Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 10
Orin 122
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Àwọn Ìfilọ̀ táa mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Ẹ má ṣe gbàgbé àkànṣe àsọyé ní April 16, tí a pe àkòrí rẹ̀ ní “Ìdí Tí Aráyé Fi Nílò Ìràpadà.” Fún gbogbo ará níṣìírí pé kí wọ́n ka Bíbélì kíkà fún Ìṣe Ìrántí tí a ṣètò láti April 14 sí 19, bó ṣe wà nínú Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2000. Ṣàyẹ̀wò “Àwọn Ohun Tí Kò Yẹ Ká Gbàgbé Nípa Ìṣe Ìrántí,” lójú ìwé 4 nínú àkìbọnú.
15 min: “Ǹjẹ́ O Ń Fìmọrírì Hàn fún Ìfẹ́ Kristi?” Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Fi àlàyé kún un láti inú Ilé Ìṣọ́ May 1, 1998, ojú ìwé 16 àti 17, ìpínrọ̀ 12 àti 13. Fún gbogbo ìjọ níṣìírí pé kí wọ́n sapá lákànṣe láti ké sí àwọn èèyàn wá sí Ìṣe Ìrántí.
20 min: “Oṣù April Jẹ́ Àkókò Láti Jẹ́ Onítara fún Iṣẹ́ Àtàtà!” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Kí á fi ìtara jíròrò ohun táa fẹ́ ṣe ní April.
Orin 199 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 17
Orin 25
13 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn ìnáwó. Òpin ọ̀sẹ̀ méjì péré ló kù nínú oṣù April, nítorí náà, fún gbogbo akéde níṣìírí pé kí wọ́n kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ kóṣù tó parí. Jẹ́ kí a lo àwọn ìtẹ̀jáde lọ́ọ́lọ́ọ́ láti fi ṣàṣefihàn bí a ṣe lè fi ìwé ìròyìn lọni ní ṣókí. Níwọ̀n bí ó ti lè di dandan pé ká dá àwọn èèyàn tí wọ́n fẹ́ ká kópa nínú àwọn àṣà ọdún Àjíǹde wọn lóhùn, ṣàyẹ̀wò ohun tó wà nínú ìwé Reasoning, ojú ìwé 179 àti 180.
16 min: “Ǹjẹ́ O Lẹ́mìí Ìfara-Ẹni-Rúbọ?” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ó yẹ ká gbé àwọn ohun àkọ́múṣe kalẹ̀, ká fohun tó yẹ kó ṣáájú sí ipò iwájú. Ó ń béèrè ìdánúṣe àti ìkóra-ẹni-níjàánu ká tó lè máa bá a nìṣó láti ṣe ohun tí yóò ṣe wá láǹfààní nípa tẹ̀mí. Ṣàlàyé ohun tí a lè rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Jésù.—Wo Insight, Apá 2, ojú ìwé 68, ìpínrọ̀ 3 sí 5.
16 min: Fi Àwọn Ìwé Ìròyìn Sóde Níbi Tí Wọ́n Á Ti Gbéṣẹ́ Jù Lọ. Àsọyé tí àwùjọ lóhùn sí. Ṣàyẹ̀wò àwọn ìdámọ̀ràn inú Jí! ti January 8, 1995, ojú ìwé 22 sí 24. Ṣàlàyé ìdí tó fi dáa pé ká wá àwọn èèyàn tó ṣeé ṣe kí wọ́n fẹ́ràn àwọn àpilẹ̀kọ inú ìwé ìròyìn wa tó sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ kan ní pàtó. Ṣàyẹ̀wò àwọn àpẹẹrẹ látinú àwọn ìtẹ̀jáde tó ti kọjá àti irú àwọn èèyàn, àwọn oníṣòwò, tàbí àjọ tí àwọn àpilẹ̀kọ náà ti gbọ́dọ̀ fà mọ́ra ní ìpínlẹ̀ ìjọ yín. Sọ pé kí àwùjọ sọ àwọn ìrírí nípa bí wọ́n ṣe ṣàṣeyọrí nígbà tí wọ́n lo ọ̀nà yìí.
Orin 71 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 24
Orin 137
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Sọ iye àwọn tó wá sí Ìṣe Ìrántí ní ìjọ yín. Sọ pé kí àwùjọ sọ ọ̀rọ̀ tí àwọn tó wá fún ìgbà àkọ́kọ́ sọ.
17 min: Ran Àwọn Ẹni Tuntun Lọ́wọ́ Láti Máa Wá sí Ìpàdé. Àsọyé táa gbé karí ìwé Ìmọ̀, ojú ìwé 162 àti 163, ìpínrọ̀ 5 sí 8. Bí àwọn ẹni tuntun bá ti kẹ́kọ̀ọ́ fún sáà kan, ó ṣe kókó pé kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wá sí àwọn ìpàdé. Ó lè kọ́kọ́ ṣòro fún wọn láti máa wá. Kí lo lè ṣe láti mú kí wọ́n máa wá? Kí àwọn tó ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ wá àyè láti jíròrò ọ̀rọ̀ yìí nínú ìwé Ìmọ̀ pẹ̀lú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọn, kí wọ́n sì ṣètò gúnmọ́ láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè dara pọ̀ mọ́ wa nínú ìjọsìn tòótọ́.
18 min: “Ǹjẹ́ O Ń Ṣe Déédéé Gẹ́gẹ́ Bí Akéde Ìjọba Náà?” Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ, akọ̀wé ni kó sì bójú tó o. Ṣàlàyé ìdí tí a fi ń ròyìn ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìsìn wa. (Wo ìwé Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-ojiṣẹ Wa, ojú ìwé 106 sí 108.) Ṣàlàyé díẹ̀ lára àwọn ìṣòro tó máa ń wáyé nígbà tí a ò bá tètè fi ìròyìn wa sílẹ̀. Sọ pé kí àwùjọ sọ ohun tí wọ́n ń ṣe láti rí i dájú pé àwọn ń fi ìròyìn àwọn sílẹ̀ lásìkò. Mẹ́nu kan ọ̀nà tí àwọn Olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ lè gbà ṣèrànwọ́. Òpin ọ̀sẹ̀ kan ṣoṣo ló kù nínú oṣù April, nítorí náà tẹnu mọ́ ọn pé ó ṣe pàtàkì kí gbogbo wa kópa nínú iṣẹ́ ìsìn, kí a sì ròyìn iṣẹ́ tí a bá ṣe bó bá di ìparí oṣù.
Orin 200 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 1
Orin 213
12 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Rán gbogbo akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti oṣù April sílẹ̀. Kí àwọn Olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ béèrè rẹ̀ lọ́wọ́ gbogbo àwọn tó wà ní ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ wọn kí a lè kó gbogbo ìròyìn jọ ní May 6. Ṣàyẹ̀wò Àpótí Ìbéèrè, sọ bí ẹ ṣe lè fi sílò nínú ìjọ yín.
18 min: “Béèrè Ìrànwọ́.” Kí alàgbà fi í sọ àsọyé, kó sì jíròrò rẹ̀ pẹ̀lú àwùjọ. Ṣàlàyé bí gbogbo wa ṣe nílò onírúurú ìrànwọ́ látìgbàdégbà. Àmọ́ ṣá o, olúkúlùkù ni yóò ru ẹrù ti ara rẹ̀. (Gál. 6:5) Ṣùgbọ́n, bí ọrùn bá fẹ́ wọ̀ wá, ká má ṣe lọ́ tìkọ̀ láti wá ìrànwọ́ lọ́dọ̀ àwọn tó dàgbà dénú nípa tẹ̀mí nínú ìjọ. Sọ pé kí àwùjọ sọ àwọn ìrírí tó ń fi hàn bí ìrànwọ́ onínúure tí àwọn ẹlòmíràn ṣe fún wọn ṣe fún wọn níṣìírí.
15 min: “Rí I Dájú Pé O Padà Lọ!” Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Jíròrò àwọn ohun tó lè mú ká kùnà láti ṣe ìpadàbẹ̀wò. Ṣàlàyé ìdí tí àkọsílẹ̀ tó péye, àti ìmúratán láti padà lọ fi ṣe pàtàkì. Dámọ̀ràn pé kí á máa ya àkókò díẹ̀ sọ́tọ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti ṣe ìpadàbẹ̀wò. Ṣàyẹ̀wò ohun tó wà nínú ìwé Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-ojiṣẹ Wa, ojú ìwé 88 àti 89. Sọ ìrírí tí a gbé jáde nínú ìwé ọdọọdún 1995 Yearbook, ojú ìwé 45.—1 Kọ́r. 3:6, 7.
Orin 68 àti àdúrà ìparí.