Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Oṣù May
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 3
Orin 7
8 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Àwọn Ìfilọ̀ tí a yàn láti inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Ìròyìn Ìṣàkóso Ọlọ́run.
17 min: “Kọ́ Àwọn Ẹlòmíràn Láti Ṣe Ara Wọn Láǹfààní.” Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì mú kí ìjíròrò lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn tẹ̀ lé e. Ní lílo orí kẹtàlá ìwé Ìmọ̀, ṣàkàwé bí àwọn ènìyàn ṣe ń jàǹfààní lọ́nà gbígbéṣẹ́ nípa kíkẹ́kọ̀ọ́, lílóye, àti fífi àwọn ìlànà Bíbélì sílò.
20 min: “Àwọn Ọ̀nà Tí O Lè Gbà Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Gbòòrò Sí I.” Àwọn alàgbà méjì jíròrò àpilẹ̀kọ yìí láti fi dáhùn àwọn ìbéèrè tí àwọn tí ń kópa nínú ìjíròrò náà ń béèrè. Akéde kan tó jẹ́ ọ̀dọ́langba, tọkọtaya kan, àti arákùnrin kan tí ọjọ́ orí rẹ̀ tó ti ẹni tó ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ béèrè àwọn ọ̀nà tí àwọn lè gbà mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ àwọn gbòòrò sí i. Àwọn alàgbà náà pèsè àbá gbígbéṣẹ́ fún wọn láti inú àpilẹ̀kọ yìí àti láti inú orí 9 ìwé Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-Ojiṣẹ Wa, wọ́n pe àfiyèsí sí ìsọ̀rí náà, “Kinni Awọn Gongo-Ilepa Rẹ Tẹmi fun Ọjọ-Ọla?,” ojú ìwé 116 sí 118. Àwọn akéde náà dúpẹ́ fún ìsọfúnni tí ń ṣèrànwọ́ tí Society pèsè tó fi hàn bí a ṣe lè wéwèé fún ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìsìn tí a mú gbòòrò sí i ní ọjọ́ iwájú tí kò jìnnà.
Orin 11 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 10
Orin 15
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò.
15 min: “Olè Jíjà Ha Ni Nítòótọ́ Bí?” Àsọyé tí a gbé karí Ilé-Ìṣọ́nà, April 15, 1994, ojú ìwé 19 sí 21. Tẹnu mọ́ àwọn ọ̀rọ̀ mìíràn tí ìwé atúmọ̀ èdè Webster’s New Dictionary of Synonyms lò fún mímú nǹkan ìní ẹlòmíràn láìjẹ́ kó mọ̀ tàbí láìsọ pé ká mú un. Mẹ́nu kàn án pé ‘mímú nǹkan ìní ẹlòmíràn láìjẹ́ pé ó mọ̀ tàbí láìsọ pé ká mú un’ jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ ìyọlẹ́gbẹ́.
20 min: “Àpéjọpọ̀ Àgbègbè ‘Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run’ ti . . . 1999.” (Ìpínrọ̀ 1 sí 11) Kí akọ̀wé bójú tó o. Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ka ìpínrọ̀ 4, 5, àti 7. Tẹnu mọ́ àwọn ìdí tó fi yẹ ká pésẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ àpéjọpọ̀ náà, títí kan ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ Friday. Tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì títẹ̀lé ìtọ́sọ́nà Society nípa ọ̀ràn ilé ibùwọ̀. Gbóríyìn fáwọn ara fún fífọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ìṣètò Society.
Orin 19 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ni May 17
Orin 27
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn ìnáwó.
15 min: “Wéwèé Ṣáájú!” Àsọyé tí a fi ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ìgbòkègbodò ìṣàkóso Ọlọ́run tí a wéwèé nínú ìjọ fún àwọn oṣù mélòó kan tí yóò tẹ̀ lé e. Fún gbogbo ìjọ níṣìírí láti sàmì sí àwọn ọjọ́ náà lórí kàlẹ́ńdà wọn kí wọ́n má sì ṣe jẹ́ kí ohunkóhun ṣèdíwọ́.
20 min: “Àpéjọpọ̀ Àgbègbè ‘Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run’ ti . . . 1999.” (Ìpínrọ̀ 12 sí 19) Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ka ìpínrọ̀ 16 sí 18. Lo àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a ṣàyọlò àti èyí tí a tọ́ka sí láti tẹnu mọ́ ìdí tí ìmúra, ìwọṣọ, àti ìwà híhù fi jẹ́ àwọn ọ̀ràn tí ń fẹ́ àfiyèsí wa gidigidi.
Orin 29 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 24
Orin 41
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ṣèfilọ̀ ètò iṣẹ́ ìsìn pápá ní òpin ọ̀sẹ̀.
15 min: Àpótí Ìbéèrè. Àsọyé tí alàgbà kan sọ.
20 min: Ǹjẹ́ A Ń Nípìn-ín Nínú Iṣẹ́ Ìyàsọ́tọ̀ Kan? Àsọyé tí ń tani jí tí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn sọ, tí a gbé karí Ilé Ìṣọ́, July 1, 1997, ojú ìwé 30 àti 31.
Orin 32 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 31
Orin 43
15 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Rán gbogbo akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti oṣù May sílẹ̀. Ṣàtúnyẹ̀wò ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni ní oṣù June. Ṣàṣefihàn ìgbékalẹ̀ kan bí àwòkọ́ṣe.
15 min: Àìní àdúgbò.
15 min: Kí Ló Lòdì Nínú Ìsìn Mi? Ìjíròrò láàárín ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ méjì. A máa ń bá ọ̀pọ̀ èèyàn pàdé tí wọ́n fẹ́ràn òtítọ́, tí wọ́n sì máa ń kan sáárá sí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ṣùgbọ́n, àjọṣe tí wọ́n ní pẹ̀lú ṣọ́ọ̀ṣì wọn ń ṣèdíwọ́ fún wọn. Ó ṣòro fún wọn láti gbà gbọ́ pé àwa ló ní ìsìn tòótọ́ kan ṣoṣo àti pé èké ni ìjọsìn tí wọ́n ń ṣe. Èyí máa ń jẹ́ ìdíwọ́ pàtàkì fún ìtẹ̀síwájú wọn nípa tẹ̀mí. Àwọn arákùnrin náà ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ìdí abájọ mẹ́fà tí a mẹ́nu kàn lójú ìwé 204 nínú ìwé Reasoning, tó fi hàn kedere pé àwọn ìsìn yòókù kò tẹ̀ lé Bíbélì. Wọ́n fún àwùjọ níṣìírí láti lo àwọn kókó wọ̀nyí láti fọgbọ́n ran àwọn olótìítọ́-ọkàn lọ́wọ́ láti ṣàyẹ̀wò ohun tí ìsìn wọn gbà gbọ́.
Orin 50 àti àdúrà ìparí.