Àwọn Ìfilọ̀
◼ Àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni ní oṣù June àti July: Fífi àdìpọ̀ ìwé tí a béèrè fún lọ́dọ̀ Society lọni lọ́nà àkànṣe, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàlàyé nínú lẹ́tà wa ti March 1, 1999. Àdìpọ̀ ìwé mẹ́rin fún ₦60. August: A lè lo èyíkéyìí nínú àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 tó tẹ̀ lé e yìí: Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá, Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae!, Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?, Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?, Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, àti Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi? Àwọn ìwé pẹlẹbẹ Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran Ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha Wa Niti Gidi Bi?, Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn, Our Problems—Who Will Help Us Solve Them?, àti Will There Ever Be a World Without War? ni a lè fi lọni nígbà tó bá yẹ. September: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun.
◼ Kí alábòójútó olùṣalága tàbí ẹnì kan tí òun yàn ṣàyẹ̀wò àkáǹtì ìjọ ní June 1 tàbí bí ó bá ti lè ṣeé ṣe kí ó yá tó lẹ́yìn ìgbà yẹn. Bí ẹ bá ti ṣe èyí, ẹ ṣe ìfilọ̀ fún ìjọ lẹ́yìn tí ẹ bá ti ka ìròyìn ìnáwó tí ó tẹ̀ lé e.