Àwọn Aṣáájú Ọ̀nà Ń Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́
1 Jésù wí pé: “Ìkórè pọ̀, ní tòótọ́, ṣùgbọ́n àwọn òṣìṣẹ́ kéré níye. Nítorí náà, ẹ bẹ Ọ̀gá ìkórè kí ó rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde sínú ìkórè rẹ̀.” Níwọ̀n bí àwọn olùkórè ọ̀rúndún kìíní ti kéré níye tí wọ́n sì ní ìpínlẹ̀ púpọ̀ láti kárí, Jésù ì bá ti darí wọn láti mú ìhìn rere dé ọ̀dọ̀ ènìyàn púpọ̀ bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó nípa rírán wọn jáde lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó “rán wọn jáde ní méjìméjì.” (Lúùkù 10:1, 2) Èé ṣe tí ó fi rán wọn ní méjìméjì?
2 Ọmọ ẹ̀yìn tuntun ni wọ́n, wọn kò sì ní ìrírí. Nípa ṣíṣiṣẹ́ pa pọ̀, wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ ara wọn kí wọ́n sì fún ẹnì kìíní-kejì níṣìírí. Bí Sólómọ́nì ṣe sọ ọ́, “ẹni méjì sàn ju ẹnì kan.” (Oníw. 4:9, 10) Lẹ́yìn ìgbà tí a tú ẹ̀mí mímọ́ jáde ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa pàápàá, Pọ́ọ̀lù, Bánábà, àti àwọn mìíràn bá àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn jáde nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. (Ìṣe 15:35) Ẹ wo irú àǹfààní tí ó ní láti jẹ́ fún àwọn kan pé kí irú àwọn ọkùnrin dídáńgájíá bẹ́ẹ̀ fúnra wọn dá wọn lẹ́kọ̀ọ́!
3 Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Tí Ó Dára Púpọ̀: Gẹ́gẹ́ bí ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ti ọ̀rúndún kìíní, ìjọ Kristẹni ti òde òní jẹ́ ètò àjọ tí ń wàásù. Ó tún ń pèsè ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún wa. Ní ẹnì kọ̀ọ̀kan, ó yẹ kí a ní ìfẹ́-ọkàn tí ó jinlẹ̀ láti sọ ìhìn rere náà fúnni lọ́nà gbígbéṣẹ́ bí ó bá ti ṣeé ṣe tó. Ìrànwọ́ wà lárọ̀ọ́wọ́tó kí àwọn akéde púpọ̀ sí i lè sunwọ̀n sí i nínú bí wọ́n ṣe gbéṣẹ́ sí.
4 Ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba tí a ṣe lẹ́nu lọ́ọ́lọ́ọ́, Society kéde ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí ó wà fún àwọn aṣáájú ọ̀nà láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá. Àìní ha wà fún èyí bí? Bẹ́ẹ̀ ni, ó wà. A ti batisí akéde tí ó ju mílíọ̀nù kan lọ ní ọdún mẹ́ta tí ó kọjá, ọ̀pọ̀ lára àwọn wọ̀nyí sì nílò ìdálẹ́kọ̀ọ́ láti túbọ̀ gbéṣẹ́ sí i nínú iṣẹ́ ìwàásù. Àwọn wo ni a lè lò láti kájú àìní yìí?
5 Àwọn aṣáájú ọ̀nà alákòókò kíkún lè ṣèrànwọ́. Ètò àjọ Jèhófà ń pèsè ọ̀pọ̀ ìmọ̀ràn àti ìdálẹ́kọ̀ọ́ fún wọn. Àwọn aṣáájú ọ̀nà máa ń gba ìtọ́ni tí a mú kí ó bá àwọn àìní wọn mu nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Aṣáájú Ọ̀nà tí ó máa ń gba ọ̀sẹ̀ méjì. Wọ́n tún ń jàǹfààní láti inú ìpàdé pẹ̀lú àwọn alábòójútó àyíká àti ti àgbègbè, títí kan láti inú ìdarísọ́nà àwọn alàgbà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo àwọn aṣáájú ọ̀nà ni ó ní ìrírí bí ti Pọ́ọ̀lù àti Bánábà, wọ́n ti rí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ṣíṣeyebíye gbà tí wọ́n láyọ̀ láti ṣàjọpín wọn.
6 Ta Ni Yóò Jàǹfààní? A ha fi ìtòlẹ́sẹẹsẹ yìí mọ sórí àwọn akéde tuntun tàbí sórí àwọn tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ batisí bí? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá! Àwọn ọmọdé àti àwọn àgbà tí wọ́n ti mọ òtítọ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún wà ṣùgbọ́n tí wọn yóò mọrírì rírí ìrànwọ́ gbà nípa àwọn apá kan nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Àwọn kan ń ṣe dáadáa jù lọ nínú fífi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ sóde ṣùgbọ́n ó ṣòro fún wọn láti ṣe àwọn ìpadàbẹ̀wò tàbí kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwọn mìíràn lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú ìdẹ̀rùn ṣùgbọ́n wọ́n ń rí i pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àwọn kò tẹ̀ síwájú. Kí ni ó ń fa àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà sẹ́yìn? A lè sọ pé kí àwọn aṣáájú ọ̀nà onírìírí ṣèrànwọ́ ní àgbègbè wọ̀nyí. Àwọn aṣáájú ọ̀nà kan gbéṣẹ́ nínú mímú kí ọkàn-ìfẹ́ dàgbà, nínú bíbẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tí wọ́n sì darí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tuntun sí ètò àjọ náà. Ìrírí wọn yóò ṣèrànwọ́ nínú ìṣètò tuntun yìí.
7 O ha rí i pé ìtòlẹ́sẹẹsẹ rẹ kì í jẹ́ kí o ṣètìlẹ́yìn fún ìpàdé tí ìjọ máa ń ṣe déédéé fún iṣẹ́ ìsìn pápá bí ìwọ yóò ṣe fẹ́ tó? Aṣáájú ọ̀nà kan lè bá ọ ṣiṣẹ́ nígbà mìíràn tí àwọn akéde yòókù kò bá sí lárọ̀ọ́wọ́tó.
8 Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Dáadáa Pọndandan: Lẹ́ẹ̀mejì lọ́dún, àwọn alàgbà yóò ṣètò kí àwọn akéde tí ó bá ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan lọ́wọ́ nínú ìṣètò Àwọn Aṣáájú Ọ̀nà Ń Ran Àwọn Ẹlòmíràn lọ́wọ́. Bí o bá gbà láti gba irú ìrànwọ́ bẹ́ẹ̀, pàdé pọ̀ pẹ̀lú aṣáájú ọ̀nà tí ó jẹ́ akéde tí a yàn láti ràn ọ́ lọ́wọ́, ẹ ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ gbígbéṣẹ́ fún iṣẹ́ ìsìn kí ẹ sì tẹ̀ lé e. Ẹ pa àdéhùn kọ̀ọ̀kan mọ́. Bí ẹ ṣe ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀, máa kíyè sí àwọn ọ̀nà gbígbéṣẹ́ láti gbà sọ ìhìn rere náà. Ṣàyẹ̀wò ìdí tí irú àwọn ọ̀nà ìyọsíni kan fi gbéṣẹ́. Ṣàyẹ̀wò àwọn àbá tí aṣáájú ọ̀nà tí ó jẹ́ akéde náà bá fún ọ nípa bí o ṣe lè mú kí àwọn ọ̀nà tí o ń gbà gbé ọ̀rọ̀ kalẹ̀ sunwọ̀n sí i. Bí o ṣe ń fi àwọn nǹkan tí o ń kọ́ sí ìlò, ìtẹ̀síwájú rẹ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ yóò fara hàn gbangba, sí ìwọ alára àti sí àwọn ẹlòmíràn. (Wo 1 Tímótì 4:15.) Ẹ máa ṣiṣẹ́ pa pọ̀ fún ọ̀pọ̀ ìgbà bí ó bá ti ṣeé ṣe tó, ẹ máa nípìn-ín nínú gbogbo apá iṣẹ́ òjíṣẹ́, títí kan ìjẹ́rìí àìjẹ́bí àṣà ṣùgbọ́n kí ẹ fún apá ibi tí o ti nílò ìrànwọ́ gan-an ní àfiyèsí.
9 Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ní ọkàn-ìfẹ́ nínú ìtẹ̀síwájú tí ìwọ yóò ní. Láti ìgbà dé ìgbà, òun yóò máa wádìí lọ́dọ̀ olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ láti mọ bí o ṣe ń jàǹfààní láti inú ìṣètò náà. Bákan náà, alábòójútó àyíká yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ nígbà tí ó bá bẹ ìjọ yín wò.
10 Jèhófà ń fẹ́ kí a dá àwọn ènìyàn òun lẹ́kọ̀ọ́ kí a sì ‘mú wọn gbára dì fún iṣẹ́ rere gbogbo.’ (2 Tím. 3:17) Wo ìṣètò Àwọn Aṣáájú Ọ̀nà Ń Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ bí ìpèsè tí ó dára púpọ̀ láti ṣèrànwọ́ fún àwọn tí ń fẹ́ láti mú kí agbára wọn láti wàásù ọ̀rọ̀ náà sunwọ̀n sí i. Bí o bá ní àǹfààní láti nípìn-ín nínú rẹ̀, fi ìmoore, ìrẹ̀lẹ̀, àti ìdùnnú ṣe bẹ́ẹ̀.