẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni àwọn náà ṣe ṣe. Ó ṣeé ṣe dáadáa pé, a óò lo ìmúratán àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà àti òye wọn tí ń pọ̀ sí i lọ́nà tí ó túbọ̀ ṣàǹfààní púpọ̀ nínú ayé tuntun Ọlọ́run.
18 Dájúdájú, àwọn tí wọ́n nípìn-ín nínú kíkọ́ àwọn ilé fún ìjọsìn Jèhófà ń rí i pé Sáàmù 127:1 jẹ́ òtítọ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òṣìṣẹ́ tí wọ́n ní òye iṣẹ́ ń yọ̀ǹda àkókò àti ìsapá wọn fún yíyára kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba rírẹwà, ìbùkún Jèhófà ni ó ń mú àṣeyọrí dájú. Lónìí, a nílò àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba púpọ̀ sí i pàápàá. Láti ìgbà tí ó ti bẹ̀rẹ̀, ó ti ṣeé ṣe fún Owó Àkànlò Society fún Gbọ̀ngàn Ìjọba láti ṣèrànwọ́ fún ọ̀pọ̀ ìjọ lórí iṣẹ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn. Ǹjẹ́ kí gbogbo wa máa bá a nìṣó láti yọ̀ǹda àkókò àti “àwọn ohun ìní” wa “tí ó níye lórí” lọ́fẹ̀ẹ́ bí a ti ń retí pé kí Jèhófà bù kún àwọn ìsapá wa.—Òwe 3:9.