Àwọn Ìfilọ̀
◼ Àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni ní December àti January: Ìfilọni àkànṣe ti àdìpọ̀ oríṣi ìwé méjì fún ₦40 àti àdìpọ̀ ìwé mẹ́rin fún ₦80, tí ẹ lè béèrè fún láti ẹ̀ka ilé iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàlàyé nínú lẹ́tà wa ti March 23, 1998. Bákan náà, a lè fi èyíkéyìí nínú àwọn ìwé olójú ewé 192 ní èdè èyíkéyìí tí ìjọ lè ní lọ́wọ́, yàtọ̀ sí Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé, Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-ojiṣẹ Wa àti Iwe-Amọna Ile Ẹkọ Iṣẹ Ojiṣẹ Ijọba Ọlọrun lọni ní àkànṣe ọrẹ ₦20. Ẹ lè béèrè fún ẹ̀dínwó lórí àwọn ìwé wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàlàyé nínú lẹ́tà wa. February: Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé. Ìfilọni àfidípò: Ìwé olójú ewé 192 èyíkéyìí tí ọjọ́ rẹ̀ ti pẹ́ tí a bá ní lọ́wọ́. March: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Ìfilọni àfidípò: Ìwé olójú ewé 192 èyíkéyìí mìíràn, kí a fi lọni ní iye tí a máa ń fi sóde. A óò sapá lákànṣe láti bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé.
◼ Kí alábòójútó olùṣalága tàbí ẹnì kan tí òun yàn ṣàyẹ̀wò àkáǹtì ìjọ ní December 1 tàbí bí ó bá ti lè ṣeé ṣe kí ó yá tó lẹ́yìn náà. Bí ẹ bá ti ṣe èyí, ẹ ṣe ìfilọ̀ fún ìjọ lẹ́yìn tí ẹ bá ti ka ìròyìn ìnáwó tí ó tẹ̀ lé e.
◼ Ní báyìí, a ń tẹ́wọ́ gba ìbéèrè fún kásẹ́ẹ̀tì fídíò tuntun (PAL) ní Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà, tí a pe àkọlé rẹ̀ ní Sing Praises to Jehovah, (Kọrin Ìyìn sí Jèhófà) Apá Kìíní. Kí àwọn ìjọ tí ó bá nílò fídíò yìí béèrè fún un nípa lílo Literature Order Form (S-14). Ṣùgbọ́n, ẹ rántí pé ohun èlò tí a máa ń béèrè lákànṣe ni èyí. Akéde yóò fi ₦800 gbà á, aṣáájú ọ̀nà yóò sì fi ₦640 gbà á.