ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Tẹsalóníkà 3
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 2 Tẹsalóníkà

      • Ẹ máa gbàdúrà (1-5)

      • Ìkìlọ̀ nítorí àwọn tó ń ṣe ségesège (6-15)

      • Ìkíni tó fi parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ (16-18)

2 Tẹsalóníkà 3:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Wo Àfikún A5.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ro 15:30; 1Tẹ 5:25; Heb 13:18
  • +Iṣe 19:20; 1Tẹ 1:8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    1/15/1991, ojú ìwé 23

2 Tẹsalóníkà 3:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 25:4
  • +Iṣe 28:24; Ro 10:16

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/1/2009, ojú ìwé 8

    5/15/1998, ojú ìwé 10

2 Tẹsalóníkà 3:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Jo 5:3
  • +Lk 21:19; Ro 5:3

2 Tẹsalóníkà 3:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìtọ́ni.”

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “wọ́n.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Tẹ 5:14
  • +1Kọ 11:2; 2Tẹ 2:15; 3:14

2 Tẹsalóníkà 3:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kọ 4:16; 1Tẹ 1:6

2 Tẹsalóníkà 3:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “láìsanwó.”

  • *

    Tàbí “iṣẹ́ àṣekára.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Iṣe 20:34
  • +Iṣe 18:3; 1Kọ 9:14, 15; 2Kọ 11:9; 1Tẹ 2:9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    12/2019, ojú ìwé 5

2 Tẹsalóníkà 3:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 10:9, 10; 1Kọ 9:6, 7
  • +1Kọ 11:1; Flp 3:17

2 Tẹsalóníkà 3:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Tẹ 4:11, 12; 1Ti 5:8

2 Tẹsalóníkà 3:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Tẹ 5:14
  • +1Ti 5:13; 1Pe 4:15

2 Tẹsalóníkà 3:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ef 4:28

2 Tẹsalóníkà 3:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Tẹ 3:6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    A Ṣètò Wa, ojú ìwé 144-145

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    11/2016, ojú ìwé 12

    Ilé Ìṣọ́,

    7/15/1999, ojú ìwé 29-31

2 Tẹsalóníkà 3:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Tẹ 5:14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    11/2016, ojú ìwé 12

    Ilé Ìṣọ́,

    7/15/1999, ojú ìwé 30-31

2 Tẹsalóníkà 3:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 14:27

2 Tẹsalóníkà 3:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kọ 16:21; Kol 4:18

Àwọn míì

2 Tẹs. 3:1Ro 15:30; 1Tẹ 5:25; Heb 13:18
2 Tẹs. 3:1Iṣe 19:20; 1Tẹ 1:8
2 Tẹs. 3:2Ais 25:4
2 Tẹs. 3:2Iṣe 28:24; Ro 10:16
2 Tẹs. 3:51Jo 5:3
2 Tẹs. 3:5Lk 21:19; Ro 5:3
2 Tẹs. 3:61Tẹ 5:14
2 Tẹs. 3:61Kọ 11:2; 2Tẹ 2:15; 3:14
2 Tẹs. 3:71Kọ 4:16; 1Tẹ 1:6
2 Tẹs. 3:8Iṣe 20:34
2 Tẹs. 3:8Iṣe 18:3; 1Kọ 9:14, 15; 2Kọ 11:9; 1Tẹ 2:9
2 Tẹs. 3:9Mt 10:9, 10; 1Kọ 9:6, 7
2 Tẹs. 3:91Kọ 11:1; Flp 3:17
2 Tẹs. 3:101Tẹ 4:11, 12; 1Ti 5:8
2 Tẹs. 3:111Tẹ 5:14
2 Tẹs. 3:111Ti 5:13; 1Pe 4:15
2 Tẹs. 3:12Ef 4:28
2 Tẹs. 3:142Tẹ 3:6
2 Tẹs. 3:151Tẹ 5:14
2 Tẹs. 3:16Jo 14:27
2 Tẹs. 3:171Kọ 16:21; Kol 4:18
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
2 Tẹsalóníkà 3:1-18

Ìwé Kejì sí Àwọn Ará Tẹsalóníkà

3 Lákòótán, ẹ̀yin ará, ẹ máa gbàdúrà fún wa,+ kí ọ̀rọ̀ Jèhófà* lè máa gbilẹ̀ kíákíá,+ kí a sì máa ṣe é lógo, bó ṣe rí lọ́dọ̀ yín, 2 kí a lè gbà wá lọ́wọ́ àwọn ẹni ibi àti èèyàn burúkú,+ nítorí ìgbàgbọ́ kì í ṣe ohun ìní gbogbo èèyàn.+ 3 Àmọ́ olóòótọ́ ni Olúwa, yóò fún yín lókun, yóò sì dáàbò bò yín kúrò lọ́wọ́ ẹni burúkú náà. 4 Yàtọ̀ síyẹn, bí a ṣe wà nínú Olúwa, a ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú yín pé ẹ̀ ń ṣe àwọn ohun tí a sọ fún yín, ẹ ó sì máa ṣe wọ́n nìṣó. 5 Kí Olúwa máa darí ọkàn yín sínú ìfẹ́ Ọlọ́run+ àti sínú ìfaradà+ fún Kristi.

6 Ní báyìí ẹ̀yin ará, à ń fún yín ní ìtọ́ni ní orúkọ Jésù Kristi Olúwa wa, pé kí ẹ fà sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ gbogbo arákùnrin tó ń rìn ségesège,+ tí kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí àṣà* tí ẹ* gbà lọ́dọ̀ wa.+ 7 Nítorí ẹ̀yin fúnra yín mọ bó ṣe yẹ kí ẹ fara wé wa,+ torí a ò ṣe ségesège láàárín yín, 8 bẹ́ẹ̀ la ò jẹ oúnjẹ ẹnikẹ́ni lọ́fẹ̀ẹ́.*+ Kàkà bẹ́ẹ̀, nínú òpò* àti làálàá, à ń ṣiṣẹ́ tọ̀sántòru kí a má bàa gbé ẹrù tó wúwo wọ ìkankan nínú yín lọ́rùn.+ 9 Kì í ṣe pé a ò ní àṣẹ,+ àmọ́ a fẹ́ fi ara wa ṣe àpẹẹrẹ fún yín kí ẹ lè máa fara wé wa.+ 10 Kódà, nígbà tí a wà lọ́dọ̀ yín, a máa ń pa àṣẹ yìí fún yín pé: “Tí ẹnikẹ́ni ò bá fẹ́ ṣiṣẹ́, kó má jẹun.”+ 11 Nítorí a gbọ́ pé àwọn kan ń rìn ségesège láàárín yín,+ wọn ò ṣiṣẹ́ rárá, ṣe ni wọ́n ń tojú bọ ohun tí kò kàn wọ́n.+ 12 Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni a pa àṣẹ fún, tí a sì gbà níyànjú nínú Jésù Kristi Olúwa pé kí wọ́n gbájú mọ́ iṣẹ́ wọn, kí wọ́n sì máa jẹ oúnjẹ tí àwọn fúnra wọn ṣiṣẹ́ fún.+

13 Ní tiyín, ẹ̀yin ará, ẹ má ṣe jẹ́ kó sú yín láti máa ṣe rere. 14 Àmọ́ tí ẹnikẹ́ni ò bá ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ tí a sọ nínú lẹ́tà yìí, ẹ sàmì sí ẹni náà, ẹ má sì bá a kẹ́gbẹ́ mọ́,+ kí ojú lè tì í. 15 Síbẹ̀, ẹ má kà á sí ọ̀tá, àmọ́ ẹ máa gbà á níyànjú+ bí arákùnrin.

16 Tóò, kí Olúwa àlàáfíà máa fún yín ní àlàáfíà nígbà gbogbo àti ní gbogbo ọ̀nà.+ Kí Olúwa wà pẹ̀lú gbogbo yín.

17 Ìkíni èmi Pọ́ọ̀lù nìyí, tí mo fi ọwọ́ ara mi kọ,+ ó jẹ́ àmì nínú gbogbo lẹ́tà mi; bí mo ṣe máa ń kọ̀wé nìyí.

18 Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Olúwa wa Jésù Kristi wà pẹ̀lú gbogbo yín.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́