Ṣé Ọ̀nà Àtiṣe Aṣáájú Ọ̀nà Ti Ṣí Sílẹ̀ fún Ọ Báyìí?
1 Ẹṣin ọ̀rọ̀ wa ti ọdún 1999 rán wa létí pé “ọjọ́ ìgbàlà” Jèhófà la ṣì wà. (2 Kọ́r. 6:2) Ṣùgbọ́n ọjọ́ ìgbàlà rẹ̀ máa tó dópin. Nígbà náà, “ọjọ́ ìdájọ́” rẹ̀ yóò bẹ̀rẹ̀. (2 Pét. 2:9) Láàárín àkókò tí Jèhófà fi ń bá a lọ láti máa nawọ́ àǹfààní ìgbàlà sí aráyé, ẹ wo bó ṣe ń múni láyọ̀ tó láti rí àwọn tí ń pọ̀ sí i ṣáá tí wọ́n ń tẹ́wọ́ gbà ìgbàlà!
2 Àwọn èèyàn Jèhófà ti sakun láti kájú ìpèníjà dídé ọ̀dọ̀ àwọn tó bá dáhùn kó tó pẹ́ jù. Fún ọ̀pọ̀ akéde Ìjọba náà, èyí ti túmọ̀ sí wíwọnú iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà. Ọ̀nà ha ti ṣí sílẹ̀ fún ọ wàyí láti ṣe aṣáájú ọ̀nà bí? Èé ṣe tí a fi béèrè?
3 Ìmọrírì Tí A Fi Hàn: Gẹ́gẹ́ bí a ṣe ṣèfilọ̀ nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti January 1999, a ti dín iye wákàtí tí a ń béèrè lọ́wọ́ àwọn aṣáájú ọ̀nà déédéé àti aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ kù. Láti lè kájú iye wákàtí tuntun tí a ń béèrè, àwọn aṣáájú ọ̀nà déédéé nílò láti ya àádọ́rin wákàtí sọ́tọ̀ lóṣù fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà kí ó sì jẹ́ òjìlélẹ́gbẹ̀rin [840] wákàtí lọ́dún iṣẹ́ ìsìn kọ̀ọ̀kan. Àwọn aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ yóò máa lo àádọ́ta wákàtí nínú iṣẹ́ ìsìn náà lóṣù. Díẹ̀ nìyí nínú ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ìmọrírì tí a ti rí gbà nítorí àwọn ìyípadà yìí:
“Ẹ̀bùn aláyọ̀ mà lèyí o látọ̀dọ̀ Baba wa ọ̀run!”
“Kò sọ́rọ̀ táa lè fi ṣàpèjúwe ìmọ̀lára ìdùnnú, ìfẹ́, àti ìmoore táa ní fún ìpèsè yìí!”
“Yóò mú kó túbọ̀ rọrùn gidigidi láti ṣiṣẹ́ níbàámu pẹ̀lú àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ wa!”
“Àdúrà wa ni pé káwọn púpọ̀ sí i bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún báyìí kí wọ́n sì máa gbádùn àwọn ìbùkún tí ń wá láti inú sísin Jèhófà lọ́nà gbígbòòrò.”
4 Bí a ṣe ń sún mọ́ òtéńté ọjọ́ ìgbàlà Ọlọ́run, ó hàn gbangba pé Jèhófà ń fẹ́ kí àwọn èèyàn rẹ̀ kígbe ìyìn ńláǹlà tó kẹ́yìn. Ìhìn iṣẹ́ yìí túbọ̀ ń pọ̀ sí i, ó sì túbọ̀ ń lágbára sí i (1) ní ti iye àwọn olùpòkìkí Ìjọba náà tí ń pọ̀ sí i ṣáá àti (2) ní ti bí olúkúlùkù ṣe ń wá ọ̀nà láti mú kí ohun tí òun lè ṣe nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà pọ̀ sí i. Jèhófà “tí ń mú kí ó dàgbà” ti mú àṣeyọrí wá lọ́nà méjèèjì nípa bíbùkún ẹ̀mí ìmúratán tí gbogbo àwọn tó tẹ́wọ́ gba ìgbàlà ní.—1 Kọ́r. 3:6, 7; Sm. 110:3.
5 Má Ṣe Tàsé Ète Rẹ̀: Pọ́ọ̀lù ṣí àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ létí nípa ọjọ́ ìgbàlà Jèhófà pé: “Ní bíbá a [Jèhófà] ṣiṣẹ́ pọ̀, àwa ń pàrọwà fún yín pẹ̀lú pé kí ẹ má ṣe tẹ́wọ́ gba inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run kí ẹ sì tàsé ète rẹ̀.” A kì yóò “tàsé ète rẹ̀” bí a bá wo ìsinsìnyí gẹ́gẹ́ bí ‘àkókò ìtẹ́wọ́gbà gan-an’ láti ṣiṣẹ́ fún ìgbàlà àwọn ẹlòmíràn ní gbogbo ìgbà tí àǹfààní bá ṣí sílẹ̀. (2 Kọ́r. 6:1, 2) Lónìí, àwọn ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù túbọ̀ jẹ́ kánjúkánjú. Àwọn Kristẹni tí ń fi ìfẹ́ àtọkànwá hàn fún Jèhófà ń ka kíkópa ní kíkún bó bá ti lè ṣeé ṣe tó nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó ti yàn fún wọn, sí àǹfààní. Nísinsìnyí, ǹjẹ́ o lè túbọ̀ kópa ní kíkún nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà déédéé?
6 Góńgó Tó Bọ́gbọ́n Mu Ni: Ní Nàìjíríà, ó jẹ́ góńgó wa láti rí i kí ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25,000] àwọn aṣáájú ọ̀nà déédéé forúkọ sílẹ̀ ní September 1. A gbà gbọ́ pé góńgó yìí bọ́gbọ́n mu, a sì lè lé e bá. Èé ṣe tí a fi ní ìgbọ́kànlé yìí? Ní March 1997, a rí i pé ẹgbẹ̀rún mọ́kàndínlógún àti igba ó lé méjìdínlógún [19,218] àwọn arákùnrin àti arábìnrin ló ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlógún [17,000] tó ṣe é ní April 1998. Ọ̀pọ̀ lára wọn ló ròyìn ọgọ́ta wákàtí—ìyẹn fi wákàtí mẹ́wàá péré dín sí wákàtí tuntun tí a ń béèrè lọ́wọ́ aṣáájú ọ̀nà déédéé! Kódà bó bá jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin péré lára àwọn tó ti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ló forúkọ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà déédéé kí ọdún iṣẹ́ ìsìn yìí tó parí, yóò ṣeé ṣe fún wa láti bẹ̀rẹ̀ oṣù September pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25,000] aṣáájú ọ̀nà alákòókò kíkún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ!
7 Ìṣètò Ló Ń Béèrè: Ǹjẹ́ ó dà bíi pé agbára ẹ kò lè gbé àádọ́rin wákàtí lóṣù? Bóyá ríronú nípa wákàtí mẹ́tàdínlógún lọ́sẹ̀ yóò ṣèrànwọ́. Nípa lílo àpẹẹrẹ ìṣètò ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó wà lójú ìwé tó tẹ̀ lé e, gbìyànjú láti ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ aṣáájú ọ̀nà déédéé tí yóò bá àyíká ipò tìrẹ mu. Láti ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ tìrẹ, bá àwọn aṣáájú ọ̀nà tó nírìírí sọ̀rọ̀ láti gba ìmọ̀ràn wọn nípa bí wọ́n ṣe lè ṣe iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹrù iṣẹ́ tiwọn àti ti ìdílé. Béèrè lọ́wọ́ alábòójútó àyíká rẹ nípa bí àwọn aṣáájú ọ̀nà tó wà ní àyíká yín ṣe ṣètò ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìsìn wọn lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Wá yíjú sí Jèhófà láti bù kún àwọn ìwéwèé rẹ láti ṣe aṣáájú ọ̀nà.—Òwe 16:3.
8 Ẹ Fi Í Ṣe Iṣẹ́ Ìdílé: Ǹjẹ́ ẹ ti ronú nípa fífi ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà ṣe iṣẹ́ ìdílé? Ẹ lè jókòó pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé kí ẹ sì jíròrò—pẹ̀lú ìwéwèé tí ẹ fara balẹ̀ ṣe àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ dáadáa—bí ẹnì kan tàbí méjì nínú àwọn mẹ́ńbà ìdílé yín ṣe lè ṣe aṣáájú ọ̀nà. Ó yéni pé, àwọn kan yóò rí i pé lẹ́yìn fífi àìlábòsí ṣàyẹ̀wò àyíká ipò wọn, kò ní lè ṣeé ṣe fún wọn láti ṣe aṣáájú ọ̀nà déédéé báyìí. Bó bá rí bẹ́ẹ̀, fi ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà ṣe góńgó ọjọ́ iwájú. Ṣùgbọ́n, bẹ̀rẹ̀ sí wéwèé, kí o sì ṣiṣẹ́ lórí bí o ṣe máa bẹ̀rẹ̀ sí ṣe aṣáájú ọ̀nà ní ọjọ́ kan pàtó. Bóyá o lè ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ fún àwọn ìgbà mélòó kan nínú ọdún kí o tó wá lè ṣe iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà déédéé.
9 Onírúurú nǹkan ló ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn aṣáájú ọ̀nà déédéé tí iye wọn ju ẹgbẹ̀rún méjìlélógún [22,000] lọ tí wọ́n forúkọ sílẹ̀ ní Nàìjíríà lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí. Kì í ṣe gbogbo wọn ni ara wọ́n le dáadáa, ọ̀pọ̀ lára wọ́n sì ní ẹrù ìdílé àti ẹrù ìnáwó tí wọ́n ń gbé. Àwọn kan ti ń darúgbó, àwọn mìíràn sì jẹ́ ọ̀dọ́ tí kò láya tàbí ọkọ. Ọ̀pọ̀ ló jẹ́ arákùnrin tí wọ́n ní ẹrù ìdílé àti ẹrù iṣẹ́ nínú ìjọ. Gbogbo àwọn wọ̀nyí ló ń “ra àkókò tí ó rọgbọ padà” fún ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà, tó túmọ̀ sí pé lọ́pọ̀ ìgbà wọ́n ní láti máa gbé ìgbésí ayé tí kì í ṣe ti olówó gọbọi ṣùgbọ́n tó túbọ̀ ń tẹ́ni lọ́rùn.—Kól. 4:5.
10 Ṣé Ó Yẹ Kí O Mú Nǹkan Rọrùn? Mímú kí ìgbésí ayé rẹ má ṣe jẹ́ ti olówó gọbọi lè jẹ́ kọ́kọ́rọ́ tí yóò ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ọ láti ṣe aṣáájú ọ̀nà. Ṣé ìgbésí ayé rẹ dà bí ilé ńlá tó ní àwọn yàrá àti èlò ọ̀ṣọ́ tí kò pọndandan, tó ń béèrè ọ̀pọ̀ àkókò, owó, àti iṣẹ́ láti tọ́jú wọn? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, fífi àyíká ipò tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì kọ́ra lè jẹ́ kí o ṣe aṣáájú ọ̀nà. Ǹjẹ́ o lè dín àkókò tí o ń lò lẹ́nu iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ kù? Ǹjẹ́ o lè ra àkókò padà láti inú àwọn ìgbòkègbodò tí kò pọndandan tàbí kí o túbọ̀ lo ìwọ̀ntúnwọ̀nsì nínú àkókò tí o ń lò lẹ́nu eré ìtura?
11 Ní 1 Tímótì 6:8, Bíbélì gbà wá nímọ̀ràn pé: “Bí a bá ti ní ohun ìgbẹ́mìíró àti aṣọ, àwa yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí.” Jíjẹ́ kí nǹkan díẹ̀ tẹ́ni lọ́rùn jẹ́ kókó pàtàkì nínú ṣíṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, ó sì máa ń mú kó rọrùn láti fi àwọn nǹkan tẹ̀mí sí ipò àkọ́kọ́. (Mát. 6:22, 33) Ìwé Yearbook ti ọdún 1998, ní ojú ewé 104, nínú ìròyìn nípa Japan, pèsè àwọn ìdámọ̀ràn mélòó kan ní ti ìdí tí ọ̀pọ̀ fi ń ṣe aṣáájú ọ̀nà ní orílẹ̀-èdè náà. Gbé ọ̀kan yẹ̀ wò: “Òótọ́ ni pé ní gbogbo gbòò, ilé àwọn ará Japan kì í lẹ́rù púpọ̀, nípa báyìí, àkókò díẹ̀ ni ìtọ́jú rẹ̀ máa ń gbà, fún àwọn tó sì pọ̀ jù lọ, ó jẹ́ àṣà wọn láti máa gbé ìgbé ayé tí kì í ṣe ti olówó gọbọi.” Ǹjẹ́ kì í ṣe ohun tí 1 Tímótì 6:8 túmọ̀ sí ní pàtàkì nìyẹn?
12 Kárí ayé, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run túbọ̀ ń tẹra mọ́ wíwàásù ìhìn rere náà kí ọjọ́ ìgbàlà Jèhófà tó dé òpin. Lọ́nà tí ń gba oríyìn, ní ìpíndọ́gba lọ́dún tó kọjá, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin tó kópa nínú onírúurú iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà lóṣooṣù. O ha lè ṣàtúnṣe ìgbòkègbodò rẹ kí o lè dara pọ̀ mọ́ wọn bí? A ké sí ọ láti fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ìgbòkègbodò rẹ tàdúràtàdúrà bí o ṣe ń dáhùn ìbéèrè yìí: “Ṣé ọ̀nà àtiṣe aṣáájú ọ̀nà ti ṣí sílẹ̀ fún ọ báyìí?”
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 3]
GÓŃGÓ: ẸGBẸ̀RÚN MẸ́Ẹ̀Ẹ́DỌ́GBỌ̀N [25,000] AṢÁÁJÚ Ọ̀NÀ DÉÉDÉÉ!
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 4]
Àpẹẹrẹ Ìṣètò Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Aṣáájú Ọ̀nà Déédéé
Ohun tí a ń fẹ́: Wákàtí 17 lọ́sẹ̀
Ọjọ́ Kan Láàárín Ọ̀sẹ̀ àti Òpin Ọ̀sẹ̀
Ọjọ́ Wákàtí
Friday 8
Saturday 6
Sunday 3
Àròpọ̀ Wákàtí: 17
Ọjọ́ Méjì Láàárín Ọ̀sẹ̀ àti Ọjọ́ Saturday
Ọjọ́ Wákàtí
Tuesday 7
Thursday 7
Saturday 3
Àròpọ̀ Wákàtí: 17
Ọjọ́ Mẹ́ta Láàárín Ọ̀sẹ̀ àti Ọjọ́ Sunday
Ọjọ́ Wákàtí
Monday 5
Wednesday 5
Friday 5
Sunday 2
Àròpọ̀ Wákàtí: 17
Ìrọ̀lẹ́ Ọjọ́ Méjì àti Òpin Ọ̀sẹ̀
Ọjọ́ Wákàtí
Monday 3
Wednesday 3
Saturday 8
Sunday 3
Àròpọ̀ Wákàtí: 17
Ṣe Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Aṣáájú Ọ̀nà Déédéé Tìrẹ
Ọjọ́ Wákàtí
Monday
Tuesday
Wednesday
Thursday
Friday
Saturday
Sunday
Àròpọ̀ Wákàtí: 17