Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún September
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní September 7
Orin 28
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Àwọn Ìfilọ̀ tí a yàn láti inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Ṣàyẹ̀wò àpótí náà, “Àbá Kan.”
15 min: “A Lè Ṣe Àwọn Iṣẹ́ Tí Ó Tóbi Jù.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Fún gbogbo ará níṣìírí láti gbé àwọn góńgó iṣẹ́ ìsìn tí ọwọ́ lè tẹ̀ kalẹ̀ ní ọdún iṣẹ́ ìsìn tuntun kí wọ́n sì ṣiṣẹ́ kára láti lé wọn bá.—Wo Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-Ojiṣẹ Wa, ojú ìwé 116 sí 118.
20 min: “Àwọn Aṣáájú Ọ̀nà Ń Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́.” Alàgbà kan ṣàlàyé pé ní àfikún sí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí a ń pèsè ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run, a ti ṣe àwọn ètò fún àwọn aṣáájú ọ̀nà láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Kí ó béèrè àwọn ìbéèrè tí a gbé karí àpilẹ̀kọ náà, kí ó sì ké sí àwùjọ láti ṣe àlàyé, ní pàtàkì kí ó ké sí àwọn aṣáájú ọ̀nà àti àwọn akéde tí wọ́n ti lọ́wọ́ nínú ìṣètò náà. Kí ó ṣàgbéyẹ̀wò bí a ṣe lè ṣe àṣeyọrí tí ó dára jù lọ nínú rẹ̀. Àwọn aṣáájú ọ̀nà lè ṣàlàyé bí àwọn ṣe gbádùn nínípìn-ín nínú ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ àti àǹfààní tí àwọn ti rí láti inú rẹ̀. Àwọn akéde tí a ti ràn lọ́wọ́ lè sọ bí àwọn ṣe mọrírì ìpèsè onífẹ̀ẹ́ yìí tó kí wọ́n sì sọ àwọn kókó tí ó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe àṣeyọrí púpọ̀ gan-an tí ó sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí ìdùnnú nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́.
Orin 172 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní September 14
Orin 160
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn Ìṣàkóso Ọlọ́run.
15 min: “Pípèsè fún Agbo Ilé Ẹni.” Ọ̀rọ̀ àsọyé tí a gbé karí Ilé Ìṣọ́, October 1, 1996, ojú ìwé 29 sí 31. Kí alàgbà kan tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí ó tóótun tí ó jẹ́ olórí ìdílé tí ó sì jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ bójú tó o, Tẹnu mọ́ ìdí tí ó fi yẹ kí gbogbo àwùjọ fi ọwọ́ pàtàkì mú ọmọ bíbí tí a tẹ́wọ́ gba ẹrù iṣẹ́ rẹ̀ ní àkókò òpin yìí.
20 min: “Àpéjọpọ̀ Àgbègbè ‘Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tí Ọlọ́run Fẹ́’ ti 1998.” (Ìpínrọ̀ 1 sí 16) Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ka ìpínrọ̀ 10 àti 11. Tẹnu mọ́ bí Ìwé Mímọ́ ṣe fi hàn pé ó ṣe pàtàkì láti pa ìrísí àti ìwà tí ó bójú mu ti Kristẹni wa mọ́ kí a sì bójú tó àwọn ọmọ wa lọ́nà yíyẹ.
Orin 48 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní September 21
Orin 122
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn ìnáwó.
20 min: “Àpéjọpọ̀ Àgbègbè ‘Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tí Ọlọ́run Fẹ́’ ti 1998.” (Ìpínrọ̀ 17 sí 22) Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ka ìpínrọ̀ 17 àti ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a tọ́ka sí. Tẹnu mọ́ bí ó ṣe yẹ kí a wà létòlétò kí a sì fi ìgbatẹnirò hàn fún àwọn ẹlòmíràn, pàápàá nígbà tí ó bá kan ọ̀ràn àyè ìjókòó. Fi ọ̀rọ̀ àsọyé ṣókí tí ń ṣàyẹ̀wò “Àwọn Ìránnilétí Àpéjọpọ̀” parí ọ̀rọ̀ rẹ.
15 min: “Mọ Àwọn Ará Ní Àmọ̀dunjú.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Fi àlàyé láti inú Ilé-Ìṣọ́nà ti October 1, 1988, ojú ìwé 10 àti 11 kún un. Fún gbogbo àwọn ará níṣìírí láti lo àtinúdá láti túbọ̀ di ojúlùmọ̀ ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì.
Orin 34 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní September 28
Orin 17
12 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Rán gbogbo akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá ti oṣù September sílẹ̀. Fún gbogbo akéde níṣìírí láti wéwèé láti ṣe iṣẹ́ ilé dé ilé púpọ̀ sí i ní oṣù October láti mú kí ìpínkiri ìwé ìròyìn pọ̀ sí i. Tọ́ka sí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti October 1996, ojú ìwé 8, fún àwọn àbá nípa bí a ṣe lè múra ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀. Ṣàṣefihàn kan nípa bí a ṣe lè fi àwọn ìwé ìròyìn lọ́ọ́lọ́ọ́ lọni. Gba àwọn ìwé ìròyìn fún ìgbòkègbodò òpin ọ̀sẹ̀.
20 min: “Àwọn Alábòójútó Tí Ń Mú Ipò Iwájú—Alábòójútó Iṣẹ́ Ìsìn.” Ọ̀rọ̀ àsọyé láti ẹnu alábòójútó iṣẹ́ ìsìn. Lẹ́yìn ṣíṣàyẹ̀wò ojúṣe rẹ̀, kí ó ṣàlàyé àwọn ọ̀nà pàtó tí ìjọ fi lè fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní àdúgbò pọ̀ sí i kí ó sì gbéṣẹ́ sí i.
13 min: Kí Ní Ń Sọni Di Akéde Ìjọ Rere? Ọ̀rọ̀ àsọyé, pẹ̀lú ìkópa díẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwùjọ. Kò pọndandan pé kí a ní agbára tàbí ẹ̀bùn tí ó ṣàrà ọ̀tọ̀; kàkà bẹ́ẹ̀, ó dára gidigidi pé kí gbogbo wa ní ìṣarasíhùwà onímùúratán tí ń fi ìfẹ́, ìrẹ̀lẹ̀, ìtara, àti ìmọrírì hàn. Ké sí àwùjọ láti sọ àwọn ìdí tí a ṣe ń fẹ́ àwọn ohun tí ó tẹ̀ lé e yìí: (1) ẹ̀mí ọ̀yàyà, (2) wíwá sí ìpàdé déédéé àti kíkópa nínú wọn, (3) mímúratán láti tẹ́wọ́ gba àwọn iṣẹ́ àyànfúnni kí a sì ṣe wọ́n, (4) fífọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn alàgbà àti pẹ̀lú ìṣètò tí a bá ṣe fún ìjọ, (5) ọkàn-ìfẹ́ tòótọ́ ní ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́, àti (6) kíkópa déédéé nínú iṣẹ́ ìsìn pápá àti ríròyìn ní kánmọ́ lóṣooṣù.
Orin 25 àti àdúrà ìparí.