ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 1/99 ojú ìwé 1
  • “Ẹ Mú Sùúrù”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ẹ Mú Sùúrù”
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Sùúrù La Fi Ń Ṣe Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
  • Ẹ Máa Ní Sùúrù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
  • Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Sùúrù Jèhófà Àti Jésù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Ìwọ Ha Lè Ṣe Sùúrù Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
km 1/99 ojú ìwé 1

“Ẹ Mú Sùúrù”

1 Bí a ṣe rí i pé òpin ètò Sátánì túbọ̀ ń sún mọ́lé pẹ́kípẹ́kí, ó ṣe pàtàkì pé kí a “mú sùúrù” bí a ṣe ń dúró dé ọjọ́ ìdáǹdè Jèhófà. Ní àkókò ìkẹyìn yìí ní pàtàkì, àwọn ọ̀tá burúkú ń gbìyànjú láti yí àfiyèsí wa kúrò nínú ọ̀ràn ipò ọba aláṣẹ Jèhófà, tí ó gba iwájú jù lọ, kí wọ́n sì fi ọ̀kẹ́ àìmọye ohun tí ó jẹ́ ìfẹ́ ti ara ẹni kẹ́dẹ mú wa láti jẹ́ kí a ní ìpínyà ọkàn. Lọ́nà yìí, Sátánì yóò wá fẹ̀tàn mú kí a juwọ́ sílẹ̀ tàbí kí a dẹwọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà. (Ják. 5:7, 8; Mát. 24:13, 14) Ní àwọn ọ̀nà wo ni a wá lè gbà fi irú sùúrù tí a nílò hàn?

2 Nípa Níní Àmúmọ́ra: Nígbà tí a bá bá ìdágunlá tàbí àtakò pàdé lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, níní àmúmọ́ra yóò ràn wá lọ́wọ́ láti tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù wa. A kò ní di ẹni tí a tètè ń kó jìnnìjìnnì bá, tàbí kí a di ẹni tí a tètè ń mú bínú nígbà tí àwọn tí a bá bá pàdé bá sọ̀rọ̀ sí wa ṣàkàṣàkà tàbí tí wọ́n bá fi ìwọ̀sí lọ̀ wá. (1 Pét. 2:23) Okun inú yìí kò ní jẹ́ kí a máa sọ̀rọ̀ tí kò dára nípa àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ wa tí wọ́n bá ṣàìka iṣẹ́ wa sí tàbí tí wọ́n ń fi ẹ̀tanú hàn, ní mímọ̀ pé ṣe ni irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ yóò kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwa àti àwọn tí a bá jùmọ̀ wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn.

3 Nípa Fífi Sùúrù Tẹra Mọ́ Ọn: Ó lè gba sùúrù púpọ̀ gan-an bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé lẹ́yìn tí a ti bá ẹnì kan jíròrò lọ́nà tí ó dára lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn pápá, a kò tún bá ẹni náà nílé mọ́. Ohun kan náà ni a nílò bí àwọn tí a bá ń bá ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ kò bá tètè tẹ̀ síwájú tàbí kí wọ́n tètè mú ìdúró wọn fún òtítọ́. Àmọ́, ìyọrísí rere máa ń jẹyọ láti inú fífi sùúrù tẹra mọ́ ọn. (Gál. 6:9) Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni arábìnrin kan padà lọ sọ́dọ̀ ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ obìnrin kan kí ó tó lè bẹ̀rẹ̀ sí bá a kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà ìbẹ̀wò márùn-ún àkọ́kọ́ tí ó ṣe síbẹ̀, àwọn ọ̀ràn mìíràn dí obìnrin náà lọ́wọ́ gidigidi. Lẹ́ẹ̀kẹfà tí arábìnrin náà máa tún gbìyànjú, ńṣe lomi ń kán tótó lára aṣọ rẹ̀ bí òjò líle ṣe rẹ ẹ́ kanlẹ̀ nígbà tí ó fi máa débẹ̀, kò sì tún bá ẹnikẹ́ni nílé. Ṣùgbọ́n, níwọ̀n bí arábìnrin náà ti pinnu láti tún fún obìnrin náà láǹfààní ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo sí i, ó tún wá a lọ, ó sì rí i pé obìnrin náà ṣe tán láti kẹ́kọ̀ọ́. Lẹ́yìn náà, obìnrin náà tẹ̀ síwájú dáadáa, kò sì pẹ́ tí ó fi ya ìgbésí ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà.

4 A mọ̀ pé ọjọ́ Jèhófà kì yóò pẹ́. Nítorí náà, a ń dúró de ọ̀nà tí Jèhófà yóò gbà yanjú àwọn ọ̀ràn, ní mímọ̀ pé sùúrù Ọlọ́run yóò so èso rere. (Háb. 2:3; 2 Pét. 3:9-15) A ní láti mú sùúrù bí Jèhófà ṣe mú sùúrù, kí a má ṣe jáwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa. Nípasẹ̀ “ìgbàgbọ́ àti sùúrù,” máa wojú Jèhófà pé yóò san èrè fún ọ lẹ́nu iṣẹ́ àṣekára rẹ.—Héb. 6:10-12.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́