ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 1/00 ojú ìwé 1
  • Mímú Kí Gbogbo Ilẹ̀ Ayé Mọ̀ Nípa Orúkọ Jèhófà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Mímú Kí Gbogbo Ilẹ̀ Ayé Mọ̀ Nípa Orúkọ Jèhófà
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ọ̀nà Tá À Ń Gbà Wàásù Ìhìn Rere
    A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
  • Àwọn Ọ̀nà Tá A Gbà Ń Wàásù—Gbogbo Ọ̀nà La Fi Ń Mú Ìhìn Rere Dé Ọ̀dọ̀ Àwọn Èèyàn
    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
  • Kí Nìdí Tí Iṣẹ́ Ìwàásù Ilé-dé-Ilé Fi Ṣe Pàtàkì Nísinsìnyí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Wàásù Ìhìn Rere Náà Níbi Gbogbo
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
km 1/00 ojú ìwé 1

Mímú Kí Gbogbo Ilẹ̀ Ayé Mọ̀ Nípa Orúkọ Jèhófà

1 Nígbà tí Jésù pínṣẹ́ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti jẹ́ ẹlẹ́rìí “títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé,” ó ti fi àpẹẹrẹ tí wọ́n á tẹ̀ lé lélẹ̀ fún wọn. (Ìṣe 1:8) Nígbàkigbà àti níbikíbi tí ó bá ti rí àwọn èèyàn, ó ń bá wọn sọ̀rọ̀ nípa ohun tó jẹ́ ète Ọlọ́run fún aráyé. Ní àfarawé Jésù, ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ náà ń lo ọ̀kan-ò-jọ̀kan ọ̀nà láti ‘sọ orúkọ Jèhófà di mímọ̀ ní gbogbo ilẹ̀ ayé.’—Aísá. 12:4, 5.

2 Ohun Táa Ṣe Láyé Ọjọ́un: Látijọ́, a máa ń tẹ ìwàásù jáde nínú àwọn ìwé ìròyìn; a ṣe fíìmù “Photo-Drama of Creation,” ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn ló sì wò ó; a lo àwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ onígbohùngbohùn; a tún lo ẹ̀rọ giramafóònù nílélóko, àwọn àkókò kan sì wà tí a lo rédíò lọ́nà kan náà—ká lè wàásù ìhìn rere náà la ṣe lo gbogbo wọn. Àmọ́ ṣá o, a ti máa ń fìgbà gbogbo tẹnu mọ́ ọn pé, ó yẹ kí àwa fúnra wa lọ bá àwọn èèyàn kí a lè mú kí ìfẹ́ tí wọ́n fi hàn pọ̀ sí i. Nítorí èyí, iṣẹ́ òjíṣẹ́ ilé dé ilé ti jẹ́ ọ̀nà kan tó gbéṣẹ́ gidigidi láti mú kí àwọn èèyàn níbi gbogbo mọ̀ nípa orúkọ Jèhófà.—Ìṣe 5:42.

3 Ohun Tí A Ń Ṣe Lóde Òní: Bí ìgbà ṣe ń yí padà, bẹ́ẹ̀ ni kòókòó jàn-án jàn-án ń pọ̀ sí i láyé, a ò sì sábà máa ń bá àwọn èèyàn nílé níbi púpọ̀. Díẹ̀ làwọn tó máa ń fẹ́ láti fi àkókò wọn kàwé kí wọ́n sì ṣàṣàrò nípa àwọn nǹkan tẹ̀mí. Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wá máa bá ipò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ mu. Láfikún sí kíkárí ìpínlẹ̀ wa láti ilé dé ilé, a fún wa níṣìírí láti máa lọ sí ibi tí àwọn èèyàn wà, kí a sì máa “wà ní ìmúratán nígbà gbogbo” láti gbèjà ìrètí tó wà nínú wa. (1 Pét. 3:15) Èyí túmọ̀ sí pé a ní láti máa sapá láti wàásù fún àwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wa, ọmọ ilé ìwé ẹlẹgbẹ́ wa, àwọn èèyàn tó wà lópòópónà àti ní ọgbà ìtura tàbí ní ibi ìgbọ́kọ̀sí, láti ilé ìtajà dé ilé ìtajà, àti láwọn ibòmíràn tí a ti lè rí àwọn èèyàn. Nítorí pé Jèhófà ń tì wá lẹ́yìn, àwọn ìsapá wa máa ń yọrí sí rere. Ǹjẹ́ ìwọ náà máa ń dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn níbikíbi tí wọ́n bá wà?

4 Kí gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan máa ṣe gbogbo ohun tí a bá lè ṣe bó bá dọ̀ràn mímú kí àwọn èèyàn mọ̀ nípa orúkọ Jèhófà ní ìpínlẹ̀ wa. A lè rí ìtẹ́lọ́rùn ńlá nínú ṣíṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa láṣepé, bí a ti ń retí pé kí Jèhófà fa àwọn tó ní ọkàn rere wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀.—Jòh. 6:44.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́