Àwọn Alábòójútó Tí Ń Mú Ipò Iwájú—Àwọn Olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ
1 Àǹfààní títayọ ni ó jẹ́ pé kí alàgbà kan tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan tí ó tóótun máa sìn gẹ́gẹ́ bí olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ. Bíbójútó àwọn àìní tẹ̀mí àwọn tí wọ́n wà ní àwùjọ rẹ̀ jẹ́ ẹrù iṣẹ́ pàtàkì. Àwọn ojúṣe rẹ̀ pín sí ọ̀nà mẹ́ta.
2 Kíkọ́ni Lọ́nà Tí Ó Múná Dóko: Ó ń béèrè pé kí olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ múra sílẹ̀ dáadáa láti lè máa fún àwùjọ rẹ̀ ní òye lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ó máa ń wá ọ̀nà láti mú kí ìmọrírì tí wọ́n ní fún ohun tí wọ́n ń kọ́ túbọ̀ jinlẹ̀ sí i. Dípò tí òun fúnra rẹ̀ ì bá fi máa sọ̀rọ̀ púpọ̀ jù nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, ohun tí ó yẹ kí ó ṣe nígbà tí ó bá pọndandan ni kí ó béèrè àwọn àfikún ìbéèrè tí ó ṣe ṣàkó láti fi fa àwọn kókó pàtàkì inú ẹ̀kọ́ náà yọ. Ìpèníjà tí ó dojú kọ ni bí yóò ṣe mú kí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lárinrin kí ó sì kún fún ẹ̀kọ́ àti bí yóò ṣe mú kí gbogbo ènìyàn lọ́wọ́ nínú ìjíròrò náà. Góńgó rẹ̀ ni láti gbéni ró nípa tẹ̀mí, láti tẹnu mọ́ bí a ṣe lè lo ẹ̀kọ́ náà lọ́nà tí ó gbéṣẹ́, àti láti mú kí ẹ̀kọ́ náà wọni lọ́kàn kí ó sì dé inú ọkàn-àyà.—1 Tẹs. 2:13.
3 Ìbẹ̀wò Olùṣọ́ Àgùntàn Tí Ó Ṣèrànwọ́: Olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ “dà bí ibi ìfarapamọ́sí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù àti ibi ìlùmọ́ kúrò lọ́wọ́ ìjì òjò.” (Aísá. 32:2) Ó ń ṣaájò àwọn tí ó wà ní àwùjọ rẹ̀ gidigidi, ó sì ń rí sí i pé a pèsè ìrànlọ́wọ́ nígbà tí ọ̀kan lára àwọn tó wà lábẹ́ àbójútó rẹ̀ bá rẹ̀wẹ̀sì.—Ìsík. 34:15, 16; 1 Tẹs. 2:7, 8.
4 Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìjíhìnrere Onítara: Olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ fọwọ́ pàtàkì mú ọ̀ràn ìṣètò tí ó gbéṣẹ́ kí gbogbo àwọn tí ó wà ní àwùjọ rẹ̀ lè kópa ní kíkún nínú iṣẹ́ ìsìn pápá. Ó ń mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ ìjíhìnrere, nítorí ó mọ̀ pé irú ẹ̀mí tí òun bá fi hàn nínú ìṣe déédéé, ìtara àti ìtúraká nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà yóò ran àwọn yòókù nínú àwùjọ rẹ̀. (Kól. 4:17; 2 Tẹs. 3:9) Bí àkókò ti ń lọ, òun yóò sapá láti bá mẹ́ńbà kọ̀ọ̀kan nínú àwùjọ rẹ̀ ṣiṣẹ́ pọ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn. Bí a bá fẹ́ túbọ̀ já fáfá sí i lẹ́nu iṣẹ́ wíwàásù àti kíkọ́ni, olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ lè ràn wá lọ́wọ́ láti lé góńgó yẹn bá.—1 Tím. 4:16; 2 Tím. 4:5.
5 Ìbùkún gidi ni àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn wọ̀nyí jẹ́ fún wa, àwọn tí wọ́n ti ṣe tán láti pèsè ìrànwọ́ àti ìtìlẹ́yìn onífẹ̀ẹ́ tí a nílò nípa tẹ̀mí fún wa. (1 Tẹs. 5:14) Ǹjẹ́ kí a máa fi ìmọrírì wa hàn fún ìpèsè àgbàyanu tí Jèhófà ṣe yìí nípa kíkópa déédéé nínú Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ àti nípa ṣíṣètìlẹ́yìn déédéé nínú iṣẹ́ ìjíhìnrere náà.—Héb. 10:25.