Àwọn Ìdílé Ńlá Tó Ṣọ̀kan Nínú Iṣẹ́ Ìsìn Ọlọ́run
Onísáàmù Náà Kọ̀wé Pé: “Àwọn Ọmọ Jẹ́ Ogún Láti Ọ̀dọ̀ Jèhófà; Èso Ikùn Jẹ́ Èrè. Bí Àwọn Ọfà Ní Ọwọ́ Alágbára Ńlá, Bẹ́ẹ̀ Ni Àwọn Ọmọ Ìgbà Èwe Rí. Aláyọ̀ Ni Abarapá Ọkùnrin Tí Ó Fi Wọ́n Kún Apó Rẹ̀.”—Sáàmù 127:3-5.
BẸ́Ẹ̀ ni, àwọn ọmọ lè jẹ́ ìbùkún látọ̀dọ̀ Jèhófà. Gẹ́gẹ́ bí inú tafàtafà ti máa ń dùn láti mọ ibi tó yẹ kí òun darí ọfà tó wà nínú apó òun sí, bẹ́ẹ̀ náà ni inú àwọn òbí máa ń dùn nígbà tí wọ́n bá darí ọmọ wọn sọ́nà tí ń sinni lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun.—Mátíù 7:14.
Láyé ijọ́un, àwọn ìdílé tí ọmọ púpọ̀ “kún apó” wọn, pọ̀ láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run. Fún àpẹẹrẹ, ronú nípa àwọn ọdún tí wọ́n fi wà ní ìgbèkùn ní Íjíbítì, tí a ròyìn pé: “Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì so èso, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbá yìn-ìn; wọ́n sì ń di púpọ̀ sí i, wọ́n sì ń di alágbára ńlá sí i ní ìwọ̀n àrà ọ̀tọ̀ gan-an, tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi kún ilẹ̀ náà.” (Ẹ́kísódù 1:7) Báa bá ṣe ìfiwéra iye àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wọ Íjíbítì àti iye tó jáde kúrò ní Íjíbítì, a óò rí i pé àwọn ìdílé tó ní tó ọmọ mẹ́wàá wọ́pọ̀!
Lẹ́yìn ìgbà yẹn, Jésù dàgbà nínú ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn yóò pè ní ìdílé ńlá lónìí. Jésù ni àkọ́bí, ṣùgbọ́n Jósẹ́fù àti Màríà tún ní ọmọkùnrin mẹ́rin mìíràn àti àwọn ọmọbìnrin. (Mátíù 13:54-56) Ní ti pé wọ́n lọ́mọ tó pọ̀ tó yẹn ló jọ pé ó fà á tí Màríà àti Jósẹ́fù fi ń padà bọ̀ nílé láti Jerúsálẹ́mù láìmọ̀ pé Jésù kò sí pẹ̀lú àwọn.—Lúùkù 2:42-46.
Àwọn Ìdílé Ńlá Lónìí
Lónìí, ọ̀pọ̀ Kristẹni ló ti pinnu pé àwọn kò fẹ́ ìdílé ọlọ́mọ yọyọ, nítorí ipò tẹ̀mí, ti ìṣúnná owó, ti ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, àti àwọn ìdí mìíràn. Síbẹ̀, àwọn ìdílé ńlá ṣì wọ́pọ̀ nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwùjọ. Gẹ́gẹ́ bí ìwé náà, The State of the World’s Children 1997, ti wí, àgbègbè tí àwọn èèyàn ti ń bímọ jù lọ ni àgbègbè gúúsù aṣálẹ̀ Sàhárà ní Áfíríkà. Níbẹ̀, ìpíndọ́gba ọmọ mẹ́fà lobìnrin kọ̀ọ̀kan ń bí.
Fún Kristẹni òbí tó ní ìdílé ńlá, títọ́ ọmọ wọn láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà kò rọrùn, ṣùgbọ́n àwọn kan ń ṣe é yọrí. Àṣeyọrí sinmi lé ṣíṣọ̀kan tí ìdílé bá ṣọ̀kan nínú ìjọsìn mímọ́. Ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sí ìjọ tó wà ní Kọ́ríńtì bá àwọn ìdílé Kristẹni tòní wí pẹ̀lú. Ó kọ̀wé pé: “Wàyí o, mo gbà yín níyànjú, ẹ̀yin ará, . . . pé kí gbogbo yín máa sọ̀rọ̀ ní ìfohùnṣọ̀kan, àti pé kí ìpínyà má ṣe sí láàárín yín, ṣùgbọ́n kí a lè so yín pọ̀ ṣọ̀kan rẹ́gírẹ́gí nínú èrò inú kan náà àti nínú ìlà ìrònú kan náà.” (1 Kọ́ríńtì 1:10) Báwo la ṣe lè ní irú ìṣọ̀kan bẹ́ẹ̀?
Àwọn Òbí Ní Láti Jẹ́ Ẹni Tẹ̀mí
Kókó pàtàkì kan ni pé àwọn òbí gbọ́dọ̀ máa fi gbogbo ọkàn wọn sin Ọlọ́run. Gbé ohun tí Mósè sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yẹ̀ wò: “Fetí sílẹ̀, ìwọ Ísírẹ́lì: Jèhófà Ọlọ́run wa, Jèhófà kan ṣoṣo ni. Kí ìwọ sì fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo okunra rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ. Kí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí mo ń pa láṣẹ fún ọ lónìí sì wà ní ọkàn-àyà rẹ; kí ìwọ sì fi ìtẹnumọ́ gbìn wọ́n sínú ọmọ rẹ, kí o sì máa sọ̀rọ̀ nípa wọn nígbà tí o bá jókòó nínú ilé rẹ àti nígbà tí o bá ń rìn ní ojú ọ̀nà àti nígbà tí o bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí o bá dìde.”—Diutarónómì 6:4-7.
Ṣàkíyèsí pé Mósè ṣàlàyé pé àwọn àṣẹ Ọlọ́run ní láti “wà ní ọkàn-àyà” àwọn òbí. Ìgbà yẹn ni wọ́n tó lè lẹ́mìí àtimáa gbin ìtọ́ni tẹ̀mí déédéé sí àwọn ọmọ wọn lọ́kàn. Ní ti tòótọ́, tí àwọn òbí bá dúró sán-ún nípa tẹ̀mí, wọn yóò máa hára gàgà láti fi nǹkan tẹ̀mí kọ́ àwọn ọmọ wọn.
Láti di ẹni tẹ̀mí àti láti fi gbogbo ọkàn-àyà ẹni nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó ṣe pàtàkì láti máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé, kí a máa ṣàṣàrò lé e lórí, kí a sì máa mú un lò. Onísáàmù kọ̀wé pé ẹni tó bá ní inú dídùn sí òfin Jèhófà, tó sì ń kà á “tọ̀sán-tòru” yóò “dà bí igi tí a gbìn sẹ́bàá àwọn ìṣàn omi, tí ń pèsè èso tirẹ̀ ní àsìkò rẹ̀ èyí tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ eléwé kì í sì í rọ, gbogbo nǹkan tí ó bá ń ṣe ni yóò sì máa kẹ́sẹ járí.”—Sáàmù 1:2, 3.
Gẹ́gẹ́ bí igi kan ti ń so èso rere báa bá ń bomi rin ín déédéé, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ìdílé táa ń fi oúnjẹ tẹ̀mí tó dọ́ṣọ̀ bọ́ ṣe máa ń so èso lọ́nà ti Ọlọ́run, sí ìyìn Jèhófà. Àpẹẹrẹ kan ni ìdílé Uwadiegwu, tí ń gbé ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ mẹ́jọ ni Uwadiegwu àti ìyàwó rẹ̀ ní, àwọn méjèèjì ń sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà, tàbí lédè mìíràn, àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Arákùnrin náà sọ pé: “Ó ti lé ní ogún ọdún báyìí tí ìdílé wa ti ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé déédéé. Láti ìgbà tí wọ́n jẹ́ ọmọdé jòjòló la ti ń kọ́ àwọn ọmọ wa ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kì í ṣe nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé nìkan, ṣùgbọ́n nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà àti ní àwọn ìgbà mìíràn pẹ̀lú. Olùpòkìkí ìhìn rere Ìjọba náà ni gbogbo àwọn ọmọ wa, kìkì àbígbẹ̀yìn, tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́fà, ni kò tíì ṣèrìbọmi.”
Ṣíṣiṣẹ́ Gẹ́gẹ́ Bí Ẹgbẹ́ Alájọṣe
Bíbélì sọ pé: “Ọgbọ́n ni a ó fi gbé agbo ilé ró.” (Òwe 24:3) Nínú ìdílé, irú ọgbọ́n bẹ́ẹ̀ ń sọ wọ́n di ẹgbẹ́ alájọṣe. Baba ni “olùdarí” ẹgbẹ́ alájọṣe ti ìdílé; òun ni olórí tí Ọlọ́run yàn fún agboolé. (1 Kọ́ríńtì 11:3) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tí a mí sí, tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì ẹrù iṣẹ́ tí ipò orí wé mọ́, nígbà tó kọ̀wé pé: “Bí ẹnì kan kò bá pèsè [nípa tara àti nípa tẹ̀mí] fún àwọn tí í ṣe tirẹ̀, àti ní pàtàkì fún àwọn tí í ṣe mẹ́ńbà agbo ilé rẹ̀, ó ti sẹ́ ìgbàgbọ́, ó sì burú ju ẹni tí kò ní ìgbàgbọ́.”—1 Tímótì 5:8.
Ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ràn yìí láti inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àwọn Kristẹni ọkọ gbọ́dọ̀ máa bójú tó ipò tẹ̀mí aya wọn. Bí iṣẹ́ ilé bá wọ aya lọ́rùn, ṣe ni yóò máa jó àjórẹ̀yìn nípa tẹ̀mí. Ní ilẹ̀ kan ní Áfíríkà, Kristẹni kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi rojọ́ fún àwọn alàgbà ìjọ rẹ̀ pé ìyàwó òun kò tiẹ̀ kọbi ara sí àwọn nǹkan tẹ̀mí rárá. Àwọn alàgbà dábàá pé ìrànlọ́wọ́ tó ṣe gúnmọ́ ni ìyàwó rẹ̀ nílò. Nítorí náà, ọkọ náà bẹ̀rẹ̀ sí ràn án lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ilé. Ó tún ṣètò àkókò láti fi ràn án lọ́wọ́ kí ìwé kíkà rẹ̀ lè túbọ̀ já gaara, kí ìmọ̀ rẹ̀ nínú Bíbélì sì túbọ̀ gún régé. Obìnrin náà wá bẹ̀rẹ̀ sí fọwọ́ dan-in dan-in mú nǹkan tẹ̀mí, gbogbo ìdílé náà sì ti ṣọ̀kan báyìí nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run.
Ó tún yẹ kí àwọn baba bìkítà nípa ipò tẹ̀mí àwọn ọmọ wọn. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin, baba, ẹ má ṣe máa sún àwọn ọmọ yín bínú, ṣùgbọ́n ẹ máa bá a lọ ní títọ́ wọn dàgbà nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfésù 6:4) Nígbà tí àwọn òbí bá fetí sí ìṣílétí náà pé kí wọ́n má ṣe máa sún àwọn ọmọ wọn bínú, tí wọ́n sì tẹ̀ lé ìtọ́ni náà pé kí wọ́n máa tọ́ wọn, àwọn ọmọ yóò ka ara wọn mọ́ ẹgbẹ́ alájọṣe ti ìdílé. Ohun tí yóò yọrí sí ni pé, àwọn ọmọ kò ní ṣàìmáa ran ara wọn lọ́wọ́ lẹ́nì kìíní kejì, wọ́n á sì máa fún ara wọn níṣìírí láti lé àwọn góńgó tẹ̀mí bá.
Ṣíṣiṣẹ́ bí ẹgbẹ́ alájọṣe wé mọ́ fífún àwọn ọmọ ní ẹrù iṣẹ́ tẹ̀mí tí apá wọn bá ká. Baba kan, tí í ṣe Kristẹni alàgbà, tó ní ọmọ mọ́kànlá, máa ń jí lárààárọ̀, ó sì máa ń bá púpọ̀ nínú àwọn ọmọ ṣèkẹ́kọ̀ọ́ kó tó di pé ó gbéra lọ síbi iṣẹ́. Lẹ́yìn tí àwọn tó ti dàgbà ṣèrìbọmi, wọ́n wá ń ran àwọn àbúrò wọn lọ́wọ́ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé, èyí tó ní nínú, nínípìn-ín nínú kíkọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Baba ń bójú tó o, ó sì ń gbóríyìn fún wọn nítorí akitiyan wọn. Mẹ́fà nínú àwọn ọmọ náà ti ṣèrìbọmi, àwọn yòókù sì ń lépa góńgó yẹn.
Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ Tó Múná Dóko àti Góńgó Àjùmọ̀ní
Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ onífẹ̀ẹ́ àti àwọn góńgó tẹ̀mí àjùmọ̀ní ṣe kókó fún àwọn ìdílé tó wà níṣọ̀kan. Gordon, tí í ṣe Kristẹni alàgbà, tí ń gbé ní Nàìjíríà, jẹ́ baba ọmọ méje tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mọ́kànlá sí ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n. Mẹ́fà nínú wọn jẹ́ aṣáájú ọ̀nà, bí òbí wọn. Àbígbẹ̀yìn, tó ṣèrìbọmi lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ń nípìn-ín déédéé nínú iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn mẹ́ńbà yòókù nínú ìdílé. Àwọn ọmọkùnrin méjì tó ti dàgbà jẹ́ ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nínú ìjọ.
Gordon tìkára rẹ̀ ló bá olúkúlùkù ọmọ rẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ìyẹn nìkan kọ́, ìdílé náà tún ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ ẹ̀kọ́ Bíbélì tó gbòòrò. Lárààárọ̀, wọ́n á pàdé pọ̀ láti ka ẹsẹ Bíbélì ojoojúmọ́, lẹ́yìn náà, wọ́n á wá múra àwọn ìpàdé ìjọ sílẹ̀.
Ọ̀kan lára góńgó tí a gbé ka iwájú mẹ́ńbà kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé ni láti ka gbogbo àpilẹ̀kọ inú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, wọ́n fi ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì kíkà ojoojúmọ́ kún un. Nípa sísọ̀rọ̀ nípa ohun tí wọ́n kà, àwọn mẹ́ńbà ìdílé ń fún ara wọn níṣìírí láti máa bá ètò náà nìṣó.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ti fìdí múlẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tó fi jẹ́ pé kò sẹ́ni tó ń gbàgbé—gbogbo wọn ló ń fojú sọ́nà fún un. Láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá, àwọn ohun tí wọ́n ń lò nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé náà, àti bí wọ́n ṣe ń ṣe é, àti bó ṣe máa ń gùn tó, ti yí padà bí ọjọ́ orí àti bí àìní àwọn ọmọ ti ń yí padà. Ìdílé náà ti fà mọ́ àwọn mìíràn tí àwọn pẹ̀lú jẹ́ olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run, èyí sì ti ṣàǹfààní fún àwọn ọmọ náà.
Gẹ́gẹ́ bí ìdílé kan, ṣe ni wọ́n máa ń ṣe nǹkan pọ̀, wọ́n sì máa ń wá àyè fún eré ìtura. Lẹ́ẹ̀kan lọ́sẹ̀, wọ́n máa ń gbádùn “alẹ́ eré ìdílé,” ní irú alẹ́ yìí, wọ́n máa ń sọ àwọn àdììtú ọ̀rọ̀, wọ́n máa ń ṣe àwọn àwàdà tó gbámúṣé, wọ́n ń tẹ dùùrù, wọ́n ń sọ ìtàn, wọn sì ń ṣe fàájì lóríṣiríṣi. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, wọ́n lè lọ sí etíkun àti àwọn ibòmíràn tó fani mọ́ra.
Gbígbáralé Jèhófà
Kò sí ìkankan nínú ohun táa mẹ́nu kàn ṣáájú tó dín ìṣòro bíbójútó ìdílé ńlá kù. Kristẹni kan sọ pé: “Ìpèníjà ńláǹlà ló jẹ́ láti jẹ́ baba rere fún ọmọ mẹ́jọ. Ó ń béèrè fún ọ̀pọ̀ oúnjẹ tara àti tẹ̀mí láti gbé wọn ró; mo gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kára kí n lè rí owó tó pọ̀ tó láti fi gbọ́ bùkátà wọn. Àwọn èyí ẹ̀gbọ́n ti di ọ̀dọ́langba, gbogbo wọn ló sì wà níléèwé. Mo mọ̀ pé ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tẹ̀mí ṣe kókó, síbẹ̀ àwọn kan lára àwọn ọmọ mi lóríkunkun, wọ́n sì ń ṣàìgbọràn. Wọ́n ń bà mí lọ́kàn jẹ́, ṣùgbọ́n mo mọ̀ pé èmi náà máa ń ṣe nǹkan tí ń ba Jèhófà lọ́kàn jẹ́ nígbà mìíràn, ó sì máa ń dárí jì mí. Nítorí náà, mo gbọ́dọ̀ máa bá a nìṣó ní fífi sùúrù tọ́ àwọn ọmọ mi sọ́nà títí orí wọn yóò fi pé wálé.
“Mo máa ń gbìyànjú láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà ní ti pé ó ń mú sùúrù fún wa nítorí pé ó fẹ́ kí gbogbo èèyàn ronú pìwà dà. Mo ń bá ìdílé mi ṣèkẹ́kọ̀ọ́, àwọn kan lára àwọn ọmọ mi sì ń sapá kí wọ́n lè ṣèrìbọmi. N kò gbẹ́kẹ̀ lè agbára èmi fúnra mi láti ṣàṣeyọrí; ìwọ̀nba díẹ̀ ni agbára mi lè ṣe yọrí. Mo máa ń gbìyànjú láti sún mọ́ Jèhófà nígbà gbogbo nínú àdúrà, mo sì ń gbìyànjú láti tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ òwe tó sọ pé: ‘Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.’ Jèhófà yóò ràn mí lọ́wọ́ láti ṣe àṣeyọrí nínú títọ́ àwọn ọmọ mi.”—Òwe 3:5, 6.
Má Ṣe Juwọ́ Sílẹ̀ Láé!
Nígbà mìíràn, ó lè jọ pé iṣẹ́ ọmọ títọ́ kò lọ́pẹ́ nínú, ṣùgbọ́n má ṣe juwọ́ sílẹ̀! Sáà máa rọ́jú! Bí àwọn ọmọ rẹ kò bá gbọ́ tìẹ, tàbí tí wọn kò mọrírì akitiyan rẹ nísinsìnyí, wọ́n lè ṣe bẹ́ẹ̀ lẹ́yìnwá ọ̀la. Ó máa ń gba àkókò kí ọmọ tó lè dàgbà di Kristẹni tí ń so èso tẹ̀mí.—Gálátíà 5:22, 23.
Monica, tí ń gbé ní Kẹ́ńyà, jẹ́ ọ̀kan lára ọmọ mẹ́wàá. Ó sọ pé: “Láti ìgbà táa jẹ́ ọmọdé jòjòló ni àwọn òbí wa ti ń kọ́ wa ní òtítọ́ Bíbélì. Ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ni Dádì máa ń bá wa ṣèkẹ́kọ̀ọ́ nínú àwọn ìtẹ̀jáde Kristẹni. Nítorí iṣẹ́ rẹ̀, ìkẹ́kọ̀ọ́ náà kì í sábà wáyé ní ọjọ́ kan náà. Nígbà mí-ìn, bó bá ti ń tibi iṣẹ́ bọ̀ wálé, tó rí wa táa ń ṣeré níta, ni yóò sọ fún wa pé, ní ìṣẹ́jú márùn-ún sí i, kí gbogbo wa ti wọlé wá ká lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa. Lẹ́yìn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa, a máa ń fún wa níṣìírí láti béèrè ìbéèrè tàbí láti jíròrò ìṣòro èyíkéyìí.
“Ó máa ń rí i dájú pé àwọn ọmọ tó bẹ̀rù Ọlọ́run là ń bá rìn. Lóòrèkóòrè ni Dádì máa ń ṣèbẹ̀wò sí iléèwé wa láti wá béèrè lọ́wọ́ àwọn tíṣà nípa ìwà wa. Nígbà kan tó ṣe irú ìbẹ̀wò bẹ́ẹ̀, ó gbọ́ pé àwọn ẹ̀gbọ́n mi mẹ́ta tó jẹ́ ọkùnrin bá àwọn ọmọkùnrin mí-ìn jà, àti pé wọ́n máa ń ṣe ìpátá lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Dádì jẹ wọ́n níyà fún àìmọ̀wàáhù, ṣùgbọ́n ó tún ṣètò àkókò láti fi Ìwé Mímọ́ ṣàlàyé ìdí tí wọ́n fi gbọ́dọ̀ máa hùwà lọ́nà tí Ọlọ́run fẹ́.
“Àwọn òbí wa fi àwọn àǹfààní tó wà nínú pípésẹ̀ sí àwọn ìpàdé hàn wá nípa mímúra àwọn ìpàdé sílẹ̀ pẹ̀lú wa. Wọ́n kọ́ wa láti di òjíṣẹ́ nípa ṣíṣe ìdánrawò nínú ilé. Láti ìgbà ọmọdé jòjòló la ti ń bá àwọn òbí wa lọ sẹ́nu iṣẹ́ ìsìn pápá.
“Lónìí, aṣáájú ọ̀nà àkànṣe làwọn ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin méjì, ọ̀kan lára àwọn àbúrò mi obìnrin jẹ́ aṣáájú ọ̀nà déédéé, ẹ̀gbọ́n mi mìíràn, tó ti wà nílé ọkọ, tó sì ti bímọ, jẹ́ Ẹlẹ́rìí onítara. Àwọn àbúrò mi méjèèjì tí wọ́n jẹ́ obìnrin, tí wọ́n jẹ́ ọmọ ọdún méjìdínlógún àti mẹ́rìndínlógún, jẹ́ akéde tí ó ti ṣèrìbọmi. Àwọn àbúrò mi ọkùnrin méjì ń gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́. Ó ti pé ọdún mẹ́ta báyìí tí mo ti ń sìn ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Kẹ́ńyà. Mo nífẹ̀ẹ́ àwọn òbí mi, mo sì mọrírì wọn nítorí pé ẹni tẹ̀mí ni wọ́n; wọ́n fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún wa.”
Láìka iye ọmọ tóo ní sí, má ṣe juwọ́ sílẹ̀ láé ní ríràn wọ́n lọ́wọ́ lójú ọ̀nà sí ìyè àìnípẹ̀kun. Bí Jèhófà ti ń bù kún ìsapá rẹ, ìwọ yóò sọ àsọtúnsọ ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Jòhánù sọ nípa àwọn ọmọ rẹ̀ tẹ̀mí pé: “Èmi kò ní ìdí kankan tí ó tóbi ju nǹkan wọ̀nyí lọ fún ṣíṣọpẹ́, pé kí n máa gbọ́ pé àwọn ọmọ mi ń bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́.”—3 Jòhánù 4.