Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Oṣù March
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní March 1
Orin 33
8 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Àwọn Ìfilọ̀ tí a yàn láti inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa.
17 min: “Ṣíṣèrántí Ikú Kristi Jákèjádò Ayé.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Fi àlàyé Ilé Ìṣọ́, February 1, 1997, ojú ìwé 11 àti 12, ìpínrọ̀ 10 sí 14 kún un. Tẹnu mọ́ bí ìfẹ́ títóbi lọ́lá tí Jèhófà ní ṣe sún un láti pèsè ìràpadà náà fún wa.
20 min: Àwọn Ìdí Tí Ń Múni Lọ́ranyàn Láti Ṣe Aṣáájú Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́ ní Oṣù April àti May. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn darí, ó rọ gbogbo àwùjọ láti ronú jinlẹ̀ gidigidi lórí ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Ṣàtúnyẹ̀wò ìyípadà nínú iye wákàtí táa ń béèrè lọ́wọ́ àwọn aṣáájú ọ̀nà déédéé àti aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, bó ṣe wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù January, ọdún 1999, ojú ìwé 3. Ó yẹ kí ìyípadà yìí mú kí ó ṣeé ṣe fún akéde púpọ̀ sí i láti gbádùn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Ṣàlàyé bí ìmọrírì táa ní fún ìrúbọ Kristi ṣe ń sọ ọ́ di ọ̀ranyàn fún wa láti lo ara wa tokunratokunra láti wàásù fún àwọn ẹlòmíràn. (2 Kọ́r. 5:14, 15) Lọ́dún yìí, Ìṣe Ìrántí bọ́ sí ọjọ́ àkọ́kọ́ nínú oṣù April. Ẹ wo ìsúnniṣe àtàtà tí èyí jẹ́ fún gbogbo akéde Ìjọba náà láti ya gbogbo oṣù náà sọ́tọ̀ fún ìgbòkègbodò tí a mú pọ̀ sí i! Ṣàtúnyẹ̀wò àwọn kókó pàtàkì tí o yàn láti inú àwọn àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti February 1997 àti March 1998, tó sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Jíròrò àwọn ọ̀nà tí a lè gbà lo àwọn ìṣètò tí a pèsè. Ṣàyẹ̀wò ìṣètò fún iṣẹ́ ìsìn ti ìjọ, tó pèsè ọ̀pọ̀ àǹfààní láti lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Fún àwọn akéde níṣìírí láti gba ìwé ìwọṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lẹ́yìn ìpàdé.
Orin 44 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní March 8
Orin 52
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò.
20 min: “Ké Sí Wọn Wá.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Tẹnu mọ́ bí ó ṣe yẹ pé kí a máa darí àwọn olùfìfẹ́hàn tuntun sí àwọn ìpàdé ìjọ nígbà gbogbo. Ṣàṣefihàn ìjíròrò kan pẹ̀lú olùfìfẹ́hàn kan, lo àkójọ ọ̀rọ̀ inú ìwé Ìmọ̀, ojú ìwé 159, ìpínrọ̀ 20, àti ojú ìwé 162 àti 163, ìpínrọ̀ 5 sí 8. Fún gbogbo àwùjọ níṣìírí láti sapá lákànṣe láti ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti àwọn olùfìfẹ́hàn mìíràn lọ́wọ́ láti wá síbi Ìṣe Ìrántí ní April 1. Fi ẹ̀dà ìwé ìkésíni kan hàn kí o sì ṣàlàyé bí a ṣe lè lò ó lọ́nà gbígbéṣẹ́. Gbogbo wa gbọ́dọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í pín ìwé ìkésíni síbi Ìṣe Ìrántí kiri lọ́sẹ̀ yìí.
15 min: “Bí Àwọn Mẹ́ńbà Ìdílé Ṣe Máa Ń Fọwọ́ Sowọ́ Pọ̀ Láti Nípìn-ín Kíkún—Nínú Àwọn Ìpàdé Ìjọ.” Ìjíròrò láàárín àwùjọ ìdílé kan. Bí wọ́n ṣe ń ṣàlàyé nípa àwọn kókó pàtàkì inú àpilẹ̀kọ náà, wọ́n jíròrò bí àwọn ṣe lè máa múra sílẹ̀ fún àwọn ìpàdé gẹ́gẹ́ bí ìdílé kan. Wọ́n jíròrò àwọn ọ̀nà tí àwọn lè gbà ran ara àwọn lọ́wọ́ lẹ́nì kìíní kejì láti kópa àti ohun tí àwọn gbọ́dọ̀ ṣe kí ìdílé àwọn lè tètè máa dé ìpàdé.
Orin 62 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní March 15
Orin 56
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn ìnáwó.
15 min: “Àwọn Ìránṣẹ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ń Ṣe Iṣẹ́ Ìsìn Oníyebíye.” Àsọyé tí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ dídáńgájíá sọ. Ṣàtúnyẹ̀wò àwọn kókó pàtàkì tí a kárí nínú ìwé Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-Ojiṣẹ Wa, ojú ìwé 57 sí 59. Ṣàlàyé bí a ṣe ń lo àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nínú ìjọ yín láti ran ìjọ lọ́wọ́.
20 min: Gbígbádùn Ìwé 1999 Yearbook. Ìjíròrò láàárín tọkọtaya. Ọkọ ṣàlàyé pé ọdún 1927 ni a kọ́kọ́ tẹ Yearbook jáde gẹ́gẹ́ bí ìwé àti pé fún èyí tó ju àádọ́rin ọdún lọ, ó ti ní ìròyìn nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé nínú. Wọ́n ṣàtúnyẹ̀wò àwọn kókó pàtàkì “1998 Grand Totals,” (Gbogbo Àròpọ̀ ti Ọdún 1998) ní ojú ìwé 31. Lẹ́yìn náà, wọ́n jíròrò “A Letter From the Governing Body,” (Lẹ́tà Tí Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso Kọ) ní ojú ìwé 3 sí 5, wọ́n sì ṣàlàyé bí àwọn yóò ṣe ṣiṣẹ́ lórí ìṣírí táa fún wọn.
Orin 68 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní March 22
Orin 162
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Kéde orúkọ àwọn tí yóò ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní oṣù April. Ṣàlàyé pé kò tíì pẹ́ jù láti fi ìwé ìwọṣẹ́ sílẹ̀. Sọ gbogbo ìṣètò àwọn ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn táa wéwèé fún oṣù April. Fún gbogbo àwùjọ níṣìírí láti tẹ̀ lé ìṣètò Bíbélì kíkà fún Ìṣe Ìrántí ní oṣù March 27 sí April 1, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣètò rẹ̀ nínú ìwé Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́ ti 1999 àti lórí 1999 Calendar.
15 min: Múra Sílẹ̀ fún Ìṣe Ìrántí. Àsọyé. Kí gbogbo akéde wéwèé láti ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti àwọn olùfìfẹ́hàn mìíràn lọ́wọ́ láti wá síbi Ìṣe Ìrántí. Àwọn ẹni tuntun tó bá wá lè máà lóye nípa ẹni tó lè jẹ àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ tàbí ìjẹ́pàtàkì ayẹyẹ yìí. Ṣàtúnyẹ̀wò ohun táa sọ nínú Ilé-Ìṣọ́nà, April 1, 1996, ojú ìwé 6 sí 8, kí o sì sọ bí a ṣe lè ran àwọn olùfìfẹ́hàn tuntun lọ́wọ́ láti lóye ìtumọ̀ àti ète ayẹyẹ yìí. Parí ọ̀rọ̀ rẹ nípa ṣíṣàyẹ̀wò “Àwọn Ìránnilétí Ìṣe Ìrántí,” kí o sì sọ àwọn ètò tí ìjọ ṣe fún Ìṣe Ìrántí.
20 min: Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú? Alàgbà bá akéde dídáńgájíá méjì tàbí mẹ́ta jíròrò ìníyelórí ìwé pẹlẹbẹ yìí àti bí a ṣe lè lò ó. A dojúlùmọ̀ ìwé pẹlẹbẹ yìí dáadáa nígbà táa kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ. Ṣé a ń lò ó lọ́nà gbígbéṣẹ́ nínú iṣẹ́ ìsìn pápá? Àwùjọ náà jíròrò ohun tó tẹ̀ lé e yìí: Kí ni ìdí tí ọ̀pọ̀ ènìyàn fi lọ́kàn-ìfẹ́ nínú kókó yìí? Láìdà bí àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn èké, ìrètí wo ni ìwé pẹlẹbẹ yìí tẹnu mọ́? Báwo la ṣe lè lo àwọn ìbéèrè tó wà lẹ́yìn rẹ̀ láti ru ọkàn-ìfẹ́ sókè? Àwọn ìgbà wo làǹfààní lè ṣí sílẹ̀ láti fi ìwé pẹlẹbẹ yìí lọni? Ṣàṣefihàn ìgbékalẹ̀ kan, kí o lo àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà ní ìpínrọ̀ 14, ní ojú ìwé 27. Fún gbogbo àwùjọ níṣìírí láti wà lójúfò láti lo ìwé pẹlẹbẹ yìí dáadáa.
Orin 92 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní March 29
Orin 111
12 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Rán gbogbo akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti oṣù March sílẹ̀. A óò fi àsansílẹ̀ owó Ilé Ìṣọ́ àti Jí! lọni ní oṣù April. Fi àwọn ìwé ìròyìn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde hàn, dábàá àwọn àpilẹ̀kọ tí a lè tẹnu mọ́, kí o sì mẹ́nu kan àwọn kókó díẹ̀ tí ń fani mọ́ra. Kí gbogbo akéde máa mú ìwé pẹlẹbẹ Béèrè dání kí wọ́n sì lò ó láti fi bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn tó bá fọkàn-ìfẹ́ hàn.
15 min: Àìní àdúgbò.
18 min: Báwo Ló Ṣe Yẹ Ká Dáhùn Padà sí Ìmọ̀ràn? Àsọyé tí alàgbà kan sọ. Gbogbo wa la lè fún nímọ̀ràn lórí ẹ̀mí èrò wa, ìwà wa, irú ẹgbẹ́ tí a ń kó, tàbí bí a ṣe ń lọ́wọ́ nínú ìgbòkègbodò ìjọ sí. Nígbà mìíràn, a máa ń ní ìtẹ̀sí láti kọ ìmọ̀ràn tàbí ká bínú. Mímúratán láti tẹ́wọ́ gba ìmọ̀ràn kí a sì fi í sílò ṣe kókó fún ìlera wa nípa tẹ̀mí. Ṣàtúnyẹ̀wò àwọn kókó pàtàkì tí ó tẹnu mọ́ àwọn ìdí tí ó fi yẹ ká tẹ́wọ́ gba ìmọ̀ràn, ká sì mọrírì rẹ̀.—Wo Jí!, March 22, 1990, ojú ìwé 14 sí 17.
Orin 118 àti àdúrà ìparí.