Ìròyìn Ìṣàkóso Ọlọ́run
Gánà: A ròyìn góńgó tuntun 55,539 akéde ní oṣù April—ìpíndọ́gba ìbísí ìpín mẹ́sàn-án nínú ọgọ́rùn-ún ju ti ọdún tó kọjá. Iye tí ó wá sí Ìṣe Ìrántí ju 200,000 lọ.
Malawi: Àwọn ìjọ ti ju 600 níbẹ̀ báyìí. Èyí jẹ́ ìbísí ìpín 50 nínú ọgọ́rùn-ún ju iye ìjọ tí ó wà nígbà tí a ṣe ìfòfindè ní October 1967.