Àwọn Alábòójútó Tí Ń Mú Ipò Iwájú—Olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́
1 Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jèhófà ni olórí ọ̀nà tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń gbà pín oúnjẹ tẹ̀mí fún wa “ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.” (Mát. 24:45) Alàgbà tí ń darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ ní ẹrù iṣẹ́ ṣíṣe kókó gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ dídáńgájíá tí ń fi àpẹẹrẹ dídára lélẹ̀ ní ti ìgbésí ayé Kristẹni.—Róòmù 12:7; Ják. 3:1.
2 Kí olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ lè kọ́ni lọ́nà gbígbéṣẹ́, ó máa ń sapá gidigidi láti múra sílẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ó ń ṣe bẹ́ẹ̀ tàdúràtàdúrà pẹ̀lú ìfarabalẹ̀. Ọkàn-ìfẹ́ mímúná tí ó ní sí ìjọ máa ń hàn nípa bí ó ṣe ń sapá gidigidi láti rí i pé àkójọ ọ̀rọ̀ tí a ń kẹ́kọ̀ọ́ dé inú ọkàn wa. Ó máa ń darí àfiyèsí sí àwọn kókó pàtàkì tí ó wà nínú ẹ̀kọ́ náà, ó sì máa ń ràn wá lọ́wọ́ láti mọ bí wọ́n ṣe tan mọ́ ẹṣin ọ̀rọ̀ àpilẹ̀kọ náà.
3 Wíwo àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ṣáájú kí ó lè mọ ìwúlò wọn jẹ́ ara ìmúrasílẹ̀ dáadáa tí ó máa ń ṣe. Ó ń fi ìjẹ́pàtàkì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run hàn nípa fífún ìjọ níṣìírí láti lo Bíbélì dáadáa ní àsìkò ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Nígbà tí àlàyé ìjọ kò bá kárí kókó pàtàkì kan tàbí nígbà tí a kò bá ṣàlàyé bí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ pàtàkì kan ṣe wúlò, ó máa ń béèrè àfikún ìbéèrè láti mú kí ìsọfúnni náà ṣe kedere. Lọ́nà yìí, ó ń ràn wá lọ́wọ́ láti dórí èrò tí ó tọ̀nà kí a sì mọ bí a ṣe lè fi àwọn ohun tí a kọ́ sílò nínú ìgbésí ayé wa.
4 Ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé, olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ máa ń sakun láti mú ọ̀nà ìgbàkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ sunwọ̀n sí i. Òun kì í ṣe àlàyé púpọ̀ jù ṣùgbọ́n ó máa ń fún wa níṣìírí láti ṣàlàyé—ní ọ̀rọ̀ ara wa, ní ṣókí, kí ó sì sojú abẹ níkòó. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó lè rán wa létí pé kí ẹni tí ó bá kọ́kọ́ dáhùn ìpínrọ̀ kan dáhùn lọ́nà tí ó ṣe ṣókí, tí ó sì jẹ́ ìdáhùn tààràtà sí ìbéèrè tí a tẹ̀. Àwọn àfikún ìdáhùn láti ọ̀dọ̀ àwùjọ lè pe àfiyèsí sí bí a ṣe lè fi àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ sílò, àwọn àlàyé aṣètìlẹ́yìn, tàbí bí a ṣe lè fi àkójọ ọ̀rọ̀ náà sílò lọ́nà gbígbéṣẹ́. Nípa fífúnni ní ìṣírí láti múra sílẹ̀ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan àti gẹ́gẹ́ bí ìdílé, olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ máa ń gbìyànjú láti ru ìfẹ́-ọkàn ẹnì kọ̀ọ̀kan sókè láti kópa nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ náà.
5 Gẹ́gẹ́ bí “àwọn tí a kọ́ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà,” a mọrírì “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn,” irú bí àwọn olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ tí wọ́n “ń ṣiṣẹ́ kára nínú . . . kíkọ́ni.”—Aísá. 54:13; Éfé. 4:8, 11; 1 Tím. 5:17.