Ìbẹ̀wò Tí Ó Lè Jẹ́ Ìbùkún
1 Tayọ̀tayọ̀ ni Sákéù fi gba Jésù lálejò sí ilé rẹ̀. Ẹ sì wo ìbùkún tí ìbẹ̀wò yẹn wá yọrí sí!—Lúùkù 19:2-9.
2 Lónìí, gẹ́gẹ́ bí Orí ìjọ, Jésù Kristi pàṣẹ fún àwọn alàgbà láti “máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run.” (1 Pét. 5:2, 3; Jòh. 21:15-17) Ní àfikún sí kíkọ́ni ní àwọn ìpàdé àti mímú ipò iwájú nínú iṣẹ́ ìsìn pápá, àwọn alábòójútó nínú ìjọ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ń pèsè ìrànwọ́ onífẹ̀ẹ́ fún àwọn mẹ́ńbà ìjọ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Nítorí náà, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, o lè retí láti rí àfiyèsí gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn alàgbà, bóyá ní ilé rẹ, ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, nígbà tí ẹ bá jọ wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn pápá, tàbí ní àwọn àkókò mìíràn. Ṣé ó yẹ kí ìbẹ̀wò àwọn alàgbà bà ọ́ lẹ́rù bí? Kò yẹ kí ó rí bẹ́ẹ̀ rárá. Pé wọ́n bẹ̀ ọ́ wò kò túmọ̀ sí pé o kò kúnjú ìwọ̀n ní àwọn ọ̀nà kan. Nígbà náà, kí wá ni ète ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn?
3 Pọ́ọ̀lù sọ pé òun fẹ́ bẹ àwọn ará wò “láti rí bí wọ́n ṣe wà.” (Ìṣe 15:36) Bẹ́ẹ̀ ni, gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn onífẹ̀ẹ́, àwọn alàgbà ní ọkàn-ìfẹ́ gidigidi nínú bí o ṣe wà. Wọ́n ń fẹ́ láti fún ọ ní ìrànwọ́ tẹ̀mí tí ó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ kí ó sì gbé ọ ró. Irú àbójútó tí a ń fún ẹnì kọ̀ọ̀kan bẹ́ẹ̀ ni Olùṣọ́ Àgùntàn wa onífẹ̀ẹ́, Jèhófà, ń fẹ́ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa máa gbádùn.—Ìsík. 34:11.
4 Fi Ayọ̀ Tẹ́wọ́ Gba Ìbẹ̀wò Àwọn Alàgbà: Ohun tí ó jẹ́ góńgó Pọ́ọ̀lù fún bíbẹ àwọn ará wò jẹ́ láti ‘fi ẹ̀bùn ẹ̀mí díẹ̀ fún wọn, kí a lè fìdí wọn múlẹ̀ gbọn-in, kí pàṣípààrọ̀ ìṣírí sì lè wà.’ (Róòmù 1:11, 12) Gbogbo wa nílò ìṣírí tẹ̀mí ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn líle koko wọ̀nyí, a sì nílò ìrànwọ́ láti máa bá a nìṣó ní fífìdímúlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́. Ìdáhùnpadà rẹ lọ́nà rere sí ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn yóò yọrí sí pàṣípààrọ̀ ìṣírí dájúdájú.
5 Máa fi ìmọrírì hàn fún ọ̀pọ̀ àǹfààní tí ìwọ yóò jèrè láti inú iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn ti àwọn alàgbà. Bí àwọn ọ̀ràn tàbí ìbéèrè kan bá wà tí o ń ṣàníyàn nípa wọn, rántí pé àwọn alàgbà wà nínú ìjọ láti ṣèrànwọ́. Má ṣe lọ́tìkọ̀ láti bá wọn jíròrò àwọn ọ̀ràn èyíkéyìí tí ó lè máa ní ipa lórí ìlera rẹ nípa tẹ̀mí. Máa fi ìmọrírì hàn fún ìṣètò onífẹ̀ẹ́ yìí láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, sì máa yọ̀ nínú àwọn ìbùkún tí irú ìbẹ̀wò bẹ́ẹ̀ lè mú wá.