ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 3/99 ojú ìwé 3
  • Àwọn Ìfilọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìfilọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
km 3/99 ojú ìwé 3

Àwọn Ìfilọ̀

◼ Àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni ní March: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun fún ₦55 (ẹlẹ́yìn rírọ̀, ₦50). Ìfilọni àfidípò: Ìwé olójú ewé 192 èyíkéyìí mìíràn, kí a fi lọni ní iye tí a máa ń fi sóde. A óò sapá lákànṣe láti bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. April àti May: Gbogbo èdè—Àsansílẹ̀ owó fún Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Mú kí ìwé pẹlẹbẹ Béèrè wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún àwọn tí ó fi ọkàn-ìfẹ́ hàn, kí o sì sakun láti bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. June: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun.

◼ Kí àwọn akéde tí wọ́n fẹ́ láti sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní oṣù April àti May ṣe àwọn ìwéwèé wọn nísinsìnyí, kí wọ́n sì tètè fi ìwé ìwọṣẹ́ wọn sílẹ̀. Èyí yóò ran àwọn alàgbà lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ètò tí ó yẹ fún iṣẹ́ ìsìn pápá, kí wọ́n sì ní ìwé ìròyìn àti ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ mìíràn tí ó pọ̀ tó lọ́wọ́. Kí a kéde orúkọ gbogbo àwọn táa fọwọ́ sí láti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ fún ìjọ.

◼ Kí alábòójútó olùṣalága tàbí ẹnì kan tí òun yàn ṣàyẹ̀wò àkáǹtì ìjọ ní March 1 tàbí bí ó bá ti lè ṣeé ṣe kí ó yá tó lẹ́yìn náà. Bí ẹ bá ti ṣe èyí, ẹ ṣe ìfilọ̀ fún ìjọ lẹ́yìn tí ẹ bá ti ka ìròyìn ìnáwó tí ó tẹ̀ lé e.

◼ A óò ṣe Ìṣe Ìrántí ní Thursday, April 1, 1999. Bó bá jẹ́ pé ìjọ yín máa ń ṣe àwọn ìpàdé lọ́jọ́ Thursday, ẹ yí àwọn ìpàdé náà sí ọjọ́ mìíràn láàárín ọ̀sẹ̀ náà bí àyè bá wà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Bí ọ̀ràn kò bá rí bẹ́ẹ̀, tí ó sì kan Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn yín, ẹ lè fi apá tó bá kan ìjọ yín gbọ̀ngbọ̀n kún Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn mìíràn.

◼ Kí àwọn tí ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ fi gbogbo àsansílẹ̀ owó tuntun àti ìsọdituntun fún Ilé Ìṣọ́ àti Jí!, títí kan àsansílẹ̀ owó tiwọn fúnra wọn ránṣẹ́ nípasẹ̀ ìjọ.

◼ Kì í ṣe Society ni ó ń kọ ìwé ìbéèrè fún ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ti akéde kọ̀ọ̀kan. Kí alábòójútó olùṣalága ṣètò fún ìfilọ̀ lóṣooṣù kí a tó fi ìbéèrè olóṣooṣù fún ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ti ìjọ ránṣẹ́ sí Society kí gbogbo ẹni tí ó bá fẹ́ láti gba ìwé ti ara rẹ̀ lè sọ fún arákùnrin tí ń bójú tó ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ fi àwọn ìtẹ̀jáde tí ó jẹ́ ìbéèrè àkànṣe sọ́kàn.

◼ Àwọn àpéjọ àyíká àti àpéjọ àkànṣe tó tẹ̀ lé e yìí yóò ní ẹ̀ka ìjókòó tí a óò yà sọ́tọ̀ fún àwọn adití tí a óò sì fi èdè àwọn adití sọ ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà fún wọn: Akabo (EE-8): May 1, 2 àti September 18; Badagry (WE-14): June 19, 20 àti September 19; Dálùwọ́n (WE-3): February 6, 7 àti June 19; Iléṣà (WE-15): April 3, 4 àti August 8; Kàdúná (NE-1): April 3, 4 àti August 8; Ọ̀tà (WE-7): May 1, 2 àti September 5; Igwuruta Ali (EE-22): February 28 àti July 24, 25; Ùbogò (ME-7): May 15, 16 àti September 26.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́