ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 1/99 ojú ìwé 2-3
  • Àwọn Ìfilọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìfilọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
km 1/99 ojú ìwé 2-3

Àwọn Ìfilọ̀

◼ Àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni ní January: Ìfilọni àkànṣe ti àdìpọ̀ oríṣi ìwé méjì fún ₦40 àti àdìpọ̀ ìwé mẹ́rin fún ₦80, tí ẹ lè béèrè fún láti ẹ̀ka ilé iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàlàyé nínú lẹ́tà wa ti March 23, 1998. Bákan náà, a lè fi èyíkéyìí nínú àwọn ìwé olójú ewé 192 ní èdè èyíkéyìí tí ìjọ lè ní lọ́wọ́, yàtọ̀ sí Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé, Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-ojiṣẹ Wa àti Iwe-Amọna Ile Ẹkọ Iṣẹ Ojiṣẹ Ijọba Ọlọrun lọni ní àkànṣe ọrẹ ₦20. Ẹ lè béèrè fún ẹ̀dínwó lórí àwọn ìwé wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàlàyé nínú lẹ́tà wa. February: Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé. Ìfilọni àfidípò: Ìwé olójú ewé 192 èyíkéyìí tí ọjọ́ rẹ̀ ti pẹ́ tí a bá ní lọ́wọ́. March: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Ìfilọni àfidípò: Ìwé olójú ewé 192 èyíkéyìí mìíràn, kí a fi lọni ní iye tí a máa ń fi sóde. A óò sapá lákànṣe láti bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. April: Gbogbo èdè—Àsansílẹ̀ owó fún Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Mú kí ìwé pẹlẹbẹ Béèrè wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún àwọn tí ó fi ọkàn-ìfẹ́ hàn, kí o sì sakun láti bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé.

◼ Gbogbo akéde tí ó ti ṣe batisí tí ó bá wà ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ní ọ̀sẹ̀ January 4 ni a óò fún ní káàdì Advance Medical Directive/Release àti Identity Card (Káàdì Ìdánimọ̀) fún àwọn ọmọ wọn.

◼ Bẹ̀rẹ̀ ní February, tí kò sì ní kọjá March 1, àsọyé fún gbogbo ènìyàn tí àwọn alábòójútó àyíká yóò máa sọ ni “Báwo Ni Ọlọ́run Ṣe Jẹ́ Gidi sí Ọ Tó?”

◼ Kí àwọn ìjọ ṣètò láti ṣayẹyẹ Ìṣe Ìrántí lọ́dún yìí ní Thursday, April 1, lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àsọyé náà lè bẹ̀rẹ̀ ṣáájú àkókò yìí, gbígbé àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ Ìṣe Ìrántí kiri kò gbọ́dọ̀ bẹ̀rẹ̀ àyàfi ìgbà tí oòrùn bá wọ̀. Ẹ wádìí ládùúgbò láti mọ ìgbà tí oòrùn máa ń wọ̀ lágbègbè yín. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó dára jù pé kí ìjọ kọ̀ọ̀kan ṣayẹyẹ Ìṣe Ìrántí tirẹ̀, èyí lè má ṣeé ṣe ní gbogbo ìgbà. Níbi tí ó bá jẹ́ pé àwọn ìjọ mélòó kan jọ ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba kan náà, ó ṣeé ṣe kí ìjọ kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ gba ilé mìíràn láti lò ní àṣálẹ́ yẹn. Níbi tí ó bá ti ṣeé ṣe, a dábàá pé ó kéré tán, kí àlàfo ogójì ìṣẹ́jú wà láàárín àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ kí àyè lè wà láti kí àwọn àlejò, kí a lè fún àwọn olùfìfẹ́hàn tuntun ní ìṣírí, kí a sì jàǹfààní lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ láti inú ayẹyẹ náà. Ó yẹ kí a tún ronú nípa ìṣòro ọkọ̀ àti ibi ìgbọ́kọ̀sí pẹ̀lú, tí ó kan pé kí èrò bọ́ sílẹ̀ nínú ọkọ̀ tàbí kí wọ́n wọkọ̀. Kí ẹgbẹ́ àwọn alàgbà pinnu ìṣètò tí yóò dára jù lọ ní àdúgbò wọn.

◼ Àkànṣe àsọyé fún gbogbo ènìyàn fún àkókò Ìṣe Ìrántí ọdún 1999 ni a óò sọ ní ọjọ́ Sunday, April 18. Àkọlé àsọyé náà ni, “Ìbádọ́rẹ̀ẹ́ Tòótọ́ Pẹ̀lú Ọlọ́run àti Aládùúgbò.” A óò pèsè ìtòlẹ́sẹẹsẹ èrò. Kí àwọn ìjọ tí wọ́n bá ní ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká, àpéjọ àyíká, tàbí àpéjọ àkànṣe ní òpin ọ̀sẹ̀ yẹn sọ àkànṣe àsọyé yìí ní ọ̀sẹ̀ tí ó tẹ̀ lé e. Kò sí ìjọ tí ó gbọ́dọ̀ sọ àkànṣe àsọyé yìí ṣáájú April 18, 1999.

◼ Bẹ̀rẹ̀ láti February 1, 1999, ìwé pẹlẹbẹ náà, Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú? ni a óò máa kà ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́