ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 6/15 ojú ìwé 9-12
  • Sùúrù—Èéṣe Tí Ó Fi Ṣọ̀wọ́n Tóbẹ́ẹ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Sùúrù—Èéṣe Tí Ó Fi Ṣọ̀wọ́n Tóbẹ́ẹ̀?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Àpẹẹrẹ Àìnísùúrù
  • Àwọn Ohun Tí Ń Fa Àìnísùúrù
  • Sùúrù—Èéṣe Tí Ó Fi Ṣeyebíye Tóbẹ́ẹ̀
  • Àwọn Àpẹẹrẹ Tí Ń Gbéniró
  • Àwọn Èrè Sùúrù
  • Ẹ Máa Ní Sùúrù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
  • Ìwọ Ha Lè Ṣe Sùúrù Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ẹ Máa Mú Sùúrù Bíi Ti Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Sùúrù Jèhófà Àti Jésù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 6/15 ojú ìwé 9-12

Sùúrù—Èéṣe Tí Ó Fi Ṣọ̀wọ́n Tóbẹ́ẹ̀?

EMILIO ti lé ní ẹni 60 ọdún.a Ohun ìbànújẹ́ kan ni ó gbé e wá sí Oahu—láti sìnkú ọmọkùnrin rẹ̀ tí ó ti dàgbà. Bí ó ti ń pọ́nkè lọ ní òpópónà dídákẹ́jẹ́ẹ́ kan tí ó sì ń bá àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀, ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan tí ń sá eré àsápajúdé bí ó ti ń fẹ̀yìnrìn lọ sí ọ̀nà tí ó yà lọ sí ilé kan mú Emilio tagìrì. Ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ náà fẹ́rẹ̀ gbá a, àti nítorí ìbínú àti àìnísùúrù, Emilio pariwo mọ́ awakọ̀ náà ó sì gbá ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ náà ní àbàrá. Àríyànjiyàn kan tẹ̀lé e. Ó dàbíi pé awakọ̀ náà ti Emilio, ẹni tí ó ṣubú tí ó sì fi orí gbá kọnkéré. Ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn náà, Emilio kú nítorí ọgbẹ́ orí rẹ̀. Ẹ wo irú ìyọrísí tí ó bani nínú jẹ́ tí èyí jẹ́!

A ń gbé nínú ayé kan níbi tí sùúrù ti jẹ́ ànímọ́ tí ó ṣọ̀wọ́n. Púpọ̀ síi àwọn tí ń wa ohun ìrìnnà ni ń sáré àsápajúdé. Àwọn mìíràn ń gbẹ́nu bọ ọkọ̀ iwájú wọn nídìí—wọ́n ń súnmọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí ju bí ó ti yẹ lọ—àwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ ń sá gbogbo eré tí agbára ọkọ̀ náà lè sá. Síbẹ̀ àwọn mìíràn ń yà kiri láti ìlà kan sí òmíràn nítorí wọn kò lè faramọ́ wíwà lẹ́yìn ọkọ̀ mìíràn. Nínú ilé, àwọn mẹ́ḿbà ìdílé lè fi ààyè gba ìrufùfù ìbínú kí wọ́n sì di oníwà-ipá. Àwọn Kristian kan pàápàá lè jẹ́ kí inú wọn ru sókè lọ́nà tí ó rékọjá ààlà nítorí àìdójú-ìwọ̀n àti àṣìṣe àwọn arákùnrin wọn nípa ti ẹ̀mí.

Èéṣe tí sùúrù fi ṣọ̀wọ́n tóbẹ́ẹ̀? Ó ha ti máa ń fìgbà gbogbo rí bẹ́ẹ̀ bí? Èéṣe tí ó fi ṣòro tóbẹ́ẹ̀ láti ní sùúrù ní ọjọ́ tiwa?

Àwọn Àpẹẹrẹ Àìnísùúrù

Bibeli sọ nípa obìnrin kan tí kò dúró láti fi ọ̀rọ̀ lọ ọkọ rẹ̀ kí ó tó ṣe ìpinnu pàtàkì kan. Efa ni orúkọ rẹ̀. Láìkò dúró de Adamu, bóyá lápákan nítorí àìnísùúrù, ó jẹ èso tí a kàléèwọ̀ náà. (Genesisi 3:1-6) Kí ni nípa ti ọkọ rẹ̀? Òun pàápàá ti lè fi àìnísùúrù hàn nípa títẹ̀lé Efa láti dẹ́ṣẹ̀ láì kọ́kọ́ tọ Jehofa, Bàbá rẹ̀ ọ̀run lọ, fún ìrànlọ́wọ́ tàbí ìdarísọ́nà. Ìwọra wọn, tí ó ṣeé ṣe kí ó papọ̀ mọ́ àìnísùúrù tí ó yọrí sí ẹ̀ṣẹ̀, ní àbájáde tí ó burú fún gbogbo wa. Láti ọ̀dọ̀ wọn ni àwa pẹ̀lú ti gba ìtẹ̀sí náà láti dá ẹ̀ṣẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ogún, èyí tí ó ní nínú ìfẹgẹ̀ àti àìnísùúrù.—Romu 5:12.

Ní nǹkan bí 2,500 ọdún lẹ́yìn ẹ̀ṣẹ̀ àwọn òbí wa àkọ́kọ́, àwọn ọmọ Israeli, àwọn ènìyàn àyànfẹ́ Ọlọrun, ṣàfihàn àìní ìgbàgbọ́ tí ń bá a nìṣó lọ́nà tí ó jinlẹ̀, bákan náà sì ni àìnísùúrù. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jehofa ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà wọ́n là lọ́nà ìyanu kúrò nínú oko-ẹrú Egipti ni, kíákíá ni wọ́n “gbàgbé iṣẹ́ rẹ̀” tí “wọn kò sì dúró de ìmọ̀ rẹ̀.” (Orin Dafidi 106:7-14) Léraléra wọ́n ṣubú sínú àṣìṣe tí ó lékenkà nítorí wọn kò ní sùúrù. Wọ́n ṣe ẹgbọrọ màálù oníwúrà wọ́n sì sìn ín; wọ́n ráhùn nípa ìpèsè ti ara ti manna tí Jehofa ṣe fún wọn; ọ̀pọ̀ nínú wọn sì tilẹ̀ ṣọ̀tẹ̀ sí Mose, aṣojú tí Jehofa yàn látọ̀runwá. Nítòótọ́, àìnísùúrù wọn sún wọn sí ẹ̀dùn-ọkàn àti ìjábá.

Saulu, ọba ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́ ní Israeli, sọ àǹfààní kí ọmọ rẹ jẹ́ ọba lẹ́yìn rẹ̀ nù. Èéṣe? Nítorí ó kọ̀ láti dúró de wòlíì náà Samueli, ẹni tí ó yẹ kí ó ṣe ìrúbọ sí Jehofa. Ìbẹ̀rù ènìyàn sún Saulu láti sáré ṣáájú Samueli nínú rírú ẹbọ náà. Ronúwòye irú ìmọ̀lára tí ó ti níláti ní nígbà tí Samueli yọ gẹ́rẹ́ lẹ́yìn tí Saulu ti parí ayẹyẹ náà! Ìbá ṣe pé ó ti dúró fún ìṣẹ́jú díẹ̀ síi!—1 Samueli 13:6-14.

Ìbá ṣe pé Efa ti dúró de Adamu dípò kíkánjú lọ mú èso náà! Ìbá ṣe pé àwọn ọmọ Israeli ti rántí láti dúró de ìmọ̀ràn Jehofa! Bẹ́ẹ̀ni, sùúrù ìbá ti ṣèrànwọ́ láti gba àwọn àti àwa là kúrò nínú ẹ̀dùn-ọkàn àti ìrora tí ó pọ̀ púpọ̀.

Àwọn Ohun Tí Ń Fa Àìnísùúrù

Bibeli ràn wá lọ́wọ́ láti lóye kókó pàtàkì tí ń fa àìnísùúrù lónìí. Timoteu Kejì orí 3 ṣàpèjúwe ìran wa gẹ́gẹ́ bí èyí tí ń gbé ní “awọn àkókò lílekoko tí ó nira lati bálò.” Ó sọ pé àwọn ènìyàn “yoo jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, ajọra-ẹni-lójú, onírera . . . aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere.” (Ẹsẹ̀ 2, 3) Irú ìwà ìwọra àti anìkànjọpọ́n bẹ́ẹ̀ ni ó wà ní ọkàn-àyà àti èrò-inú ọ̀pọ̀ ènìyàn, èyí tí ó mú kí ó ṣòro fún gbogbo wọn, àní àwọn Kristian tòótọ́ pàápàá, láti ní sùúrù. Nígbà tí a bá rí àwọn ènìyàn ayé tí wọ́n ń sáré àsápajúdé tàbí tí wọ́n ń yọ fòkìfòkì síwájú àwọn tí wọ́n wà lórí ìlà tàbí tí wọ́n ń rọ̀jò èébú sí wa, sùúrù wa ni a lè pè níjà gidigidi. A lè dán wa wò láti farawé wọn tàbí gbẹ̀san lára wọn, kí a sì tipa báyìí rẹ ara wa sílẹ̀ sínú ìwà ìgbéraga onímọtara-ẹni-nìkan bíi tiwọn.

Nígbà mìíràn orí ìpinnu òdì tí a dé ni ó sún wa láti máṣe ní sùúrù. Ṣàkíyèsí bí ọlọ́gbọ́n Ọba Solomoni ṣe ṣàfihàn àjọṣepọ̀ tí ó wà láàárín ìkánjú, èrò-òdì àti àìnísùúrù, ìwà ìbínú: “Ẹni tí ó ní sùúrù sàn ju ẹlẹ́mìí ìrera lọ. Máṣe yára ní ẹ̀mí rẹ láti bínú, nítorí pé yíyára bínú sinmi ní àyà òmùgọ̀.” (Oniwasu 7:8, 9, NW) Bí a bá farabalẹ̀ láti rí bí ipò nǹkan ti rí gan-an lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ ṣáájú kí a tó hùwàpadà, ó ṣeé ṣe kí a lóye síi, kí a ní ẹ̀mí ìbánikẹ́dùn síi, kí a sì túbọ̀ ní sùúrù pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Ní ọwọ́ mìíràn ẹ̀wẹ̀, ẹ̀mí ìrera, anìkànjọpọ́n lè sún wa láti jẹ́ aláìgbatẹnirò, aláìnísùúrù, ọlọ́kàn kíkorò, bíi ti àwọn ọmọ Israeli awarùnkì, tí wọ́n ń kùn tí wọ́n sì yọ Mose lẹ́nu.—Numeri 20:2-5, 10.

Ìdí mìíràn tí ó fa àìnísùúrù tí ń pọ̀ síi nínú ayé yìí ni ipò àìnírètí rẹ̀, tí ó jẹ́ ìyọrísí sísọ ara wọn dàjèjì sí Jehofa. Dafidi sọ àìní náà fún ènìyàn láti ní ìrètí nínú Jehofa pé: “Ọkàn mi, ìwọ sá dúró jẹ́ẹ́ de Ọlọrun; nítorí láti ọ̀dọ̀ [rẹ̀] wá ni ìrètí mi.” (Orin Dafidi 62:5) Ọ̀pọ̀ ènìyàn tí kò mọ Jehofa ní ojú-ìwòye tí ó láàlà, tí ó dágùdẹ̀, nítorí náà wọ́n ń gbìyànjú láti lo gbogbo ìgbádùn àti èrè tí wọ́n lè jẹ ṣáájú kí wọ́n tó kú. Gẹ́gẹ́ bíi bàbá wọn nípa ti ẹ̀mí, Satani Èṣù, nígbà púpọ̀ ni wọn kò bìkítà nípa bí ìwà wọn ṣe lè dun àwọn mìíràn.—Johannu 8:44; 1 Johannu 5:19.

Abájọ nígbà náà tí sùúrù fi ṣọ̀wọ́n tóbẹ́ẹ̀ lónìí. Ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan búburú, onímọtara-ẹni-nìkan yìí, tí Satani jẹ́ ọlọrun rẹ̀, àti ìtẹ̀sí ẹ̀ṣẹ̀ ẹran ara aláìpé wa mú kí ó ṣòro fún gbogbo wa, àní àwọn olóòótọ́-ọkàn pàápàá, láti ní sùúrù. Síbẹ̀, Bibeli gbà wá níyànjú láti “mú sùúrù,” ní pàtàkì nípa ìṣàṣeparí àwọn ète Ọlọrun. (Jakọbu 5:8) Èéṣe ti sùúrù fi ṣeyebíye tóbẹ́ẹ̀? Èrè wo ni ó lè mú wá fún wa?

Sùúrù—Èéṣe Tí Ó Fi Ṣeyebíye Tóbẹ́ẹ̀

“Àwọn wọnnì tí wọ́n faradà pẹ̀lú sùúrù a máa ṣiṣẹ́sìn pẹ̀lú.” Akéwì Gẹ̀ẹ́sì kan John Milton ni ó sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní èyí tí ó lé ní ọ̀ọ́dúnrún ọdún sẹ́yìn nínú orin rẹ̀ kékeré kan tí àkọlé rẹ̀ ń jẹ́ “Nípa Ìfọ́jú Rẹ̀.” Ní ìbẹ̀rẹ̀ ewì náà, ó fi ìjákulẹ̀ àti àníyàn hàn nípa ìmọ̀lára rẹ̀ ti ṣíṣàì lè ṣiṣẹ́sin Ọlọrun lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ nítorí ó ti di afọ́jú nígbà tí ó ti lé ní ẹni 40 ọdún. Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ó ti hàn nínú ìlà tí ó gbẹ̀yìn ewì rẹ̀ tí a tọ́ka sí lókè yìí, ó ti wá mọ̀ pé ẹnì kan lè jọ́sìn Ọlọrun nípa fífi sùúrù farada ìpọ́njú kí ó sì farabalẹ̀ wá àwọn àǹfààní iṣẹ́-ìsìn tí ó bá wà. Milton rí ìjẹ́pàtàkì fífi sùúrù fọkàntẹ Ọlọrun.

Èyí tí ó pọ̀ jùlọ nínú wa lè ní ojú tí ó ríran dáradára, ṣùgbọ́n gbogbo wa ni a ní ààlà tí ó lè sún wa láti bínú tàbí ṣàníyàn. Báwo ni a ṣe lè jèrè sùúrù kí a sì fi í hàn?

Àwọn Àpẹẹrẹ Tí Ń Gbéniró

Bibeli fún wa ní àwọn àpẹẹrẹ àtàtà mélòókan nípa sùúrù. Sùúrù Jehofa mú kí ìyè àìnípẹ̀kun ṣeé ṣe fún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ẹ̀dá ènìyàn. (2 Peteru 3:9, 15) Nínú ìkésíni onínúrere rẹ̀ pé kí a gba àjàgà òun kí a sì “rí ìtura fún ọkàn [wa],” Jesu ṣàgbéyọ sùúrù àgbàyanu Bàbá rẹ̀. (Matteu 11:28-30) Ṣíṣàṣàrò lórí àwọn àpẹẹrẹ Jehofa àti Jesu lè ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ ní sùúrù.

Ẹnì kan tí ó dàbíi pé ó ní ìdí tí ó pọ̀ tó láti bínú, hùwà kíkorò, tàbí gbẹ̀san ni Josefu ọmọ Jakọbu. Àwọn arákùnrin rẹ̀ ti hùwà sí i lọ́nà tí ó burú jáì, wọ́n pète ikú rẹ̀ àti nígbẹ̀yìn gbẹ́yín wọ́n tà á sí oko ẹrú. Ní Egipti, láìka iṣẹ́-ìsìn rẹ̀ tí ó fi tọkàntọkàn ṣe, àti pẹ̀lú ìdúróṣinṣin sí Potifari sí, Josefu ni a fẹ̀sùn èké kàn tí a sì fi sẹ́wọ̀n. Ó fi sùúrù farada gbogbo ìpọ́njú rẹ̀, bóyá ní lílóye pé irú àdánwò bẹ́ẹ̀ lè ṣèrànwọ́ láti mú àwọn ète Jehofa ṣẹ. (Genesisi 45:5) Nítorí pé ó mú ìgbàgbọ́ àti ìrètí nínú Jehofa pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ àti òye dàgbà, Josefu lè ní sùúrù àní pàápàá lábẹ́ àyíká ipò tí ń dánniwò gan-an.

Ìrànlọ́wọ́ pàtàkì mìíràn ni ẹ̀mí mímọ́ Jehofa. Fún àpẹẹrẹ, bí ara wa bá ń tètè gbóná sódì tí a sì máa ń sọ̀rọ̀ tí kò báradé, a lè gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ́ kí a baà lè mú èso rẹ̀ dàgbà. Ṣíṣàṣàrò lórí ìkọ̀ọ̀kan àwọn èso wọ̀nyí, irú bí ìpamọ́ra àti ìkóra-ẹni-níjàánu, yóò ràn wá lọ́wọ́ láti rí bí wọ́n ṣe ní ìsopọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú sùúrù.—Galatia 5:22, 23.

Àwọn Èrè Sùúrù

Níní sùúrù lè mú ọ̀pọ̀ àǹfààní wá fún wa. Ó ń sọ wá di ẹni tí ìwà rẹ̀ dára síi ó sì ń pa wá mọ́ kúrò nínú híhùwà pẹ̀lú ìwàǹwára, àwọn ìwà òmùgọ̀. Ta ni nínú wa tí kò ti ṣe àṣìṣe tí ó dùn wá nítorí yíyára jù láti hùwàpadà sí àwọn ipò tí ó ṣòro tàbí ti másùnmáwo? A lè ti sọ ọ̀rọ̀ tí kò fi inúrere hàn tàbí hùwà ní ọ̀nà àìlẹ́kọ̀ọ́. A lè ti yọ̀ọ̀da fún àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí kò tó nǹkan láti di iṣu-ata-yán-anyàn-an pẹ̀lú ẹni ọ̀wọ́n kan tí a fẹ́ràn. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ìbínú, ijákulẹ̀, àti ìrora, a ti lè fi pẹ̀lú àbámọ̀ ronú pé, ‘Ìbá ṣe pé mo ti túbọ̀ ní sùúrù ni.’ Níní sùúrù lè dáàbòbò wá kúrò nínú ẹ̀dùn-ọkàn ní gbogbo ọ̀nà. Òtítọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ yìí nìkan fún ìgbésí-ayé wa ní àlàáfíà, ìbàlẹ̀-ọkàn, àti ìtẹ́lọ́rùn tí ó pọ̀ púpọ̀.—Filippi 4:5-7.

Jíjẹ́ onísùúrù tún lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní ọkàn-àyà tí ó balẹ̀, tí ó ṣee gbẹ́kẹ̀lé. Èyí lè yọrí sí gbígbádùn ìlera ti ara, ti èrò-ìmọ̀lára, àti ti ẹ̀mí tí ó dára síi. (Owe 14:30) Ìbínú tí a kò ṣàkóso, lè yọrí sí àìlera tí ó lekoko níti èrò-ìmọ̀lára àti ti ara àti ikú. Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, nípa níní sùúrù a lè ní ìṣarasíhùwà tí ó dára sí àwọn mìíràn, pàápàá àwọn arákùnrin wa nípa ti ẹ̀mí àti àwọn mẹ́ḿbà ìdílé wa. Nígbà náà a óò túbọ̀ ní ìtẹ̀sí láti máa gba ti àwọn ènìyàn rò kí a sì jẹ́ ẹni tí ń ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ kàkà kí a máa mú wọn bínú kí a sì máa ṣe lámèyítọ́. Nítorí ìdí èyí, àwọn mìíràn yóò rí i pé ó túbọ̀ rọrùn ó sì túbọ̀ gbádùn mọ́ wọn láti darapọ̀ mọ́ wa.

Àwọn alàgbà nínú ìjọ Kristian ní pàtàkì níláti ní sùúrù. Nígbà mìíràn, àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ wọn ń tọ̀ wọ́n wá pẹ̀lú àwọn ìṣòro tí ó lekoko. Àwọn olóòótọ́-ọkàn wọ̀nyí ni ọkàn wọn lè dàrú, kí ọkàn wọ́n gbọgbẹ́, tàbí kí a ti mú wọn soríkọ́, nígbà tí ó lè ti rẹ àwọn alàgbà fúnra wọn tàbí kí àwọn ìṣòro tí ara wọn tàbí ti ìdílé ti pín ọkàn wọn níyà. Síbẹ̀, ẹ wo bí ó ti ṣe pàtàkì tó pé kí àwọn alàgbà ní sùúrù nínú àwọn àyíká ipò tí ń pinnilẹ́mìí bẹ́ẹ̀! Ní ọ̀nà yìí wọ́n lè fúnni ní ìtọ́ni “pẹlu ìwàtútù” kí wọ́n sì “fi ọwọ́ pẹ̀lẹ́tù mú agbo.” (2 Timoteu 2:24, 25; Ìṣe 20:28, 29) Ìwàláàyè tí ó ṣeyebíye wà nínú ewu. Ẹ wo bí àwọn alàgbà tí wọ́n jẹ́ onínúrere, onífẹ̀ẹ́, àti onísùúrù ti jẹ́ ìbùkún fún ìjọ tó!

Àwọn olórí ìdílé gbọ́dọ̀ bá agboolé wọn lò pẹ̀lú sùúrù, òye, àti inúrere. Wọ́n sì tún gbọ́dọ̀ retí gbogbo mẹ́ḿbà ìdílé láti ní irú àwọn ànímọ́ kan náà yìí kí wọ́n sì fún wọn ní ìṣírí láti ṣe bẹ́ẹ̀. (Matteu 7:12) Èyí yóò dákún ìfẹ́ àti àlàáfíà ńláǹlà nínú ilé.

Níní sùúrù nígbà tí a bá ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ pápá yóò ran àwọn Kristian òjíṣẹ́ lọ́wọ́ láti gbádùn iṣẹ́-ìsìn yìí lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ síi. Wọn yóò lè túbọ̀ farada ìdágunlá àti ìṣàtakò tí wọ́n bá bá pàdé. Dípò jíjiyàn pẹ̀lú àwọn onílé tí ń bínú, àwọn òjíṣẹ́ onísùúrù yóò lè fúnni ní ìdáhùn pẹ̀lẹ́ tàbí kí wọ́n kúrò níbẹ̀ jẹ́ẹ́, kí wọ́n sì tipa báyìí di àlàáfíà àti ìdùnnú-ayọ̀ mú títí. (Matteu 10:12, 13) Síwájú síi, nígbà tí àwọn Kristian bá ń bá gbogbo ènìyàn lò pẹ̀lú sùúrù àti inúrere, àwọn ẹni-bí-àgùtàn yóò lè fà súnmọ́ ìhìn-iṣẹ́ Ìjọba náà. Jehofa ti bùkún ìsapá onísùúrù jákèjádò àgbáyé, bí ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn onínútútù olùwá òtítọ́ ti ń rọ́ wá sínú ijọ́ onífẹ̀ẹ́ Jehofa lọ́dọọdún.

Nítòótọ́, níní sùúrù yóò mú àwọn èrè àtàtà wá fún wa. A óò dènà ọ̀pọ̀ jàm̀bá àti ìṣòro tí híhùwà jàùjàù tàbí jíjẹ́ ẹni tí kò lè kó ahọ́n rẹ̀ níjàánu máa ń dá sílẹ̀. A óò láyọ̀ síi, ara wa yóò balẹ̀ síi, ó sì ṣeé ṣe kí a ní ìlera tí ó dára síi. A óò ní ìrírí ìdùnnú-ayọ̀ àti àlàáfíà ńláǹlà nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ wa, nínú ìjọ, àti nínú ilé. Ṣùgbọ́n ju gbogbo rẹ̀ lọ, a óò gbádùn ipò ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọrun. Nítorí náà dúró de Jehofa. Mú sùúrù!

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí orúkọ náà padà.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Báwo ni o ti ń ní sùúrù tó nínú ìgbésí-ayé ojoojúmọ́?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́