-
Rahabu—A Polongo Rẹ̀ ní Olódodo Nípa Àwọn Iṣẹ́ Ìgbàgbọ́Ilé-Ìṣọ́nà—1993 | December 15
-
-
àwọn ọ̀nà rẹ̀ padà. Ọ̀rọ̀ Ọlọrun pé Israeli yóò pa àwọn ará Kenaani run nítorí àwọn ìwàpálapàla wọn, àti ìbùkún rẹ̀ lórí Rahabu àti lórí ìṣẹ́gun Jeriko, mú kí ó dánilójú pé àwọn amí náà kò hùwà pálapàla.—Lefitiku 18:24-30.
Àwọn ọ̀rọ̀ aṣinilọ́nà Rahabu sí àwọn olùlépa àwọn amí náà ńkọ́? Ọlọrun fọwọ́sí ipa-ọ̀nà rẹ̀. (Fiwé Romu 14:4.) Ó fi ẹ̀mí rẹ̀ wewu kí ó baà lè dáàbòbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ní fífi ẹ̀rí ìgbàgbọ́ rẹ̀ hàn. Bí ó ti jẹ́ pé irọ́ pípa aláràn-án-kan kò tọ́ ni ojú Jehofa, kò di dandangbọ̀n fún ẹnìkan láti túdìí àṣírí ìsọfúnni òtítọ́ fún àwọn ènìyàn tí wọn kò lẹ́tọ̀ọ́ sí i. Jesu Kristi pàápàá kò sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ tàbí ìdáhùn tààràtà nígbà tí ṣíṣe bẹ́ẹ̀ lè ti fa ìpalára tí kò yẹ. (Matteu 7:6; 15:1-6; 21:23-27; Johannu 7:3-10) Dájúdájú, ipa-ọ̀nà Rahabu ti ṣíṣi àwọn ọ̀tá oníṣẹ́ náà lọ́nà ni a gbọ́dọ̀ fi ojú yẹn wò.
Èrè-Ẹ̀san Rahabu
Báwo ni a ṣe san èrè-ẹ̀san fún Rahabu fún fífi ìgbàgbọ́ hàn? Dájúdájú, pípa a mọ́ nígbà ìparun Jeriko jẹ́ ìbùkún kan láti ọ̀dọ̀ Jehofa. Lẹ́yìn náà, ó fẹ́ Salmoni (Salma), ọmọkùnrin olórí aginjù náà Naṣoni ti ẹ̀yà Juda. Gẹ́gẹ́ bí òbí Boasi oníwà-bí-Ọlọ́run naa, Salmoni àti Rahabu ní ìsopọ̀ kan nínú ìlà ìdílé tí ó ṣamọ̀nà sí Ọba Dafidi ti Israeli. (1 Kronika 2:3-15; Rutu 4:20-22) Ní pàtàkì jùlọ, aṣẹ́wó tẹ́lẹ̀rí náà Rahabu jẹ́ ọ̀kan péré lára àwọn obìnrin mẹ́rin tí a dárúkọ nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ Matteu nípa ìlà-ìdílé Jesu Kristi. (Matteu 1:5, 6) Ẹ wo irú ìbùkún tí èyí jẹ́ láti ọ̀dọ̀ Jehofa!
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kìí ṣe ọmọ Israeli tí ó sì jẹ́ aṣẹ́wó kan tẹ́lẹ̀rí, Rahabu jẹ́ àpẹẹrẹ títayọ ti obìnrin kan tí ó fihàn nípa iṣẹ́ rẹ̀ pé òun ní ìgbàgbọ́ kíkún nínú Jehofa. (Heberu 11:30, 31) Bíi ti àwọn mìíràn, díẹ̀ lára àwọn tí wọn ti kọ ìgbésí-ayé ti ṣíṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó sílẹ̀, òun yóò gba èrè-ẹ̀san mìíràn síbẹ̀—àjínde kúrò nínú ikú sí ìwàláàyè lórí paradise ilẹ̀-ayé. (Luku 23:43) Nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀ ti ó fi iṣẹ́ tì lẹ́yìn, Rahabu jèrè ìtẹ́wọ́gbà Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́, olùdáríjini. (Orin Dafidi 130:3, 4) Dájúdájú, àpẹẹrẹ rere rẹ̀ pèsè ìṣírí rere fún gbogbo àwọn olùfẹ́ òdodo láti gbójúlé Jehofa Ọlọrun fún ìyè àìnípẹ̀kun.
-
-
Jíjẹ́ kí Ojú Wa “Mú Ọ̀nà Kan” nínú Iṣẹ́ ÌjọbaIlé-Ìṣọ́nà—1993 | December 15
-
-
Jíjẹ́ kí Ojú Wa “Mú Ọ̀nà Kan” nínú Iṣẹ́ Ìjọba
ÌLÚ Aláààrẹ Oníjọba Dẹmọ ti Germany (G.D.R.), tàbí ohun tí a mọ̀ sí East Germany tẹ́lẹ̀, ti fẹ́rẹ̀ẹ́ wọ agbedeméjì sànmánì. Ọdún 41 tí ó ti wà parí ní oṣù October 3, 1990, nígbà tí agbègbè-ìpínlẹ̀ rẹ̀, tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó Liberia tàbí ìpínlẹ̀ Tennessee ní United States, di èyí tí a jápọ̀ mọ́ Ìlú Aláààrẹ ti Ìjọba Àpapọ̀ Germany, èyí tí a ti ń pè ní West Germany.
Ìtúnmúṣọ̀kan àwọn ilú Germany méjèèjì náà ti túmọ̀sí ọ̀pọ̀ iye àwọn àtúnṣe. Ààlà-ilẹ̀ kan tí ó jẹ́ tí àwọn àbá-èrò-orí ni ó ti ya àwọn orílẹ̀-èdè méjèèjì náà sọ́tọ̀, kìí wulẹ̀ ṣe ààlà-ẹnubodè gidi kan lásán. Kí ni gbogbo èyí túmọ̀sí fún àwọn ènìyàn tí wọ́n wà níbẹ̀, báwo sì ni ìgbésí-ayé ṣe yípadà fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa?
Wende, ìyípadà tegbòtigàgá náà tí ó wáyé
-