ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 1/99 ojú ìwé 2
  • Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún January

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún January
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní January 4
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní January 11
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní January 18
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní January 25
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
km 1/99 ojú ìwé 2

Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún January

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní January 4

Orin 36

15 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Àwọn Ìfilọ̀ tí a yàn láti inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Bí ẹ bá yí àwọn àkókò ìpàdé yín padà ní January 1, ẹ rán gbogbo ìjọ létí láti lo ìwé ìléwọ́ láti fi ìṣètò tuntun náà hàn. Ṣàtúnyẹ̀wò “Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Tuntun fún Àpéjọ Àkànṣe.”

10 min: ‘Ẹ Má Ṣe Fi Àìdọ́gba So Pọ̀ Mọ́ra Sábẹ́ Àjàgà.’ Àsọyé láti ẹnu alàgbà, tí a gbé karí Ilé-Ìṣọ́nà, November 15, 1995, ojú ìwé 31.

20 min: Advance Medical Directive/ Release Card. Lẹ́yìn ìpàdé yìí, a óò fún Àwọn Ẹlẹ́rìí tí ó ti ṣe batisí ní káàdì tuntun kọ̀ọ̀kan, àwọn tí ó sì ní àwọn ọmọ aláìtójúúbọ́ tí kò tí ì ṣe batisí yóò gba Identity Card (Káàdì Ìdánimọ̀) fún ọmọ kọ̀ọ̀kan. A kò ní kọ ọ̀rọ̀ kún àwọn káàdì wọ̀nyí ní alẹ́ òní. Kí ẹ fara balẹ̀ kọ ọ̀rọ̀ kún inú wọn ní ilé ṣùgbọ́n kí ẹ MÁ ṢE bu ọwọ́ lù ú. Bíbuwọ́lù ú, jíjẹ́rìí sí i, àti kíkọ déètì sí gbogbo káàdì náà ni a óò ṣe lẹ́yìn Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ tí ń bọ̀, lábẹ́ àbójútó olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ. Kí ẹ tó buwọ́ lu àwọn káàdì náà, ẹ rí i dájú pé a ti kọ gbogbo ohun tí ó yẹ kí a kọ sínú wọn tán pátápátá. Kí àwọn tí ń bu ọwọ́ lu káàdì náà gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ń jẹ́rìí sí i jẹ́ kí ẹni tí ó ni káàdì náà buwọ́ lù ú níṣojú wọn. Nípa títún àwọn ọ̀rọ̀ tí a lò nínú káàdì yí kọ láti bá ipò àti ìdánilójú tiwọn mu, àwọn akéde tí kò tí ì ṣe batisí lè kọ ìtọ́sọ́nà tiwọn tí wọn yóò lò fún ara wọn àti fún àwọn ọmọ wọn. Kí àwọn olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ kan láti rí i dájú pé gbogbo àwọn tí a pín sí àwùjọ wọn rí ìrànwọ́ tí wọ́n nílò gbà láti kọ ọ̀rọ̀ kún káàdì Advance Medical Directive/Release. Kí ààbò tí ó dára jù lọ lè wà lábẹ́ òfin, a gbọ́dọ̀ kọ ọ̀rọ̀ kún káàdì yìí. Àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti August 1994, lábẹ́ ìsọ̀rí náà, “Awọn Ìgbésẹ̀ Àgbéṣáájú Ṣíṣekókó—Iwọ Ha Ti Gbé Wọn Síbẹ̀síbẹ̀ Bí?” ìpínrọ̀ 8 àti 9 sọ pé: “Ríi dájú pé gbogbo wọn mú àwọn àkọsílẹ̀ wọnyi lọ́wọ́ NÍGBÀ GBOGBO. Yẹ̀ ẹ́ wò lọ́wọ́ àwọn ọmọ rẹ ṣáájú kí wọn to lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ lójoojúmọ́, bẹ́ẹ̀ni, àní kí wọn tó lọ sí pápá ìṣeré pàápàá. Gbogbo wa níláti ríi dájú pé awọn àkọsílẹ̀ wọnyi wà pẹlu wa lẹ́nu iṣẹ́, nígbà ìsinmi, tabi ní awọn àpéjọpọ̀ Kristian. Máṣe wà láìní wọn lọ́wọ́! “Ronú nipa ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀ sí ọ bí a bá níláti gbé ọ wá sí iyàrá pàjáwìrì ilé-ìwòsàn ninu ipò lílekoko kan, láìmọ̀nǹkankanmọ́ tabi tí o kò lè fúnraàrẹ sọ̀rọ̀. Bí o kò bá ní àkọsílẹ̀ naa lọ́wọ́, tí kò sì sí ìbátan tabi alàgbà kankan ní ilé-ìwòsàn naa lati gbẹnusọ fún ọ, tí wọn sì pinnu pé o ‘nílò ẹ̀jẹ̀,’ ṣíṣeéṣe naa wà pé iwọ yoo gba ẹ̀jẹ̀. Lọ́nà tí ó baninínújẹ́, èyí ti ṣẹlẹ̀ sí awọn kan. Ṣugbọn nígbà tí a bá ni àkọsílẹ̀ naa, ó ń gbẹnusọ fún wa, ní ṣíṣàlàyé ohun tí a fẹ́.” Ní báyìí, ọ̀pọ̀ dókítà tí wọ́n fọwọ́ sowọ́ pọ̀ ní Nàìjíríà ń bọ̀wọ̀ fún káàdì Medical Directive/Release. Wọ́n sọ pé kí àwọn ará máa mú káàdì náà káàkiri láti fi ara wọn hàn àní nígbà tí wọ́n bá wà ní ipò pàjáwìrì.

Orin 61 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní January 11

Orin 88

10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ṣàlàyé ìṣètò iṣẹ́ ìsìn pápá fún oṣù January.

20 min: Ìwọ Ha Máa Ń Ṣàyẹ̀wò Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́ Bí? Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Lọ́dọọdún, Society máa ń pèsè ìwé kékeré náà, Ṣíṣàyẹ̀wò Ẹsẹ Ìwé Mímọ́. Ǹjẹ́ ẹ máa ń lo ìtẹ̀jáde yìí dáadáa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan tàbí gẹ́gẹ́ bí ìdílé? Ṣàlàyé àwọn ìdí ṣíṣàǹfààní tí ó fi yẹ kí a máa ṣàyẹ̀wò ẹsẹ Ìwé Mímọ́ fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan. Jíròrò àlàyé tí ó wà nínú ọ̀rọ̀ ìṣáájú ìwé náà, Ṣíṣàyẹ̀wò Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—1999, ojú ìwé 3 àti 4. Ké sí àwọn akéde láti ṣàlàyé àkànṣe ìsapá tí wọ́n ń ṣe láti jíròrò ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ojoojúmọ́ àti àlàyé wọn ní ti gidi lẹ́nì kọ̀ọ̀kan àti gẹ́gẹ́ bí ìdílé.

15 min: “Ẹ Mú Sùúrù.” Ìjíròrò láàárín àwọn mẹ́ńbà ìdílé kan. Wọ́n ṣàyẹ̀wò àwọn ọ̀nà tí wọ́n lè gbà mú sùúrù dáadáa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn. Fi àlàyé tí ó bá a mu kún un láti inú Ilé-Ìṣọ́nà, June 15, 1995, ojú ìwé 12.

Orin 135 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní January 18

Orin 169

10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn ìnáwó.

10 min: Àìní àdúgbò.

10 min: “Àwọn Alábòójútó Tí Ń Mú Ipò Iwájú—Àwọn Olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ.” Àsọyé láti ẹnu olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ kan tí ó jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ, tí ó ṣàyẹ̀wò àwọn ẹrù iṣẹ́ rẹ̀. Ó fi hàn bí irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ ṣe ń fi kún ìtẹ̀síwájú àti ìlera ìjọ nípa tẹ̀mí. Fi àwọn àlàyé pàtàkì kún un láti inú ìwé Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-Ojiṣẹ Wa, ojú ìwé 43 sí 45, àti ojú ìwé 74 sí 76.

15 min: “Fífi Ìwé Pẹlẹbẹ Béèrè Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́.” Ìjíròrò lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

Orin 197 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní January 25

Orin 201

10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò.

20 min: “Láti Ẹnu Àwọn Ìkókó.” Àsọyé láti ẹnu alàgbà kan, tí a gbé karí Ilé-Ìṣọ́nà, January 1, 1995, ojú ìwé 24 sí 26.

15 min: “Ìyípadà Nínú Iye Wákàtí Tí A Ń Béèrè Lọ́wọ́ Àwọn Aṣáájú Ọ̀nà.” Àsọyé tí alàgbà sọ. Gbóríyìn fún àwọn aṣáájú ọ̀nà tí ń bẹ nínú ìjọ, sì fún àwọn akéde púpọ̀ sí i níṣìírí láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ àti aṣáájú ọ̀nà déédéé, kí wọ́n ní in lọ́kàn láti fi kún ìgbòkègbodò wọn ní oṣù March, April, àti May. Fi ìsọfúnni kún un láti inú àwọn àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti February 1997 àti July 1998.

Orin 225 àti àdúrà ìparí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́