Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn July
Av. Av. Av. Av.
Iye: Hrs. Mags. R.V. Bi.St.
Aṣá. Àkàn. 482 133.8 14.0 61.0 10.4
Aṣá. Déédé 20,467 66.9 6.8 23.8 5.5
Aṣá. Olù. 5,553 55.8 4.2 15.6 3.7
Akéde 185,459 10.5 0.9 3.4 1.0
ÀRÒPỌ̀ 211,961 Àwọn Tí A Batisí: 443
Inú wa dùn láti tún ròyìn góńgó tuntun mìíràn ju ti ìgbàkígbà rí lọ ti 211,961 akéde tí ó ròyìn ní oṣù July. Èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ tí a kọjá góńgó 210,000. Ohun mìíràn tí ó tún fani lọ́kàn mọ́ra ni iye ìwé ẹlẹ́yìn líle tí a fi sóde—57,217 ní àròpọ̀—tí ó fi iye tí ó ju 42,000 lọ ju iye tí a fi sóde ní oṣù July 1997. Síwájú sí i, láti oṣù December 1997 wá, a ti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé tí ó ju 300,000 lọ lóṣooṣù. Èyí fi hàn pé ìbísí síwájú sí i ṣeé ṣe gidigidi. A kún fún ìmoore sí Jèhófà nítorí bí ó ṣe ń bù kún iṣẹ́ wa.