‘Pípèsè fún Agbo Ilé Ẹni’—Kíkojú Ìpènijà Náà ní Àwọn Ilẹ̀ Tí Ń Gòkè Àgbà
“DÁJÚDÁJÚ bí ẹnì kan kò bá pèsè fún àwọn wọnnì tí wọ̀n jẹ́ tirẹ̀, àti ní pàtàkì fún àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ mẹ́ḿbà agbo ilé rẹ̀, òun ti sẹ́ níní ìgbàgbọ́ ó sì burú ju ẹni tí kò ní ìgbàgbọ́.” Ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nìyẹn. (Tímótì Kìíní 5:8) Níwọ̀n bí gbígbọ́ bùkátà ìdílé tí túbọ̀ ń ṣòro sí i ní àwọn orílẹ̀-èdè tí nǹkan rọ̀ ṣọ̀mù fún, ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ní ilẹ̀ tí ń gòkè àgbà sábà máa ń gbé ìpènijà pípáni láyà gidigidi dìde.
Fún àpẹẹrẹ, ní Áfíríkà, ìnira ọrọ̀ ajé sábà máa ń jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ ìgbà gbogbo, kì í ṣe ohun àjèjì. Iṣẹ́ wọ́n, ìgbà tí a bá sì rí wọn, ọkọ àti aya lè ní láti ṣiṣẹ́ láti baà lè pèsè kìkì ohun agbẹ́mìíró lásán. Àwọn olórí ìdílé lè ní láti rìnrìn àjò lọ sí ọ̀nà jínjìn réré láti wá iṣẹ́, ní fífi àwọn alábàáṣègbéyàwó wọn àti àwọn ọmọ nìkan sílẹ̀ fún ọ̀pọ̀ oṣù—tàbí ọdún. Ó tún lè ṣòro láti rí ibùgbé tí ó tó pẹ̀lú. Ọ̀pọ̀ ìdílé àwọn ará Áfíríkà tóbi; ibùgbé ń tipa bẹ́ẹ̀ há gádígádí, tí kì í sì í ní àwọn ohun kò-ṣeé-má-nìí. Àwọn ipò tí ń ṣàkóbá fún ìlera sábà máa ń wà.
Ní àfikún sí i, àwọn àṣà ìbílẹ̀, àṣà àbáláyé ọlọ́jọ́ pípẹ́, àti ojú ìwòye gbígbajúmọ̀ lè ta ko ìlànà Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Bíbélì. Gbé àwọn ìṣarasíhùwà kan nípa ìgbéyàwó àti ọmọ yẹ̀ wò. Àwọn olórí ìdílé kan gbà gbọ́ pé, kìkì sísan owó ilé àti owó ilé ẹ̀kọ́ pípọn dandan nìkan ni ojúṣe wọn. Àwọn aya wọn—àti nígbà míràn àwọn ọmọ tí ó dàgbà díẹ̀—ni wọ́n máa ń fi iṣẹ́ pípèsè àwọn ohun kò-ṣeé-má-nìí bí oúnjẹ àti aṣọ sílẹ̀ fún.
Síwájú sí i, àwọn ọkọ kan ní ojú ìwòye náà pé, “èmi ni mo ní owó mi, ṣùgbọ́n owó tìrẹ ara owó tèmi ni.” Èyí sábà máa ń ru kùnrùngbùn sókè nínú àwọn aya tí ń ṣiṣẹ́. Obìnrin kan, ará Tanzania, ṣàròyé pé: “Ọtí ni ó ń fi owó náà mu, kì í ná an sórí wa tàbí sórí àwọn ọmọ. A jọ ń pín iṣẹ́ ṣe ni, tàbí kí n ṣe èyí tí ó pọ̀ jù lọ níbẹ̀, ṣùgbọ́n òun ni yóò gba gbogbo owó náà ní sísọ fún wa pé tòun ni—pé òun ni òun làágùn fún un.”
Ṣùgbọ́n, àwọn Kristẹni fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣáájú àṣà ìbílẹ̀ tàbí èrò gbígbajúmọ̀. Bíbélì fúnni ní ìtọ́sọ́nà ríranni lọ́wọ́ lórí ọ̀ràn bíbójú tó ìdílé ẹni. Fún àpẹẹrẹ, ó sọ pé “kò yẹ fún àwọn ọmọ láti to nǹkan jọ pamọ́ fún àwọn òbí wọn, bí kò ṣe àwọn òbí fún àwọn ọmọ wọn.” (Kọ́ríńtì Kejì 12:14) Nítorí náà, àwọn ọkùnrin olùbẹ̀rù Ọlọ́run tí wọ́n lè ṣiṣẹ́ kì í tìtorí ìwà ọ̀lẹ yọ́ pípèsè oúnjẹ àti aṣọ fún ìdílé sílẹ̀ fún àwọn aya wọn tàbí àwọn ọmọ wọn tí wọ́n ti dàgbà díẹ̀; ojúṣe yẹn já lé olórí ìdílé léjìká.—Kọ́ríńtì Kìíní 11:3.
Lóòótọ́, owó tí ń wọlé fún ọkọ kan lè máà tó láti gbọ́ bùkátà ìdílé. Ṣùgbọ́n bí owó bá ń wọlé fún aya rẹ̀ láti ìta, Kristẹni ọkùnrin kan kì yóò bínú. Kàkà bẹ́ẹ̀, yóò bá a lò gẹ́gẹ́ bí “alábàáṣègbéyàwó” tí a bọ̀wọ̀ fún. (Málákì 2:14, NW) Nípa báyìí, òun kì yóò fi ìwà àìgbatẹnirò gba owó tí aya náà làágùn rí, kí ó sì bààná rẹ̀ láìbìkítà rárá fún ìmọ̀lára rẹ̀. Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, òun àti aya rẹ̀ yóò ‘fi ikún lukùn’ wọn yóò sì pinnu bí wọ́n ṣe lè lo owó wọn lọ́nà tí yóò ṣàǹfààní jù lọ fún gbogbo ìdílé náà. (Òwe 13:10, NW) Níbi tí ó bá ti ṣeé ṣe, ọkọ kan tilẹ̀ lè yọ̀ọ̀da fún aya rẹ̀ láti máa fi òwò díẹ̀ pawọ́ dà, gẹ́gẹ́ bí ti “obìnrin oní ìwà rere” ní àkókò tí a kọ Bíbélì. (Òwe 31:10, 11, 16) Títẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì nínú irú àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀ ń gbé ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn ìdílé lárugẹ.
Kíkojú Ìpènijà Àìríṣẹ́ṣe
Ronú nípa ìṣòro àìríṣẹ́ṣe. Nígbà tí iṣẹ́ kò bá tó nǹkan, tí owó sì kéré, ọ̀pọ̀ àwọn olórí ìdílé ará Áfíríkà ti wá iṣẹ́ lọ sí ọ̀nà jínjìn réré sí ilé wọn—níbi ìwakùsà, ní àwọn ilé iṣẹ́, nínú oko, àti níbi oko ọ̀gbìn ńlá. Bí Kristẹni ọkùnrin kan bá wà nínú ipò yìí, ó lè rí i pé òun jìnnà sí àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ òun, ó sì lè máa kẹ́gbẹ́ búburú. (Òwe 18:1; Kọ́ríńtì Kìíní 15:33) Bí ìdílé rẹ̀ tilẹ̀ ń sakun láti kojú ipò náà lọ́nà tí kò nira púpọ̀, ó ṣeé ṣe kí wọ́n jìyà nítorí pé, bàbá wọn kò sí nílé láti mú ipò iwájú nípa tẹ̀mí tàbí láti ṣèrànlọ́wọ́ ní ti èrò ìmọ̀lára. Lọ́nà tí a kò retí, àìsínílé fún ìgbà pípẹ́ lè yọrí sí ohun náà gan-an tí a retí pé kí ó dènà—ìṣòro ìṣúnná owó.
Ìyálọ́mọ kan sọ pé: “Ọkọ mi lọ wa wúrà. Ó wéwèé láti padà lẹ́yìn oṣù kan tàbí ó pẹ́ tán lẹ́yìn oṣù méjì. Ọdún kan kọjá kí ó tó dé! Ó fi èmi nìkan sílẹ̀ láti tọ́jú ọmọ mẹ́fà. Owó ilé wà nílẹ̀ láti san. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ara mi kò dá, mo ní láti san owó ilé ìwòsàn. A nílò aṣọ, a óò sì jẹun lójoojúmọ́. N kò níṣẹ́ lọ́wọ́. Nǹkan kò rọrùn. Apá tí ó ṣòro jùlọ ni bíbójú tó àwọn ọmọ nípa tẹ̀mí—ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé, ìpàdé, àti iṣẹ́ ìwàásù. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, lọ́nà kan ṣá, a yè é.”
Àní àwọn ìyálọ́mọ kan pàápàá ti rò pé ó pọn dandan fún wọn láti fi àwọn ìdílé wọn sílẹ̀ sẹ́yìn fún ọ̀pọ̀ oṣù láti baà lè ṣiṣẹ́. Àwọn kan jẹ́ alájàpá, wọn kì í sì í gbélé. Ó di dandan fún àwọn ọmọ tí wọ́n dàgbà díẹ̀ láti tẹ́rí gba ojúṣe òbí àti láti bójú tó àtijẹ, iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ inú ilé, àti bíbá àwọn àbúrò wọn kéékèèké wí pẹ̀lú. Lílọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí kò lọ déédéé. Bẹ́ẹ̀ ni, másùn máwo tí èyí ń fún ìdílé bù yààrì!
Àmọ́ ṣáá o, nígbà tí ipò ìṣúnná owó kò bá fara rọ, ó lè máà sí ọ̀nà míràn fún òbí kan láti pèsè fún ìdílé rẹ̀ ju kí ó wá iṣẹ́ lọ sí ọ̀nà jínjìn réré. Ní àkókò tí a kọ Bíbélì, dájúdájú, àwọn ọmọkùnrin Jékọ́bù ní láti fi ìdílé wọn sílẹ̀ láti baà lè rí oúnjẹ ní Íjíbítì. (Jẹ́nẹ́sísì 42:1-5) Nítorí náà, nígbà tí irú ipò jíjọra bẹ́ẹ̀ bá dìde lónìí, àwọn olórí ìdílé gbọ́dọ̀ ronú jinlẹ̀ lórí àǹfààní ti ara yòó wù tí iṣẹ́ ọ̀nà jínjìn réré náà lè mú wà àti ìpalára ti pípínyà fún ìgbà pípẹ́ yóò mú wá nípa tẹ̀mí àti ti èrò ìmọ̀lára. Ọ̀pọ̀ ìdílé yàn láti fara da ìnira ọrọ̀ ajé ju láti pínyà fún sáà pípẹ́. Wọ́n fi àwọn ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù tí a rí nínú Tímótì Kìíní 6:8 sọ́kàn pé: “Bí a bá ti ní ohun ìgbẹ́mìíró àti ìbora, àwa yóò ní ìtẹ́lọ́rùn ọkàn pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí.”—Fi wé Òwe 15:17.
Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ohun mìíràn wà tí a lè ṣe dípò rínrìnrìn àjò. Nípa lílo àtinúdá àti ọgbọ́n inú, ó ti ṣeé ṣe fún àwọn kan láti dá iṣẹ́ sílẹ̀ nípa pípèsè ohun tí àwọn ènìyàn nílò.a (Fi wé Òwe 31:24.) Tàbí kí ó jẹ́ ọ̀ràn títẹ́wọ́ gba àwọn iṣẹ́ rírẹlẹ̀ tí àwọn mìíràn fojú yẹpẹrẹ wò. (Éfésù 4:28) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fúnra rẹ̀ ‘ṣòpò àti làálàá ní òru àti ní ọ̀sán’ láti baà lè yẹra fún dídi ẹrù ìnáwó tirẹ̀ ru ẹlòmíràn. (Tẹsalóníkà Kejì 3:8) Àwọn ọkùnrin Kristẹni lónìí lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ yẹn.
Àwọn Ìṣòro Lílọ Sí Ilé Ẹ̀kọ́
Ìṣòro mìíràn wé mọ́ lílọ sí ilé ẹ̀kọ́. Ní àwọn agbègbè àdádó kan, ó wọ́ pọ̀ kí àwọn òbí máa rán àwọn ọmọ wọn lọ sí ọ̀nà jínjìn láti gbé pẹ̀lú àwọn mọ̀lẹ́bí fún sáà gígùn, kí àwọn ọmọ náà baà lè lọ sí ilé ẹ̀kọ́ tí ó pójú owó. Níwọ̀n bí wọn kò ti sí lọ́dọ̀ àwọn òbí wọn, irú àwọn ọmọ bẹ́ẹ̀ máa ń ní ìṣòro lílọ sí ìpàdé tàbí lílọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá. Nítorí a fi ìbáwí tí wọ́n nílò dù wọ́n, wọ́n tètè máa ń ṣubú sínú pàkúté ẹgbẹ́ búburú. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí èyí, ọ̀pọ̀ ti fi ọ̀nà ìgbésí ayé Kristẹni sílẹ̀.
Kò sí àní-àní pé ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ayé ní àwọn àǹfààní tirẹ̀. Ṣùgbọ́n, Bíbélì gbé ìníyelórí gíga ka ìmọ̀ ẹ̀kọ́ nípa tẹ̀mí, Ọlọ́run sì ti fún àwọn òbí ní ẹrù iṣẹ́ láti pèsè irú ìtọ́ni bẹ́ẹ̀. (Diutarónómì 11:18, 19; Òwe 3:13, 14) Bí ó ti wù kí ó rí, rírán ọmọ kan lọ sí ọ̀nà jínjìn fún sáà kan ṣeé ṣe kí ó jin ìsapá àwọn òbí láti tọ́ ọ dàgbà “nínú ìbáwí àti ìlà èrò orí Jèhófà” lẹ́sẹ̀.—Éfésù 6:4.b
Nígbà tí àǹfààní ti ó wà ládùúgbò fún ìmọ̀ ẹ̀kọ́ bá dà bí èyí tí kò tó, àwọn òbí lè máà ní ohun mìíràn tí wọ́n lè ṣe ju kí àwọn fúnra wọn kọ́ àwọn ọmọ wọn ní àwọn òye iṣẹ́ ṣíṣe pàtàkì. Jèhófà, “Atóbilọ́lá Olùfúnni Nítọ̀ọ́ni” wa pẹ̀lú ń pèsè ìrànlọ́wọ́. (Aísáyà 30:20, NW) Àwọn ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ó wà ládùúgbò ń pèsè ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìmọ̀ ẹ̀kọ́. Ọ̀pọ̀ ìjọ ń darí kíláàsì mọ̀ ọ́n kọ mọ̀ ọ́n kà. Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run bákan náà jẹ́ ìpèsè ìrànwọ́ tí ó lè mú kí agbára ìkàwé àti ìsọ̀rọ̀ ọmọ kan lọ́nà jíjá gaara túbọ̀ dán mọ́rán.
Ojú Ìwòye Wíwà Déédéé Nípa Ọmọ Bíbí
Pípèsè fún àwọn ọmọ lè nira ní pàtàkì bí wọ́n bá pọ̀. Àwọn òbí tí wọ́n jẹ́ ará Áfíríkà sábà máa ń sọ pé àwọn nífẹ̀ẹ́ ọmọ; nítorí náà, wọ́n máa ń bí iye ọmọ tí wọ́n bá lè bí! Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè ka ọmọ sí ọ̀nà ìmówówọlé, ọ̀pọ̀ òbí kò lè pèsè lọ́nà títẹ́rùn fún ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ wọn.
Dájúdájú, Bíbélì sọ pé “àwọn ọmọ ní ìní Olúwa.” (Orin Dáfídì 127:3) Ṣùgbọ́n, ṣàkíyèsí pé, a kọ àwọn ọ̀rọ̀ yẹn nígbà tí ipò nǹkan rọrùn ní Ísírẹ́lì. Lẹ́yìn ìgbà náà, ìyàn mímú hánhán àti ogun mú kí ọmọ bíbí di àdánwò. (Ẹkún Jeremáyà 2:11, 20; 4:10) Lójú ìwòye ipò ìṣòro tí ń gbilẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ tí ń gòkè àgbà, àwọn Kristẹni tí ó ṣeé fẹrù iṣẹ́ lé lọ́wọ́ yẹ kí wọ́n ronú jinlẹ̀ nípa iye ọmọ tí wọ́n lè bọ́, ra aṣọ fún, pèsè ilé fún, àti iye tí wọ́n lè tọ́ ní ti gidi. Lẹ́yìn tí wọ́n ti ṣírò ohun tí yóò ná wọn, ọ̀pọ̀ tọkọtaya pinnu pé, yóò dára jù láti má ṣe tẹ̀ lé àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ti níní ìdílé ńlá, wọ́n sì fi òté lé iye ọmọ tí wọn yóò bí.c—Fi wé Lúùkù 14:28.
Ó ṣe kedere pé, àwọn wọ̀nyí ni “àwọn àkókò líle koko tí ó nira láti bálò.” (Tímótì Kejì 3:1-5) Bí ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ìsinsìnyí tí ń já ṣòòròṣò lọ sí òpin rẹ̀ tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀, kó si iyè méjì pé, pákáǹleke lórí ìdílé ní àwọn ilẹ̀ tí ń gòkè àgbà yóò máa peléke sí i ni. Síbẹ̀, nípa rírọ̀ tímọ́tímọ́ mọ́ àwọn ìlànà Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àwọn olórí ìdílé lè ṣàṣeyọrí nínú bíbójú tó àìní ìdílé wọn nípa ti ara àti nípa tẹ̀mí, nítorí Jèhófà ṣèlérí yìí fún àwọn wọnnì tí wọ́n bá fi ìdúróṣinṣin ṣiṣẹ́ sìn ín pé: “Dájúdájú èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tàbí ṣá ọ tì lọ́nàkọnà.” (Hébérù 13:5) Bẹ́ẹ̀ ni, àní ní àwọn ilẹ̀ òtòṣì pàápàá, àwọn Kristẹni lè ṣàṣeyọrí nínú kíkojú ìpènijà pípèsè fún agbo ilé wọn!
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà, “Dídá Iṣẹ́ Sílẹ̀ ní Àwọn Orílẹ̀-Èdè tí Wọ́n Ṣẹ̀ṣẹ̀ Ń Gòkè Àgbà” nínú ìtẹ̀jáde ìwé ìròyìn ẹlẹgbẹ́ èyí, Jí!, October 22, 1994.
b Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé síwájú sí i, wo “Ibeere Lati Ọwọ Awọn Onkawe” nínú Ile-Iṣọ Naa, February 15, 1983.
c A pèsè ìsọfúnni tí ń ranni lọ́wọ́ nínú ọ̀wọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà, “Ìfètòsọ́mọbíbí—Àríyànjiyàn Àgbáyé,” tí ó fara hàn nínú Jí!, February 22, 1993.