Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún December
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní December 7
Orin 186
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Àwọn Ìfilọ̀ tí a yàn láti inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa.
15 min: “A Gbọ́dọ̀ Dé Ọ̀dọ̀ Àwọn Ènìyàn Léraléra.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ní ṣókí, sọ̀rọ̀ lórí Ìsíkíẹ́lì 3:17-19, tẹnu mọ́ ẹrù iṣẹ́ wa láti máa bá a nìṣó ní pípolongo ìhìn iṣẹ́ ìkìlọ̀ náà.
20 min: “‘Má Fawọ́ Sẹ́yìn’ Láti Jẹ́ Kí Wọ́n Gbọ́.” Arákùnrin kan jíròrò àpilẹ̀kọ yìí pẹ̀lú akéde dídáńgájíá méjì tàbí mẹ́ta. Ṣàṣefihàn bí a ṣe lè fi ìwé tí a óò fi lọni ní December lọni.
Orin 192 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní December 14
Orin 206
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Dábàá nípa bí a ṣe lè fọgbọ́n dáhùn ìkíni ayẹyẹ ọdún. Bí ìjọ bá ní ìwé Ọkunrin Titobilọla Jùlọ tàbí Olukọ Nla lọ́wọ́, fi hàn bí a ṣe lè lò wọ́n lọ́nà gbígbéṣẹ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ lákòókò ayẹyẹ Kérésìmesì. Ṣàlàyé àkànṣe ìṣètò iṣẹ́ ìsìn pápá fún December 25 àti January 1.
15 min: “Àwọn Alábòójútó Tí Ń Mú Ipò Iwájú—Olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́.” Ọ̀rọ̀ àsọyé láti ẹnu olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́. Ó ṣàlàyé àwọn ẹrù iṣẹ́ rẹ̀ àti bí gbogbo àwọn tí ó bá pésẹ̀ ṣe lè ṣèrànwọ́ láti mú kí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà tani jí, kí ó kún fún ẹ̀kọ́, kí ó sì gbéni ró nípa tẹ̀mí.—Wo ìwé Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-Ojiṣẹ Wa, ojú ìwé 66 àti 67.
20 min: “Wọ́n Rí I Pé A Yàtọ̀.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ní ṣókí, ṣàyẹ̀wò ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ànímọ́ tí ó mú kí a yàtọ̀. Sọ bí a ṣe lè lo ìsọfúnni yìí láti darí àwọn olùfìfẹ́hàn sí ètò Ọlọ́run àti láti fi hàn wọ́n bí òtítọ́ ti ń mú àwọn ànímọ́ Kristẹni jáde nínú àwọn tí ó bá gbé ní ìbámu pẹ̀lú rẹ̀.
Orin 146 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní December 21
Orin 163
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn ìnáwó. Bí ìjọ yín yóò bá yí àkókò ìpàdé padà ní ọdún tuntun, fún gbogbo àwùjọ níṣìírí onínúure láti máa bá a lọ láti pésẹ̀ déédéé pẹ̀lú ìjọ ní àwọn àkókò tuntun náà. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìyípadà èyíkéyìí tó àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọn àti àwọn olùfìfẹ́hàn létí. Fún gbogbo akéde níṣìírí pé kí wọ́n tọ́jú àwọn ẹ̀dà Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa tiwọn, pàápàá àwọn àkìbọnú. Ó ṣeé ṣe pé a óò máa tọ́ka sí wọn ní ọjọ́ iwájú.
10 min: Ṣàyẹ̀wò “Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Tuntun fún Àpéjọ Àyíká.”
25 min: “A Ń Fẹ́ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Púpọ̀ Sí I.” Ọ̀rọ̀ àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn darí. Ṣàyẹ̀wò ìgbòkègbodò ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìjọ. Gbóríyìn fún ìjọ níbi tí ó bá ti ṣe dáadáa. Tọ́ka sí ohun tí a tún lè ṣe láti bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé, kí a sì máa darí wọn. Ṣàpèjúwe ìpínrọ̀ 5 nípa fífi ọ̀rọ̀ wá òbí kan tí ó máa ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé déédéé lẹ́nu wo. Ka ìpínrọ̀ 8, kí o sì tẹnu mọ́ àwọn kókó mẹ́jọ tí a tò lẹ́sẹẹsẹ. Ṣàlàyé ìpínrọ̀ 13 nípa kíké sí akéde kan tí ó dáńgájíá nínú dídarí ìkẹ́kọ̀ọ́ kí ó ṣàlàyé bí ó ti ṣeé ṣe láti kárí àkójọ ọ̀rọ̀ láìsí ìdádúró tí kò pọndandan. Fi ìrírí kan tí ó dára kún un, tí ó fi hàn bí a ṣe ṣe àṣeyọrí ládùúgbò.
Orin 109 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní December 28
Orin 178
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Rán gbogbo akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn fún oṣù December sílẹ̀. Fi àwọn ìwé àdìpọ̀ tí ó wà lọ́wọ́, tí a óò fi lọni ní oṣù January hàn. Fún àwọn akéde níṣìírí pé kí wọ́n gba mélòó kan fún ìpínkiri ní òpin ọ̀sẹ̀ yìí.
20 min: Àìní àdúgbò.
15 min: “Jàǹfààní Láti Inú Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run fún Ọdún 1999.” Ọ̀rọ̀ àsọyé láti ẹnu alábòójútó Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run. Jẹ́ kí àwọn akéde mélòó kan sọ àǹfààní tí wọ́n ti jèrè láti inú títẹ̀lé “Àfikún Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì Kíkà” lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Fún gbogbo àwùjọ níṣìírí láti máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́.
Orin 91 àti àdúrà ìparí.