Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ó fi lọni ní oṣù May: Àwọn ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Ní ìwé pẹlẹbẹ Béèrè lọ́wọ́ nítorí àwọn èèyàn tó bá fìfẹ́ hàn, kí o sì sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn èèyàn nínú ilé wọn. June: Kí Ni Ọlọ́run Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? Pọkàn pọ̀ sórí bíbẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn èèyàn nínú ilé wọn. July àti August: A lè lo èyíkéyìí nínú àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé méjìlélọ́gbọ̀n tó tẹ̀ lé e yìí: Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá, Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae!, Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?, Ki Ni Ète Igbesi-Aye—Báwo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?, Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà tí A Bá Kú?, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae, àti Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi? Àwọn ìwé pẹlẹbẹ Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran Ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha Wa Niti Gidi Bi? àti Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn ni a lè fi lọni nígbà tó bá yẹ.
◼ Nínú Iṣẹ́-Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti July 1994, a mẹ́nu kàn án pé, ní ọjọ́ Sátidé tó bá kẹ́yìn nínú oṣù èyíkéyìí, kò ní sí ṣíṣèbẹ̀wò sí ilé Bẹ́tẹ́lì láti rìn ín yíká. A ti yí ìyẹn padà báyìí. Ní báyìí, àyè wà fún ìjọ tàbí ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ ṣèbẹ̀wò sí ilé Bẹ́tẹ́lì ní Igieduma, ní gbogbo ọjọ́ Sátidé nínú oṣù. Ní ọjọ́ Monday sí Sátidé, a lè ṣe ìbẹ̀wò yíká láàárín agogo mẹ́jọ sí agogo mọ́kànlá òwúrọ̀ àti láàárín agogo kan ọ̀sán sí agogo mẹ́rin ìrọ̀lẹ́. Kí ẹ tètè dé láti ṣèbẹ̀wò yíká kí ẹ lè ṣe tán lákòókò kí ẹ sì padà sílé lọ́jọ́ kan náà. Kò sí àyè ibi tí àwọn tó bá wá ṣèbẹ̀wò yíká máa sùn ní Bẹ́tẹ́lì. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ fi sọ́kàn pé kò ní sí ṣíṣe ìbẹ̀wò yíká ní ọjọ́ Sunday o.
◼ Kí alábòójútó olùṣalága tàbí ẹnì kan tí ó yàn ṣàyẹ̀wò àkáǹtì ìjọ ní June 1, tàbí bó bá ṣe lè yá tó lẹ́yìn náà. Bí ẹ bá ti ṣe èyí, ẹ ṣe ìfilọ̀ fún ìjọ lẹ́yìn tí ẹ bá ti ka ìròyìn ìnáwó tó tẹ̀ lé e.
◼ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ ṣe àtúnṣe yìí nínú ìwé Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-ojiṣẹ wa tiyín lédè Yorùbá, ojú ìwé 50, láàárín ìlà 4 sí 8. Gbólóhùn náà kà pé: “Lori idamọran alaboojuto ayika, Society yoo yan awọn oṣiṣẹ apejọ tí yoo maa bojuto awọn ọran apejọ naa titi lọ, oluranlọwọ alaboojuto apejọ ati aṣoju onirohin kan.” Kí gbólóhùn náà kà báyìí lọ́nà tí ó tọ́ pé: “Lórí ìdámọ̀ràn alábòójútó àyíká, Society yóò yan àwọn òṣìṣẹ́ àpéjọ tí yóò máa bójú tó àwọn ọ̀ràn àpéjọ náà títí lọ: alábòójútó àpéjọ, olùrànlọ́wọ́ alábòójútó àpéjọ àti aṣojú oníròyìn kan.” A máa ṣe àtúnṣe yìí nígbà tí a bá tún ìwé yìí tẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.