Ìyípadà Nínú Iye Wákàtí Tí A Ń Béèrè Lọ́wọ́ Àwọn Aṣáájú Ọ̀nà
1 Gbogbo wa ló mọrírì níní àwọn aṣáájú ọ̀nà déédéé àti aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ tí ń ṣiṣẹ́ kára nínú ìjọ. Kódà níbi tí ìpínlẹ̀ kò ti pọ̀ tí a sì ń ṣe wọ́n kúnnákúnná déédéé, àwọn aṣáájú ọ̀nà ti fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ nípa iṣẹ́ ìsìn Ìjọba tí wọ́n ń fi ìtara ṣe. Wọ́n ti fún gbogbo akéde níṣìírí láti máa jẹ́ kí ọwọ́ wọn dí ní wíwá àwọn tí wọ́n “ní ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́” kiri.—Ìṣe 13:48.
2 Society ti kíyè sí ìṣòro tí ń ga sí i tí àwọn aṣáájú ọ̀nà ń dojú kọ, pàápàá ní ti rírí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tí ó jẹ́ aláàbọ̀ àkókò ṣe tí yóò jẹ́ kí wọ́n lè kúnjú àìní wọn dáadáa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan kí wọ́n lè máa bá a nìṣó nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Ní báyìí, ipò ọrọ̀ ajé ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ tún mú kí ó túbọ̀ ṣòro fún àwọn mìíràn láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó wù wọ́n láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ní àwọn oṣù lọ́ọ́lọ́ọ́, a ti fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ìwọ̀nyí àti àwọn ìdí mìíràn.
3 Nítorí náà, lójú ìwòye ohun tó wà lókè yìí, Society ti dín wákàtí tí a ń béèrè lọ́wọ́ àwọn aṣáájú ọ̀nà déédéé àti aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ kù. Bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 1999, àádọ́rin [70] wákàtí lóṣù tàbí àròpọ̀ òjìlélẹ́gbẹ̀rin [840] wákàtí lọ́dún ni a óò máa béèrè lọ́wọ́ àwọn aṣáájú ọ̀nà déédéé. Àádọ́ta [50] wákàtí ni a óò máa béèrè lọ́wọ́ àwọn aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù. Wákàtí tí a ń béèrè lọ́wọ́ àwọn aṣáájú ọ̀nà àkànṣe àti míṣọ́nnárì kò yí padà níwọ̀n bí Society ti ń ràn wọ́n lọ́wọ́ kí ó lè ṣeé ṣe fún wọn láti gbọ́ bùkátà wọn ṣíṣe kókó nípa ti ara. Nípa báyìí, wọ́n lè túbọ̀ pọkàn pọ̀ sórí iṣẹ́ wíwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn tí wọ́n ń ṣe.
4 A retí pé ìyípadà tí a ṣe sí iye wákàtí tí a ń béèrè yìí yóò ran àwọn aṣáájú ọ̀nà púpọ̀ sí i lọ́wọ́ láti máa bá a nìṣó nínú àǹfààní iṣẹ́ ìsìn ṣíṣeyebíye yìí. Ó yẹ kí ó tún ṣí ọ̀nà fún àwọn akéde púpọ̀ sí i láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà déédéé àti aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Ẹ wo ìbùkún tí èyí yóò jẹ́ fún gbogbo àwọn tí ó wà nínú ìjọ!