Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún July
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní July 6
Orin 110
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Àwọn Ìfilọ̀ tí a yàn láti inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Sọ̀rọ̀ nípa ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá ti oṣù March ti orílẹ̀-èdè àti ti ìjọ àdúgbò.
15 min: “Ó Ti Dára Tó Pé Kí A Máa Pésẹ̀ Nígbà Gbogbo!” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Fi àlàyé inú Jí! December 8, 1988, ojú ìwé 19 sí 21, kún un láti fún àwọn ọ̀dọ́ níṣìírí láti máa lọ sí ìpàdé déédéé.
20 min: “Ó Yẹ Kí Àwọn Aládùúgbò Wa Gbọ́ Ìhìn Rere.” A óò fi àdìpọ̀ ìwé méjì tàbí mẹ́rin lọni ní ẹ̀dínwó. Ṣètò akéde dídáńgájíá méjì tàbí mẹ́ta láti ṣàyẹ̀wò àwọn àbá náà, kí wọ́n lo ìwé Itan Bibeli. Tẹnu mọ́ àwọn kókó tí ó lè gbéṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ àdúgbò. Tẹnu mọ́ góńgó bíbẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ìwé pẹlẹbẹ Béèrè tàbí nínú ìwé Ìmọ̀. Ṣàṣefihàn ìgbékalẹ̀ àkọ́kọ́, kí ìpadàbẹ̀wò tẹ̀ lé e kí a sì fi ìkẹ́kọ̀ọ́ lọni.
Orin 73 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní July 13
Orin 116
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Fún gbogbo ìjọ níṣìírí láti ronú jinlẹ̀ lórí fíforúkọsílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní oṣù August tí yóò ní òpin ọ̀sẹ̀ márùn-ún kíkúnrẹ́rẹ́.
15 min: “Ta Ló Gbójúgbóyà Láti Jẹ Ilé Àwọn Opó Run?” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Kí alàgbà bójú tó o.
20 min: Ẹ̀mí Ayé Ha Ń Bà Ọ́ Jẹ́ Bí? Ọ̀rọ̀ àsọyé láti ẹnu alàgbà, tí a gbé karí Ilé Ìṣọ́, October 1, 1997, ojú ìwé 25 sí 29.
Orin 182 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní July 20
Orin 18
8 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn ìnáwó.
12 min: “Ìbẹ̀wò Tí Ó Lè Jẹ́ Ìbùkún.” Ìjíròrò láàárín alàgbà méjì. Ṣàlàyé ète iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn gẹ́gẹ́ bí a ṣe ṣàgbéyẹ̀wò rẹ̀ nínú Ilé-Ìṣọ́nà, September 15, 1993, ojú ìwé 20 sí 23. Fi ọ̀yàyà fún ìjọ níṣìírí láti fojú sọ́nà fún ìbẹ̀wò àwọn alàgbà.
25 min: “Iṣẹ́ Ìsìn Aṣáájú Ọ̀nà—Ǹjẹ́ O Lè Ṣe é?” (Ìpínrọ̀ 1 sí 14) Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn sọ ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ ṣókí, ó fún gbogbo ìjọ níṣìírí láti ronú jinlẹ̀ lórí ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà déédéé. Lẹ́yìn náà, ó jíròrò ìbéèrè 1, ó fi gbólóhùn láti inú “Enthusiastic Pioneer Spirit” (Ẹ̀mí Onítara ti Aṣáájú Ọ̀nà) nínú ìwé 1998 Yearbook, ojú ìwé 104 àti 105 kún un. Mẹ́ńbà ìjọ méjì tàbí mẹ́ta tí wọ́n nírìírí ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà dara pọ̀ mọ́ ọn lórí pèpéle láti jíròrò ìbéèrè 2. Wọ́n jíròrò ojú ìwòye tí ó gbéṣẹ́ tí ó sì jóòótọ́ ní ti bí ó ṣe ṣeé ṣe tó láti máa gbọ́ bùkátà ara wọn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà. Lẹ́yìn náà, òbí méjì dara pọ̀ mọ́ àwùjọ náà láti jíròrò ìbéèrè 3. Wọ́n sọ ìdí rere tí ó fi yẹ kí àwọn èwe ronú jinlẹ̀ nípa fífi iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ṣiṣẹ́ ṣe. Fún gbogbo ìjọ níṣìírí láti wá sí Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ọ̀sẹ̀ tí ń bọ̀ nígbà tí a óò ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ìbéèrè yòókù.
Orin 80 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní July 27
Orin 155
15 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Rán gbogbo ìjọ létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn fún oṣù July sílẹ̀. Ṣèfilọ̀ ètò fún iṣẹ́ ìsìn fún òpin ọ̀sẹ̀ àkọ́kọ́ nínú oṣù August, kí o sì fún gbogbo ìjọ níṣìírí láti lọ́wọ́ nínú rẹ̀.
30 min: “Iṣẹ́ Ìsìn Aṣáájú Ọ̀nà—Ǹjẹ́ O Lè Ṣe é?” (Ìpínrọ̀ 15 sí 25) Ọ̀rọ̀ àsọyé àti ìjíròrò tí alàgbà kan darí. Ṣètò ṣáájú àkókò kí àwọn aṣáájú ọ̀nà àti àwọn tí ó ti ṣe aṣáájú ọ̀nà sẹ́yìn ṣàjọpín àwọn ọ̀rọ̀ tí a sọ látọkànwá ní ìdáhùn sí ìbéèrè 4 àti 5. Wọ́n tẹnu mọ́ bí ó ti yẹ láti ní ìṣètò tí ó dára kí a sì máa tẹ̀ lé e, wọ́n sọ àpẹẹrẹ ìṣètò iṣẹ́ ìsìn ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ gbígbéṣẹ́ tí ó ń ṣàṣeyọrí ní tòótọ́. Alàgbà parí ọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ àsọyé tí ń súnni ṣiṣẹ́ tí ó dáhùn ìbéèrè 6. Ìbẹ̀rẹ̀ ọdún iṣẹ́ ìsìn ní September 1 jẹ́ àkókò tí ó dára fún àwọn aṣáájú ọ̀nà tuntun láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún wọn. Wọ́n lè gba ìwé ìwọṣẹ́ lọ́dọ̀ èyíkéyìí lára mẹ́ńbà Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ.
Orin 51 àti àdúrà ìparí.