Àwọn Ìfilọ̀
◼ Àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni ní July sí September: Ìfilọni àkànṣe ti àdìpọ̀ oríṣi ìwé méjì fún ₦40 àti àdìpọ̀ ìwé mẹ́rin fún ₦80, tí ẹ lè béèrè fún láti ẹ̀ka ilé iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàlàyé nínú lẹ́tà wa ti March 23, 1998. Bákan náà, a lè fi èyíkéyìí nínú àwọn ìwé olójú ewé 192 ní èdè èyíkéyìí tí ìjọ lè ní lọ́wọ́, yàtọ̀ sí Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé, Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ Sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-ojiṣẹ Wa àti Iwe-Amọna Ile Ẹkọ Iṣẹ Ojiṣẹ Ijọba Ọlọrun lọni ní àkànṣe ọrẹ ₦20. Ẹ lè béèrè fún ẹ̀dínwó lórí àwọn ìwé wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàlàyé nínú lẹ́tà wa. October: Àsansílẹ̀ owó fún Ilé Ìṣọ́ tàbí Jí! tàbí fún ìwé ìròyìn méjèèjì.
◼ Bí oṣù August ti ní òpin ọ̀sẹ̀ márùn-ún kíkúnrẹ́rẹ́, ó jẹ́ àkókò tí ó dára fún ọ̀pọ̀ láti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́.
◼ Bẹ̀rẹ̀ láti oṣù September, àwọn alábòójútó àyíká yóò máa sọ ọ̀rọ̀ àsọyé fún gbogbo ènìyàn tí a pe àkọlé rẹ̀ ní “Ìwọ Ha Ń Bá Ọlọ́run Rìn Bí?”