ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 11/98 ojú ìwé 2
  • Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún November

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún November
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní November 2
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní November 9
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní November 16
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní November 23
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní November 30
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
km 11/98 ojú ìwé 2

Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún November

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní November 2

Orin 38

10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Àwọn Ìfilọ̀ tí a yàn láti inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Sọ̀rọ̀ nípa ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá ti oṣù July ti orílẹ̀-èdè yìí àti ti ìjọ àdúgbò.

15 min: “Gbogbo Ènìyàn Gbọ́dọ̀ ‘Gba Ọ̀rọ̀ Náà Tọkàntọkàn’!” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Fi àwọn àbá láti inú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti June 1996, ìpínrọ̀ 21 kún un.

20 min: “Mo Fẹ́ Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Kan!” Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ èyí tí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn darí. Ṣàlàyé bí a óò ṣe ṣètò ìsapá àjùmọ̀ṣe yìí nínú ìjọ láti ṣe ìpadàbẹ̀wò. Dé ìwọ̀n àyè tí ó bá ṣeé ṣe, àwọn akéde tí wọ́n ní ìrírí lè bá àwọn tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ di akéde ṣiṣẹ́. Jẹ́ kí akéde tí ó dáńgájíá ṣàṣefihàn bí a ṣe lè fi ìkẹ́kọ̀ọ́ lọni nígbà ìpadàbẹ̀wò. Fún gbogbo àwọn akéde níṣìírí láti sakun láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ tuntun.

Orin 35 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní November 9

Orin 187

13 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ṣàlàyé àkànṣe ìṣètò fún iṣẹ́ ìsìn pápá ní òpin ọ̀sẹ̀. Àpótí Ìbéèrè.

15 min: Àìní àdúgbò.

17 min: “Ẹ Máa Gbé Ara Yín Ró Lẹ́nì Kìíní-Kejì Nípa Dídáhùn ní Àwọn Ìpàdé.” Ìbéèrè àti Ìdáhùn. Ṣàlàyé bí dídáhùn ní ìpàdé ṣe ń fi kún ìtẹ̀síwájú wa nípa tẹ̀mí. (Wo Iwe-Amọna Ile Ẹkọ, ìkẹ́kọ̀ọ́ 38, ìpínrọ̀ 4.) Ké sí àwọn kan láti sọ bí wọ́n ṣe borí lílọ́ tìkọ̀ láti dáhùn àti bí a ti ṣe bù kún wọn nípasẹ̀ kíkópa nínú àwọn ìpàdé.

Orin 51 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní November 16

Orin 182

8 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn ìnáwó.

20 min: “Àwọn Alábòójútó Tí Ń Mú Ipò Iwájú—Alábòójútó Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run.” Ọ̀rọ̀ àsọyé láti ẹnu alábòójútó ilé ẹ̀kọ́. Ṣàtúnyẹ̀wò Iwe-Amọna Ile Ẹkọ, ojú ìwé 10 àti 11, ìpínrọ̀ 6 sí 12.

17 min: “Gbéṣẹ́ Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ.” Ìjíròrò ìpínrọ̀ 1 sí 7 lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn nínú àkìbọnú. Darí àfiyèsí sí àwọn kókó tí ó wúlò ní pàtàkì fún ìpínlẹ̀ ìjọ.

Orin 167 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní November 23

Orin 89

8 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Sọ ìrírí tí a tẹ̀ jáde ní ojú ewé tí ó kẹ́yìn nínú Jí!, August 8, 1998, nípa ipa tí ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ ti ní lórí àwọn ènìyàn. Kí gbogbo akéde wà lójúfò láti fi ìwé yìí lọni ní àwọn àkókò yíyẹ.

17 min: “Gbéṣẹ́ Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ.” Ìjíròrò ìpínrọ̀ 8 sí 21 lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn nínú àkìbọnú. Darí àfiyèsí sí àwọn kókó tí yóò wúlò ní pàtàkì ní ìpínlẹ̀ ìjọ.

20 min: Àwọn Àbá Láti Mú Bíbélì Kíkà Rẹ Dára Sí I. Ọ̀rọ̀ àsọyé tí a gbé karí Ilé-Ìṣọ́nà, May 1, 1995, ojú ìwé 16 àti 17. Tẹnu mọ́ àwọn àǹfààní tẹ̀mí tí a ń jèrè láti inú kíka Bíbélì lójoojúmọ́. Ṣàtúnyẹ̀wò àwọn àbá tí a fúnni, sì jíròrò bí a ṣe lè fi wọ́n sílò. Jẹ́ kí akéde méjì tàbí mẹ́ta sọ bí wọ́n ṣe ń jàǹfààní nípa kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé.

Orin 46 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní November 30

Orin 64

15 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Rán gbogbo ìjọ létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn sílẹ̀. Fún gbogbo àwọn tí kò bá bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ kan ní oṣù November níṣìírí láti máa bá ìsapá wọn nìṣó ní oṣù December, oṣù tí a ń fi ìwé Ìmọ̀ àti Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lọni. Jẹ́ kí akéde dídáńgájíá ṣàṣefihàn ìpadàbẹ̀wò kan nípa lílo àpótí tí ó wà ní ojú ìwé 19 nínú ìwé Ìmọ̀; akéde náà ṣàlàyé bí a ṣe lè lo ìwé náà láti lóye àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì, ó sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́.

15 min: Lo Kàlẹ́ńdà Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti Ọdún 1999 Lọ́nà Rere. Ọ̀rọ̀ àsọyé. Ṣàyẹ̀wò àwọn apá fífanimọ́ra tí kàlẹ́ńdà náà ní: (1) àwọn àwòrán tí ń fani mọ́ra tí ń ṣàpèjúwe àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àti ẹ̀kọ́ pàtàkì nínú Bíbélì, (2) ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ fún Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run, (3) ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì kíkà ọdọọdún fún àsìkò Ìṣe Ìrántí, (4) ìfitónilétí nípa àwọn àtúnyẹ̀wò alákọsílẹ̀ tí ń bọ̀, àti (5) ìránnilétí láti nípìn-ín déédéé nínú iṣẹ́ ìwé ìròyìn. Jíròrò àwọn ọ̀nà tí a lè gbà lo àwọn àlàfo tí ó wà lórí rẹ̀ láti ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìṣètò iṣẹ́ ìsìn pápá, láti ṣàkọsílẹ̀ ìròyìn iṣẹ́ ìsìn àti àdéhùn láti bá àwọn ẹlòmíràn ṣiṣẹ́, láti ṣàkọsílẹ̀ àwọn iṣẹ́ àyànfúnni ní ìpàdé, láti ṣàkọsílẹ̀ ìránnilétí nípa ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká àti àwọn àpéjọ tí ń bọ̀. Fífi kàlẹ́ńdà náà síbi tí a ti lè tètè rí i ní ilé tàbí ní ibi iṣẹ́ lè ṣí àǹfààní sílẹ̀ fún wa láti bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò láti inú Ìwé Mímọ́. Sọ ìrírí láti inú ìwé Yearbook ti ọdún 1988, ojú ìwé 8.

15 min: Jàǹfààní Ní Kíkún Láti Inú Ìwé Yearbook ti ọdún 1998. Baba ṣàtúnyẹ̀wò ojú ìwé 3 sí 6, àti 31 pẹ̀lú ìdílé rẹ̀, ìyẹn ṣàlàyé nípa àṣeyọrí tí a ti ṣe ní ti ìṣàkóso Ọlọ́run ní ọdún tó kọjá. Ó ṣàyẹ̀wò àwọn àǹfààní tí ìdílé náà ti gbádùn nípa kíka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ojoojúmọ́ àti apá kan láti inú ìwé Yearbook pa pọ̀ ní àkókò oúnjẹ àti jíjíròrò wọn, wọ́n pinnu láti máa bá ṣíṣe bẹ́ẹ̀ nìṣó jálẹ̀ ọdún.

Orin 121 àti àdúrà ìparí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́