Wọ́n Rí I Pé A Yàtọ̀
1 Lọ́dún tó kọjá, ó ju ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [300,000] ènìyàn tí ó dara pọ̀ mọ́ wa nípa ṣíṣe batisí. Kí ni àwọn ènìyàn wọ̀nyí rí lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ó mú kí wọ́n fẹ́ láti di apá kan ètò Ọlọ́run? Èé ṣe tí a fi yàtọ̀ sí gbogbo ìsìn yòókù? Àwọn ìdáhùn díẹ̀ tí ó fara hàn gbangba nìyí:
—A ń tẹ̀ lé ohun tí ó wà nínú Bíbélì dípò èrò ara wa: A ń jọ́sìn Jèhófà Ọlọ́run “ní ẹ̀mí àti òtítọ́,” gan-an bí Jésù Kristi ti ṣe. Èyí túmọ̀ sí pé a kọ èké tí ń bẹ nínú ìsìn sílẹ̀, a sì ń tẹ̀ lé àkọsílẹ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.—Jòh. 4:23, 24; 2 Tím. 3:15-17.
—A máa ń tọ àwọn ènìyàn lọ dípò kí a dúró pé kí wọ́n wá bá wa: A tẹ́wọ́ gba àṣẹ tí Kristi pa pé kí a wàásù kí a sì kọ́ni, a sì ń fara wé àpẹẹrẹ rẹ̀ ní ti wíwá àwọn aláìlábòsí-ọkàn rí. A máa ń wá wọn lọ sí ilé wọn, a ń pàdé wọn ní òpópónà, a sì máa ń wá wọn lọ sí ibikíbi tí a bá ti lè rí wọn.—Mát. 9:35; 10:11; 28:19, 20; Ìṣe 10:42.
—A máa ń pèsè ìtọ́ni Bíbélì fún gbogbo ènìyàn lọ́fẹ̀ẹ́: A máa ń lo àwọn ohun àmúṣọrọ̀ àti agbára wa lọ́fẹ̀ẹ́ nípa yíya ohun tí ó ju bílíọ̀nù wákàtí sọ́tọ̀ lọ́dọọdún fún iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Láìṣojúsàájú, a ń bá onírúurú ènìyàn ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.—Mát. 10:8; Ìṣe 10:34, 35; Ìṣí. 22:17.
—A dá wa lẹ́kọ̀ọ́ dáadáa láti ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí: Nípasẹ̀ ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí a ń ṣe àti àwọn ìtọ́ni tí a ń pèsè ní àwọn ìpàdé ìjọ, àpéjọ, àti àpéjọpọ̀, a ń rí ẹ̀kọ́ ìṣàkóso Ọlọ́run tí kò ṣeé díye lé, tí ń bá a nìṣó gbà, èyí sì ń jẹ́ kí a lè la àwọn ẹlòmíràn lóye nípa tẹ̀mí.—Aísá. 54:13; 2 Tím. 2:15; 1 Pét. 3:15.
—A ń fi ọwọ́ pàtàkì mú òtítọ́, a sì ń fi í sílò nínú ìgbésí ayé wa: Nítorí pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, a ń ṣe àwọn ìyípadà, a ń mú kí ìgbésí ayé wa bá ohun tí ó fẹ́ mu. Ànímọ́ tuntun bí ti Kristi tí a ní ń fa àwọn ẹlòmíràn sún mọ́ òtítọ́.—Kól. 3:9, 10; Ják. 1:22, 25; 1 Jòh. 5:3.
—A ń sakun láti máa bá àwọn ènìyàn gbé kí a sì máa ṣiṣẹ́ pẹ̀lú wọn ní àlàáfíà: Mímú tí a ń mú àwọn ànímọ́ Ọlọ́run dàgbà ń ràn wá lọ́wọ́ láti máa ṣọ́ ìwà àti ọ̀rọ̀ wa. A ń “wá àlàáfíà” pẹ̀lú gbogbo ènìyàn, a sì ń “lépa rẹ̀.”—1 Pét. 3:10, 11; Éfé. 4:1-3.
2 Àwọn àpẹẹrẹ ọ̀nà ìgbésí ayé Kristẹni tí àwọn ènìyàn ń rí nínú ètò Jèhófà ń sún ọ̀pọ̀ láti tẹ́wọ́ gba òtítọ́. Ǹjẹ́ kí àpẹẹrẹ wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ní ipa kan náà lórí àwọn tí ó mọ̀ wá tí wọ́n sì ń ṣàkíyèsí wa.