Mọ Àwọn Ará Ní Àmọ̀dunjú
1 Bíbélì ṣàpèjúwe ọ̀rẹ́ tòótọ́ pé ó jẹ́ ẹni tí ń fà mọ́ni tímọ́tímọ́ ju arákùnrin lọ, tí ó máa ń nífẹ̀ẹ́ ẹni nígbà gbogbo, tí ó jẹ́ adúróṣinṣin, tí ó sì máa ń ran alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ ní ìgbà wàhálà. (Òwe 17:17; 18:24) A kì yóò fẹ́ irú àwọn ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀ kù nínú ìjọ bí a bá sapá láti mọ ara wa ní àmọ̀dunjú kí a sì nífẹ̀ẹ́ ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.—Jòh. 13:35.
2 Àǹfààní wà fún wa dáadáa kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀ àti lẹ́yìn tí ó bá parí láti di ojúlùmọ̀ àwọn arákùnrin wa. Èé ṣe tí o kò fi tètè dé kí ó sì túbọ̀ dúró pẹ́ díẹ̀ lẹ́yìn ìpàdé kí o lè gbádùn ìbákẹ́gbẹ́ ọlọ́yàyà tí ń tani jí? Tọ àwọn ará lọ ní onírúurú kí o sì bá wọn jíròrò, títí kan àwọn àgbàlagbà onírìírí àti àwọn ọmọdé tàbí àwọn tí ń bẹ̀rù.
3 Bẹ̀rẹ̀ Ìjíròrò: Má ṣe jẹ́ kí ó mọ sórí wíwulẹ̀ kí àwọn ará. O lè bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò nípa ṣíṣàjọpín ìrírí inú iṣẹ́ òjíṣẹ́, kókó kan tí ń gba ọkàn-ìfẹ́ nínú ìwé ìròyìn lọ́ọ́lọ́ọ́, tàbí gbólóhùn kan nípa ìpàdé tí ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe tán. O lè mọ ohun púpọ̀ nípa àwọn ará nípa fífetísílẹ̀ dáadáa, kí o fún wọn níṣìírí pé kí wọ́n sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìrírí wọn àti àwọn nǹkan tí wọ́n ń kọ́. Wíwulẹ̀ béèrè bí ẹnì kan ṣe di ẹni tí ó mọ Jèhófà lè ṣí ọ̀pọ̀ nǹkan payá. Àwọn kan ti ní ìrírí tí ń fún ìgbàgbọ́ lókùn nínú ìgbésí ayé wọn, tí àwọn mìíràn sì ń fara da àwọn ìṣòro kan lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí tí ó lè ṣòro fún ọ̀pọ̀ láti mọ̀. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ tòótọ́, mímọ èyí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti mọ àwọn àìní àwọn ẹlòmíràn kí a sì dáhùn padà sí wọn.
4 Ẹ Bá Ara Yín Dọ́rẹ̀ẹ́ Lẹ́nì Kìíní-Kejì: Lẹ́yìn tí ọmọ arábìnrin kan kú, ó ṣòro fún un láti kọ àwọn orin Ìjọba Ọlọ́run tí ó sọ nípa àjíǹde. Ó sọ pé: “Ní àkókò kan, arábìnrin kan tí ó jókòó dojú kọ mí rí i pé mo ń sọkún. Ó dìde wá, ó fọwọ́ rẹ̀ gbá mi mọ́ra, ó sì kọ ìyókù orin náà pẹ̀lú mi. Ìfẹ́ mi fún àwọn arákùnrin àti arábìnrin kún gidigidi mo sì láyọ̀ pé a lọ sí àwọn ìpàdé, ní mímọ̀ pé ibẹ̀ ni ìrànwọ́ wa wà, ní Gbọ̀ngàn Ìjọba.” Ó yẹ kí a bá àwọn ará dọ́rẹ̀ẹ́ nípa títù wọ́n nínú nígbà tí ó bá yẹ bẹ́ẹ̀ kí a sì máa fún wọn níṣìírí nígbà gbogbo.—Héb. 10:24, 25.
5 Bí ayé ògbólógbòó yìí ṣe túbọ̀ ń nini lára sí i, ẹ jẹ́ kí a pinnu láti mọ àwọn ará ní àmọ̀dunjú sí i. Ṣíṣe pàṣípààrọ̀ ojúlówó ìṣírí lọ́nà yìí yóò yọrí sí ìbùkún fún gbogbo wa.—Róòmù 1:11, 12.