A Lè Ṣe Àwọn Iṣẹ́ Tí Ó Tóbi Jù
1 Iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù Kristi kún fún iṣẹ́ tí ó tayọ. Ó bọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà iṣẹ́ ìyanu, ó mú ọ̀pọ̀ lára dá, ó sì jí àwọn kan dìde kúrò nínú ikú. (Mát. 8:1-17; 14:14-21; Jòh. 11:38-44) Ìgbòkègbodò rẹ̀ gba àfiyèsí odindi orílẹ̀-èdè. Síbẹ̀, ní alẹ́ tí ó ṣáájú ikú rẹ̀, ó sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ olùṣòtítọ́ pé: “Ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú mi, ẹni yẹn pẹ̀lú yóò ṣe àwọn iṣẹ́ tí èmi ń ṣe; yóò sì ṣe àwọn iṣẹ́ tí ó tóbi ju ìwọ̀nyí.” (Jòh. 14:12) Báwo ni a ṣe lè ṣe àwọn iṣẹ́ tí ó “tóbi jù?”
2 Nípa Kíkárí Ìpínlẹ̀ Tí Ó Pọ̀ Ju Tirẹ̀: Ìgbòkègbodò Jésù kò kọjá Palẹ́sìnì, nígbà tí ó sì jẹ́ pé ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ láti jẹ́rìí “títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé,” tí ó jìnnà ré kọjá ibi tí Jésù fúnra rẹ̀ ti wàásù. (Ìṣe 1:8) Iṣẹ́ ìwàásù tí ó bẹ̀rẹ̀ ti kárí ayé ní báyìí, ó ti dé 232 ilẹ̀. (Mát. 24:14) Ìwọ ha ń ní ìpín kíkún nínú ṣíṣiṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ tí a yàn fún ìjọ rẹ bí?
3 Nípa Dídé Ọ̀dọ̀ Àwọn Ènìyàn Púpọ̀ Ju Tirẹ̀: Àwọn ọmọ ẹ̀yìn tí Jésù fi sílẹ̀ láti máa bá iṣẹ́ ìwàásù náà nìṣó kò tó nǹkan. Bí ó ti wù kí ó rí, nítorí fífi tí wọ́n fi ìtara jẹ́rìí ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, ó tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọkàn tí ó tẹ́wọ́ gba òtítọ́ tí a sì batisí ní ọjọ́ yẹn. (Ìṣe 2:1-11, 37-41) Ṣíṣàkójọ àwọn tí ó “ní ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun” ń bá a nìṣó títí di ọjọ́ wa, tí a ń batisí èyí tí ó ju 1,000 ènìyàn lójoojúmọ́ ní ìpíndọ́gba. (Ìṣe 13:48) Ìwọ ha ń ṣe gbogbo ohun tí o lè ṣe láti dé ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí ó jẹ́ aláìlábòsí-ọkàn níbikíbi tí o bá ti lè rí wọn kí o sì padà ṣiṣẹ́ lórí ọkàn-ìfẹ́ tí wọ́n fi hàn bí ó bá ti ṣeé ṣe kí ó yá tó?
4 Nípa Fífi Àkókò Gígùn Ju Tirẹ̀ Wàásù: Ọdún mẹ́ta àti ààbọ̀ péré ni Jésù fi ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Àkókò tí ọ̀pọ̀ jù lọ lára wa ti fi ń wàásù ti gùn jù bẹ́ẹ̀ lọ. Láìka bí àkókò tí a óò gbà wá láyè láti máa bá iṣẹ́ yìí lọ yóò ṣe gùn tó, a kún fún ìmoore pé a ń ran ọmọ ẹ̀yìn tuntun kọ̀ọ̀kan lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ sí tọ ojú ọ̀nà tí ó lọ sí ìyè. (Mát. 7:14) Ìwọ ha ń ní púpọ̀ láti ṣe lóṣooṣù nínú iṣẹ́ Olúwa bí?—1 Kọ́r. 15:58.
5 A lè ní ìgbọ́kànlé pé bí Jésù ṣe ń tì wá lẹ́yìn, a óò túbọ̀ ṣe àwọn iṣẹ́ tí ó tóbi jù gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tòótọ́.—Mát. 28:19, 20.