Ta Ló Gbójúgbóyà Láti Jẹ Ilé Àwọn Opó Run?
1 ‘Àwọn ni wọ́n ń jẹ ilé àwọn opó run . . . wọn yóò sì gba ìdájọ́ tí ó wúwo jù.’ (Máàkù 12:40) Èé ṣe tí Jésù fi sọ gbólóhùn yìí? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwà ìgbéraga àti ìwà ìbàjẹ́ àwọn akọ̀wé òfin ní ìgbà ayé rẹ̀ ni ó ń jíròrò, síbẹ̀ ó ṣe kedere pé bí ó ṣe mẹ́nu kan àwọn opó nínú àyíká ọ̀rọ̀ yìí tẹnu mọ́ bí dídu irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀tọ́ wọn ṣe burú tó. Ó lè mú kí Jèhófà fúnra rẹ̀ dáni lẹ́jọ́ lọ́nà tí kò bára dé.—Aísá. 1:23.
2 Ṣùgbọ́n, kí ni ‘jíjẹ ilé àwọn opó rún’ túmọ̀ sí? Gbé ọ̀ràn wọ̀nyí yẹ̀ wò. Ìwé ìròyìn kan ròyìn pé nígbà tí ọkọ obìnrin kan kú, àwọn àna rẹ̀ pín ilé òkú náà láàárín ara wọn, wọ́n sì fẹ̀sùn kan opó náà pé òun ló pa ọkọ rẹ̀. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó wákàtí mẹ́ta tí wọ́n fi ń bí i ní ọ̀pọ̀ ìbéèrè. Lẹ́yìn náà, wọ́n sọ pé kí ó mu omi tí wọ́n fi wẹ òkú náà. Wọ́n gbìyànjú láti fagbára mú un láti fẹ́ ẹnì kan tí ó jẹ́ àna. Nígbà tí ó kọ̀ jálẹ̀, wọ́n lé e kúrò nínú ẹbí, wọ́n sì fi í sílẹ̀ kí ó máa gbọ́ bùkáta ara rẹ̀ àti ti àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́ta tí kò ní baba mọ́. Nínú ọ̀ràn mìíràn, opó kan sọ pé ojú òun rí màbo lọ́wọ́ àwọn alàgbà kan nínú ìjọ pàápàá nígbà tí wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé ogún ọkọ òun nítorí àwáwí tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ pé wọ́n fẹ́ bójú tó ọ̀nà tí òun yóò máa gbà lo nǹkan ìní náà. Abájọ tí opó kan fi sọ pé ‘jíjẹ́ opó dà bí gbígbé ní orílẹ̀-èdè kan níbi tí kò sí ẹni tí ń sọ èdè rẹ, orílẹ̀-èdè kan tí wọ́n ti kà ọ́ sí ẹni tí kò yẹ kí a sún mọ́.’
3 Nígbà tí ọkọ wọn bá kú, àwọn opó ni a mọ̀ pé wọ́n máa ń ní ìmọ̀lára ìbínú, ìjákulẹ̀, ìroragógó wàhálà, ìnìkanwà, àti ìdàrúdàpọ̀ ọkàn nígbà mìíràn. Pé kí ẹnì kan wá fi hílàhílo fífi ọ̀nà ìgbọ́bùkátà duni kún àwọn ìṣòro wọ̀nyí dà bí fífún okùn mọ́ ẹnì kan tí kò lókun nínú lọ́rùn. Ó ń múni banú jẹ́. Ojú kòkòrò, àṣìlò agbára, àìmọ̀kan, àti ìbẹ̀rù àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ jẹ́ díẹ̀ nínú àwọn nǹkan tí ń mú kí àwọn ènìyàn máa pọ́n àwọn opó àti ọmọ òrukàn lójú. Ṣùgbọ́n, kò sí èyíkéyìí nínú àwọn àwáwí wọ̀nyí tí ó mú kí ẹni tí ó bá jẹ̀bi bọ́ lọ́wọ́ ìbínú Ọlọ́run. (Ẹ́kís. 22:22, 23) Ìdí nìyí tí gbogbo Kristẹni fi gbọ́dọ̀ wà lójúfò láti má ṣe pọ́n àwọn opó àti ọmọ òrukàn lójú tàbí kí a lù wọ́n ní jìbìtì.
4 Ó báni nínú jẹ́ láti sọ pé, títí di ọjọ́ ikú wọn, àwọn Kristẹni ọkọ kan, fi kún ìṣòro àwọn opó wọn nípa fífi ọrọ̀ wọn pa mọ́ tàbí nípa ṣíṣàìjẹ́ kí aya wọn mọ ibi tí àkáǹtì wọn ní báǹkì, ìbánigbófò, àti àwọn ohun ìní ti ara mìíràn wà. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, wọ́n kùnà láti ṣe ìwé ìpíngún tí yóò ṣàlàyé bí a ṣe ní láti pín dúkìá wọn, bóyá wọn kò fẹ́ kí aya wọn (àti àwọn ọmọ) jogún ohunkóhun lẹ́yìn ikú wọn. Láìmọ̀ọ́mọ̀, wọ́n tipa bẹ́ẹ̀ fi aya (àti àwọn ọmọ) wọn sílẹ̀ fúnyà jẹ. Èyí fi hàn pé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ní ti gidi kò nífẹ̀ẹ́ aya wọn gẹ́gẹ́ bí ara àwọn fúnra wọn.—Éfé. 5:28, 29.
5 Ṣùgbọ́n, lọ́nà tí ó gboríyìn, àwọn mìíràn kọ ìwé ìpíngún ṣíṣe kedere tí ó ń fi ìpèsè tí wọ́n fẹ́ kí a ṣe fún ìdílé wọn gan-an hàn bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé àwọn kú. Ìrírí ti fi hàn pé èyí jẹ́ ìṣètò onífẹ̀ẹ́ tí ó sì mọ́gbọ́n dání. Ó ń dènà ìnilára èyíkéyìí tí ó lè ṣẹlẹ̀. Ní gidi, ó jẹ́ ‘ọgbọ́n tí a fi hàn ní olódodo nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ rẹ̀.’—Mát. 11:19; 2 Kọ́r. 12:14; 1 Tím. 5:8.
6 Ọ̀kan lára àwọn ohun tí Jèhófà ṣe dẹ́bi fún àwọn “apàṣẹwàá Sódómù” jẹ́ nítorí níni àwọn opó lára. (Aísá. 1:10, 17) Lẹ́yìn ìyẹn, òun kọ̀ láti tẹ́tí sí ohun tí wọ́n ń tọrọ àti ẹ̀bẹ̀ wọn. Híhùwà sí àwọn opó àti ọmọ aláìníbaba lọ́nà tí kò tọ́ lè yọrí sí pípàdánù àwọn àkànṣe àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ. Ìdájọ́ náà tilẹ̀ lè túbọ̀ wúwo fún àwọn tí ó jẹ́ pé ìwà àìtọ́ tí wọ́n hù sí àwọn opó tàbí sí àwọn ọmọ òrukàn ní jìbìtì àti ojú kòkòrò nínú. Ohun tí ó tọ́ ni bí a bá yọ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lẹ́gbẹ́ kúrò nínú ìjọ Kristẹni àyàfi bí wọ́n bá ronú pìwà dà ní tòótọ́ tí wọ́n sì yí padà. Nítorí náà, kí àwọn alàgbà máa wà lójúfò láti “gba ẹjọ́” àwọn opó “rò” kí wọ́n sì dáàbò bò wọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹni bí ìkokò tàbí afiniṣèjẹ.—Aísá. 1:17; Máàkù 12:40; 1 Kọ́r. 5:10, 11; 6:10; 1 Tím. 3:8.
7 Ǹjẹ́ kí gbogbo wa múra tán, kí a sì nífẹ̀ẹ́ láti “máa bójú tó àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn opó nínú ìpọ́njú wọn,” kí a sì máa tipa bẹ́ẹ̀ jọ́sìn Jèhófà, Ọlọ́run wa tí ó bìkítà, lọ́nà tí ó tẹ́wọ́ gbà.—Ják. 1:27.