Ó Ti Dára Tó Pé Kí A Máa Pésẹ̀ Nígbà Gbogbo!
1 Fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún ní Ìlà-Oòrùn Yúróòpù, a fi òfin de ọ̀pọ̀ àwọn ará wa ọ̀wọ́n láti má ṣe ìpàdé ní gbangba. Ẹ finú wòye bí inú wọn ṣe dùn tó nígbà tí a mú ìfòfindè náà kúrò tí wọ́n sì lè ṣe ìpàdé ní òmìnira!
2 Alábòójútó àyíká kan kọ̀wé nípa ìbẹ̀wò tí ó ṣe sí irú ìjọ kan bẹ́ẹ̀ pé: “Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Tuesday, nígbà tí ìbẹ̀wò mi bẹ̀rẹ̀ gan-an, ẹ̀rọ amúlégbóná bàjẹ́. Ní ìta, gbogbo rẹ̀ tutù bí yìnyín, inú ilé pẹ̀lú sì tutù nini ní nǹkan bí ìwọ̀n ìtutù 5 lórí òṣùwọ̀n Celsius. Àwọn ará jókòó, wọ́n wọ àwọ̀lékè wọn, wọ́n wé gèlè, wọ́n wọ ìbọ̀wọ́, wọ́n dé fìlà, wọ́n sì wọ bàtà àmùtán. Kò sí ẹni tí ó lè ṣí Bíbélì níwọ̀n bí kò ti ṣeé ṣe láti ṣí àwọn ojú ìwé. Bí mo ṣe wà ní ìdúró lórí pèpéle pẹ̀lú aṣọ àwọ̀lékè mi lọ́rùn mi, mo ti fẹ́rẹ̀ẹ́ gan pa, gbogbo ìgbà tí mo bá sì sọ̀rọ̀, mo lè rí i bí ooru ṣe ń jáde lẹ́nu mi. Ṣùgbọ́n ohun tí ó wú mi lórí ni pé n kò gbọ́ kí ẹnikẹ́ni ráhùn. Gbogbo àwọn ará sọ bí ó ṣe gbádùn mọ́ni tí ó sì dára púpọ̀ tó láti pésẹ̀!” Àní àwọn ará wọ̀nyẹn kò tilẹ̀ ronú pé kí àwọn pa ìpàdé yẹn jẹ!
3 Ṣé Bí Ìmọ̀lára Wa Ṣe Rí Nìyẹn? Àwa ha máa ń ṣìkẹ́ àǹfààní náà láti kóra jọpọ̀ fàlàlà ní àwọn ìpàdé ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ wa bí? Tàbí àwa ha máa ń ṣàìnáání àwọn ìpàdé nígbà tí àwọn àyíká ipò rọgbọ bí? Lílọ sí ìpàdé déédéé lè má rọrùn, àkókò sì lè wà nígbà tí a lè ní ìdí tí ó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ fún ṣíṣàìlọ. Ṣùgbọ́n, ẹ má ṣe gbàgbé pé àwọn kan ń bẹ lára wa tí ó jẹ́ pé láìka ọjọ́ ogbó, àìlera líle koko, àléébù ara, ìtòlẹ́sẹẹsẹ iṣẹ́ tí ń tánni lókun, àti àwọn ẹrù iṣẹ́ wíwúwo mìíràn sí, wọ́n mọ̀ pé àwọn ìpàdé ṣe pàtàkì, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ìgbà ni wọ́n máa ń pésẹ̀. Ẹ wo àpẹẹrẹ rere tí ìyẹn jẹ́ fún wa láti tẹ̀ lé!—Fi wé Lúùkù 2:37.
4 Ẹ jẹ́ kí a sọ ọ́ di àṣà wa láti máa ti ìjọsìn tòótọ́ lẹ́yìn nípa lílọ sí gbogbo ìpàdé Kristẹni wa, láti orí àwùjọ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ kékeré dé orí àpéjọpọ̀ ńlá. Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a fi ọwọ́ pàtàkì mú lílọ sí àwọn ìkórajọ wọ̀nyí? Nítorí pé ó jẹ́ àṣẹ Ọlọ́run pé kí a máa kóra jọpọ̀. Ṣùgbọ́n àwọn ìdí pàtàkì mìíràn tún wà. Gbogbo wa nílò àwọn àǹfààní ìtọ́ni Ọlọ́run àti ìrànwọ́ ẹ̀mí mímọ́ èyí tí a ń rí gbà ní àwọn ìpàdé. (Mát. 18:20) Ṣíṣe pàṣípààrọ̀ ìṣírí nígbà tí a bá ń kẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ará wa ń gbéni ró.—Héb. 10:24, 25.
5 Nígbà ìpaláradà náà, Pétérù wí pé, “Olùkọ́ni, ó dára púpọ̀ fún wa láti wà níhìn-ín.” (Lúùkù 9:33) Ó yẹ kí a ní ìmọ̀lára kan náà nípa gbogbo ìpàdé Kristẹni wa. Ní tòótọ́, ó mà dára o pé kí a máa pésẹ̀ nígbà gbogbo!