Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ó fi lọni ní oṣù November: Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? tàbí Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. December: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun pẹ̀lú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. January: Ìwé olójú ewé 192 èyíkéyìí tí ìjọ bá ní tí a ti tẹ̀ jáde ṣáájú ọdún 1986. Àwọn ìjọ tí kò bá ní irú àwọn ìwé bẹ́ẹ̀ lè fi ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye lọni. February: Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé.