Ìròyìn Ìṣàkóso Ọlọ́run
Àǹgólà: A dé góńgó tuntun 35,034 akéde ní oṣù December.
Bangladesh: Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ìgbàgbọ́ Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” tí a ṣe ní Dacca ni iye àwọn ènìyàn tí ó jẹ́ 142 pésẹ̀ sí, èyí pọ̀ ju ti ìgbàkígbà rí lọ, a sì batisí ẹni 14. Ìyẹn ju ìlọ́po méjì iye àwọn ènìyàn tí a tí ì batisí rí ní Bangladesh lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.
Benin: Àròpọ̀ iye àwọn tí ó wá sí ọ̀wọ́ Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ìgbàgbọ́ Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” dé 15,633, tí a sì batisí 403 ènìyàn. Ìròyìn oṣù December fi hàn pé a dé góńgó tuntun ti 5,351 àwọn akéde.
Liberia: Ní oṣù December, a ṣe àpéjọpọ̀ alárinrin kan ní Monrovia, tí 5,158 ènìyàn sì pésẹ̀. A ròyìn góńgó tuntun ti 2,127 àwọn akéde ní oṣù yẹn.
Madagascar: A dé ìbísí ìpín 11 nínú ọgọ́rùn-ún nínú iye àwọn akéde ju ìpíndọ́gba ti ọdún tó kọjá ní oṣù December, tí 9,226 akéde sì lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn pápá.
St. Maarten: A ròyìn góńgó tuntun ti àwọn akéde 265 ní oṣù December tí ó fi ìbísí ìpín 10 nínú ọgọ́rùn-ún ju ìpíndọ́gba ti ọdún tó kọjá. Wọ́n darí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé tí ó jẹ́ 310.