Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run
Àtúnyẹ̀wò láìṣí ìwé wò fún àkópọ̀ ẹ̀kọ́ tí a kárí nínú àwọn iṣẹ́ Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run fún àwọn ọ̀sẹ̀ January 3 sí April 17, 2000. Lo abala tákàdá ọ̀tọ̀ láti fi kọ ìdáhùn sí púpọ̀ nínú àwọn ìbéèrè náà, bí ó bá ti lè ṣeé ṣe fún ọ tó, ní ìwọ̀n àkókò tí a yàn.
[Àkíyèsí: Lákòókò àtúnyẹ̀wò alákọsílẹ̀, Bíbélì nìkan ni a lè lò láti dáhùn ìbéèrè èyíkéyìí. Àwọn ìtọ́kasí tí ó tẹ̀ lé àwọn ìbéèrè wà fún ìwádìí fúnra rẹ. Nọ́ńbà ojú ìwé àti ìpínrọ̀ lè má fara hàn nínú gbogbo àwọn ìtọ́ka tí a ṣe sí Ilé Ìṣọ́.]
Dáhùn Òtítọ́ tàbí Èké sí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn gbólóhùn tó tẹ̀ lé e yìí:
1. Nígbà mìíràn, a ní láti dúró di àkókò yíyẹ láti gba ìbùkún Jèhófà, nítorí pé Jèhófà mọ ipò wa, ó sì ń bójú tó àìní kọ̀ọ̀kan nígbà tí yóò ṣe wá láǹfààní jù lọ. (Sm. 145:16; Ják. 1:17) [w98-YR 1/1 ojú ìwé 23 ìpínrọ̀ 5]
2. Bí àpótí májẹ̀mú bá tilẹ̀ wà pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ìyẹn nìkan ò sọ pé kí wọ́n ṣàṣeyọrí. Àwọn tó ní àpótí náà lọ́dọ̀ gbọ́dọ̀ dúró dáadáa nípa tẹ̀mí kí wọ́n sì máa ṣègbọràn tìṣòtítọ́tìṣòtítọ́ kí wọ́n tó lè rí ìbùkún Jèhófà gbà. (Jóṣ., orí keje) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo it-1-E ojú ìwé 167 ìpínrọ̀ 2.]
3. Lónìí, wíwulẹ̀ ka àwọn àsọjáde Jèhófà ló ń fún wa lókun nípa tẹ̀mí. (Diu. 8:3) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w85-YR 12/15 ojú ìwé 17 ìpínrọ̀ 15, 17.]
4. Ìlànà tí a mẹ́nu bà nínú Òfin Mósè ní Diutarónómì 23:20 fi hàn pé ìwà àìnífẹ̀ẹ́ láá mú kí Kristẹni kan gba èlé nígbà tó bá ń yáni lówó. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo it-1-E ojú ìwé 1212 ìpínrọ̀ 5 àti 6; it-2-E ojú ìwé 259 ìpínrọ̀ 12; w86-YR 10/15 ojú ìwé 12 ìpínrọ̀ 9.]
5. Ìròyìn rere tí Jóṣúà àti Kálébù mú wá jẹ́ nítorí pé wọ́n ní ìdánilójú gidigidi nínú agbára àti ìmúratán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti borí ohun ìdènà èyíkéyìí tó lè fẹ́ dí wọn lọ́wọ́ gbígba Ilẹ̀ Ìlérí. (Núm. 13:30) [w98-YR 2/1 ojú ìwé 5 ìpínrọ̀ 4]
6. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa “ẹ̀bùn” nínú Tímótì Kìíní, ṣe ló ń rán Tímótì létí nípa ẹ̀mí mímọ́ tí a fi yàn án, àti èrè ti ọ̀run tó ń dúró dè é. (1 Tím. 4:14) [w98-YR 2/15 ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 1]
7. Ráhábù múra tán láti kọ ẹ̀yìn sáwọn èèyàn rẹ̀, kó sì fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wewu láti lè rí ìfẹ́ inú rere Jèhófà gbà. [w84-YR 11/15 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 1]
8. Ìwé Àwọn Onídàájọ́ jẹ́ àkọsílẹ̀ nípa àwọn ọkùnrin méjìlá tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ títayọ. [w85-YR 1/1 ojú ìwé 20 ìpínrọ̀ 1, 2]
9. Ohun tí Gídéónì béèrè, bí a ṣe ṣàpèjúwe rẹ̀ nínú Àwọn Onídàájọ́ 6:37-39, fi hàn pé ó ti ṣọ́ra jù, ó sì ti fura jù. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w88-YR 4/1 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 6.]
10. Nípa fífún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nítọ̀ọ́ni pé ‘kí wọ́n má ṣe gbá ẹnikẹ́ni mọ́ra bí wọ́n bá ń kí wọn lójú ọ̀nà,’ ṣe ni Jésù ń tẹnu mọ́ ọn pé iṣẹ́ ìwàásù náà jẹ́ kánjúkánjú àti pé ó yẹ kí wọ́n fún iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ yìí ní àfiyèsí kíkún. (Lúùkù 10:4) [w98-YR 3/1 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 5]
Dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e yìí:
11. Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì pé kí ọ̀rọ̀ Jèhófà wà lọ́kàn àwọn òbí? (Diu. 6:5, 6) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w98-YR 6/1 ojú ìwé 20 ìpínrọ̀ 4.]
12. Báwo ni olórí ìdílé kan ṣe lè fi ìlànà tó wà nínú Diutarónómì 11:18, 19 sílò? [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo fy-YR ojú ìwé 70 ìpínrọ̀ 14.]
13. Báwo ni Ìwé Mímọ́ ṣe fi hàn pé Ónẹ́símù, ìsáǹsá ẹrú náà, ti wà pẹ̀lú àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún àkókò díẹ̀ kí Pọ́ọ̀lù tó kọ̀wé sí Fílémónì? [w98-YR 1/15 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 3]
14. Nígbà tí a bá rí àwọn èèyàn tí wọn ò ṣèdájọ́ òdodo, tàbí tó jẹ́ pé àwa gan-an ni wọ́n hu irú ìwà bẹ́ẹ̀ sí, kí la lè ṣe kí a máa bàa rẹ̀wẹ̀sì tàbí ṣiyè méjì? [w98-YR 2/1 ojú ìwé 6 ìpínrọ̀ 2, 3]
15. Báwo ni Jóṣúà ṣe bọ̀wọ̀ fún òfin Ọlọ́run gidigidi? (Diu. 20:8, 15-18) [w84-YR 8/15 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 7]
16. Báwo ni àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a ṣàpèjúwe nínú Jóṣúà 10:10-14 ṣe jọ ohun tí a lè retí ní Amágẹ́dọ́nì? [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w86-YR 12/15 ojú ìwé 23 ìpínrọ̀ 12 sí ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 14.]
17. Mẹ́nu kan àwọn àǹfààní mẹ́ta tí ń bẹ nínú yíyin ẹnì kan látọkànwá nítorí ìwà yíyẹ tí ẹni náà hù. (Fi wé Òwe 15:23.) [w98-YR 2/1 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 5, 6]
18. Ní ìbámu pẹ̀lú Jóṣúà 20:4, báwo lèèyàn ṣe ń sá lọ sí ìlú ìsádi amápẹẹrẹṣẹ? [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w86-YR 12/15 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 16.]
19. Báwo ni ìwé Àwọn Onídàájọ́ 5:31 ṣe fi hàn pé ṣíṣẹ́gun tí Bárákì Onídàájọ́ ṣẹ́gun agbo ọmọ ogun Sísérà tí wọ́n pọ̀ ju tirẹ̀ lọ, ní àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Kíṣónì, ní ìtumọ̀ pàtàkì fún ọjọ́ wa? [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w86-YR 6/15 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 4.]
20. Báwo la ṣe lè bọ̀wọ̀ fún ìlànà tí ń bẹ lẹ́yìn gbólóhùn náà pé, “wọ́n dúró, olúkúlùkù ní àyè rẹ̀,” bó ṣe wà nínú ìwé Àwọn Onídàájọ́ 7:21? [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w82-YR 12/1 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 17.]
Pèsè ọ̀rọ̀ tàbí gbólóhùn tó yẹ kó wà ní àlàfo inú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn gbólóhùn tó tẹ̀ lé e yìí:
21. Láti lè jèrè ìbùkún Jèhófà ní kíkún sí i, a gbọ́dọ̀ máa bá a lọ láti __________________________, ká sì máa rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà láti ràn wá lọ́wọ́ láti __________________________ àwọn ẹ̀kọ́ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó mí sí, __________________________. (1 Tím. 4:8, 9) [w98-YR 1/1 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 6]
22. Ìpọ́nni àbòsí kò dùn mọ́ Jèhófà rárá nítorí pé __________________________ ló ń súnni ṣe é, __________________________ ni, kò sì fi __________________________ hàn, jù gbogbo rẹ̀ lọ, kò fi __________________________ hàn. [w98-YR 2/1 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 2, 3]
23. Orúkọ náà, __________________________, jẹ́ ọ̀nà kan tí Gíríìkì ń gbà pe orúkọ èdè Hébérù náà, __________________________. [w84-YR 11/15 ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 1]
24. Ní ìbámu pẹ̀lú àkàwé Jésù nínú Mátíù 7:24-27, àwọn òbí tó lóye lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti kojú pákáǹleke tó dà bí ìjì nípa fífún wọn ní __________________________ tí yóò ran àwọn ọmọ náà lọ́wọ́ láti __________________________. [w98-YR 2/15 ojú ìwé 9 ìpínrọ̀ 1]
25. __________________________ ni onídàájọ́ àkọ́kọ́ tí a mẹ́nu kàn nínú ìwé Àwọn Onídàájọ́. [w85-YR 1/1 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 1]
Mú ìdáhùn tó tọ̀nà nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn gbólóhùn tó tẹ̀ lé e yìí:
26. Gbígbégbèésẹ̀ nípa bí a óò ṣe pín ohun ìní ẹni bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé a ku jẹ́ (ọ̀ràn ìjọ; ọ̀ràn ara ẹni; ohun tí a béèrè lọ́wọ́ àwọn Kristẹni tòótọ́). (Gál. 6:5) [w98-YR 1/15 ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 6]
27. Pọ́ọ̀lù rọ Fílémónì láti fi inú rere gba (Ónámù; Ónẹ́sífórù; Ónẹ́símù), ṣùgbọ́n kò lo àṣẹ tó ní gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì láti pàṣẹ fún un pé kó ṣe bẹ́ẹ̀ tàbí láti tú ẹrú rẹ̀ sílẹ̀. (Fílém. 21) [w98-YR 1/15 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 1]
28. Àlèébù ńlá kan tí àwọn adẹ́tẹ̀ tí a ròyìn pé Jésù mú lára dá ní ni (àìnígbàgbọ́; àìgbọràn; àìmoore). (Lúùkù 17:11-19) [w98-YR 2/15 ojú ìwé 5 ìpínrọ̀ 1]
29. Níwọ̀n bí Ọlọ́run ti tẹ́wọ́ gba ìgbésẹ̀ Ráhábù, ọ̀rọ̀ tó sọ fún àwọn ọkùnrin Jẹ́ríkò tí ń lépa àwọn amí tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì fi hàn pé (bóyá ká parọ́ tàbí ká má parọ́ jẹ́ ọ̀ràn ara ẹni; kò di dandangbọ̀n fún ẹnì kan láti túdìí àṣírí ìsọfúnni òtítọ́ fún àwọn ènìyàn tí wọn kò lẹ́tọ̀ọ́ sí i; kò tíì yí gbogbo ọ̀nà ayé tó ń tọ̀ padà). (Jóṣ. 2:3-5; fi wé Róòmù 14:4.) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w93-YR 12/15 ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 1.]
30. Bí a ṣe ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ ní Jòhánù 13:5, ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n tí Jésù pèsè fi ànímọ́ (inú rere; ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò; ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀) hàn, tó máa ń jẹ́ kí èèyàn fẹ́ láti ṣe iṣẹ́ tó rẹlẹ̀ jù lọ nítorí àwọn ẹlòmíràn. [w98-YR 3/15 ojú ìwé 8 ìpínrọ̀ 1]
So àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó tẹ̀ lé e yìí mọ́ èyí tó bá a mu lára àwọn gbólóhùn tí a tò lẹ́sẹẹsẹ sí ìsàlẹ̀ yìí:
Diu. 7:3, 4; 17:7; 25:11, 12; 28:3; Jer. 15:20
31. Níwọ̀n bí Ẹlẹ́dàá ti ní ọ̀wọ̀ gidigidi fún ẹ̀yà ìbímọ, ó yẹ kí ìyẹn ní ipa lórí ìpinnu tí Kristẹni kan bá ṣe nípa ọ̀nà tó yẹ láti gbà fètò sọ́mọ bíbí. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w99-YR 6/15 ojú ìwé 28 ìpínrọ̀ 3 sí 6.]
32. A lè ní ìgbọ́kànlé pé Jèhófà yóò tì wá lẹ́yìn bí a ṣe ń ṣe iṣẹ́ tó gbé lé wa lọ́wọ́ láti wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. [w98-YR 3/1 ojú ìwé 28 ìpínrọ̀ 1]
33. Kíkọbiara sí ìkìlọ̀ Bíbélì ń yọ wá nínú àwọn ìrora tó sábà máa ń jẹ yọ nígbà tí Kristẹni kan bá fẹ́ aláìgbàgbọ́. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w89-YR 11/1 ojú ìwé 20 ìpínrọ̀ 11.]
34. Gbígbádùn àwọn ìbùkún Ọlọ́run kò sinmi lórí ibi tí a ń gbé tàbí ibi tí a ti ń sìn tàbí ohun tí a ń ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w96-YR 6/15 ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 15.]
35. Pọ́ọ̀lù ṣàyọlò Òfin Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọlá àṣẹ fún ìtọ́ni tó fúnni nínú Kọ́ríńtì Kìíní orí Karùn-ún. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo si-E ojú ìwé 213 ìpínrọ̀ 24.]