Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 8
Orin 36
12 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ṣàyẹ̀wò Àpótí Ìbéèrè.
20 min: “Ẹ Wà Lójúfò.” Ìjíròrò lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Ṣàlàyé ìdí tó fi jẹ́ kánjúkánjú pé ká wà lójúfò nípa tẹ̀mí bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò mọ ọjọ́, tí a kò sì mọ oṣù.—Wo Ilé-Ìṣọ́nà, November 1, 1995, ojú ìwé 20.
13 min: Kí Làwọn Ìwéwèé Rẹ fún Ìgbà Ẹ̀ẹ̀rùn? Ìdílé kan jíròrò ohun tí wọn yóò ṣe láwọn oṣù ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn. Wọ́n sọ̀rọ̀ nípa lílọ sí gbogbo ìpàdé àti àpéjọ àti ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ fún oṣù kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Àǹfààní tún lè wà láti ṣèbẹ̀wò sí ọgbà tí wọ́n ti lè rí àwọn nǹkan ìṣẹ̀dá tàbí kí wọ́n kópa nínú àwọn eré ìtura mìíràn tó gbámúṣé. Gbogbo wọn fohùn ṣọ̀kan láti má ṣe pa àwọn ìgbòkègbodò ìṣàkóso Ọlọ́run tí wọ́n máa ń ṣe tì.
Orin 83 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 15
Orin 134
13 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó.
17 min: “Ǹjẹ́ O Máa Ń Fi Hàn Pé O Moore?” Àsọyé tí alàgbà sọ, tí a gbé karí Ilé Ìṣọ́, April 15, 1999, ojú ìwé 15 sí 17.
15 min: “Àpéjọpọ̀ Àgbègbè ‘Àwọn Olùṣe Ohun Tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Wí’ ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Ọdún 2000.” Akọ̀wé jíròrò ìpínrọ̀ 1 sí 10 ti àpilẹ̀kọ tó wà nínú àkìbọnú lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Lo àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a tọ́ka sí láti fi ìdí tó fi yẹ kí gbogbo wa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Society láìkù síbi kan hàn.
Orin 91 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 22
Orin 125
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ àti àwọn Ìfilọ̀ táa mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa.
20 min: Báwo ló ṣe yẹ kí ìfẹ́sọ́nà ṣe pàtàkì tó lójú àwọn Kristẹni? Àsọyé tí a gbé karí Ilé Ìṣọ́, August 15, 1999, ojú ìwé 30 àti 31.
15 min: “Àpéjọpọ̀ Àgbègbè ‘Àwọn Olùṣe Ohun Tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Wí’ ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Ọdún 2000.” Alàgbà kan jíròrò ìpínrọ̀ 11 sí 17 ti àpilẹ̀kọ tó wà nínú àkìbọnú lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Tẹnu mọ́ ọn pé ó ṣe pàtàkì pé kí olúkúlùkù ṣètò àkókò ìsinmi tó ṣe gúnmọ́ ṣáájú àkókò láti lè lọ sí gbogbo ọjọ́ àpéjọpọ̀ náà, títí kan ọjọ́ Friday. Gbóríyìn fún àwọn ará fún fífọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ìṣètò Society.
Orin 56 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 29
Orin 135
12 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán gbogbo akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti oṣù May sílẹ̀. Jẹ́ kí á ṣàṣefihàn ṣókí nípa bí a ṣe lè fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ lọni lóṣù June. Fi bí a ṣe lè fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọni hàn nípa lílo Ẹ̀kọ́ 13 nínú ìwé pẹlẹbẹ Béèrè.
15 min: “Rírí Ìdùnnú Nínú Iṣẹ́ Ìsìn Mímọ́ Rẹ.” Àsọyé. Jíròrò àwọn ìdí tó fi yẹ kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa máa mú inú wa dùn.—Wo ìwé Insight, Apá Kejì, ojú ìwé 120.
18 min: Bíbélì Kíkà Tí Ń Mérè Wá. Àsọyé àti àṣefihàn táa gbé karí Iwe-Amọna Ile Ẹkọ, ojú ìwé 35, ìpínrọ̀ 6 àti 7. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Bíbélì kíkà, tí a máa ń gbé kókó pàtàkì láti inú Bíbélì kà, jẹ́ ara ètò ẹ̀kọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run. (Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti December 1999, ojú ìwé 7) Jẹ́ kí ìdílé kan ṣàṣefihàn bí ìdílé ṣe lè ṣàyẹ̀wò ibi tí a ó kà lọ́sẹ̀ yìí ní ilé ẹ̀kọ́ náà. Wọ́n yan kókó fífanimọ́ra kan tàbí méjì, wọ́n sì ṣe àfikún ìwádìí nínú ìwé Watch Tower Publications Index tàbí ìwé Insight on the Scriptures. Sọ bí Bíbélì kíkà ṣe lè túbọ̀ nítumọ̀, tí yóò sì túbọ̀ mú wa gbára dì láti “fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́.”—2 Tím. 2:15.
Orin 95 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 5
Orin 37
5 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.
10 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
15 min: “Àǹfààní Tó Ṣí Sílẹ̀ fún Àwọn Èwe.” Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Sọ àwọn ìrírí tó wà nínú Ilé Ìṣọ́, December 1, 1996, ojú ìwé 13, ìpínrọ̀ 15. Sọ pé kí àwọn èwe sọ bí wọ́n ṣe gbádùn pípín ìwé ìròyìn. Jẹ́ kí èwe kan tàbí méjì ṣàṣefihàn fífi ìwé ìròyìn lọni láti ẹnu ọ̀nà dé ẹnu ọ̀nà, kí ó jẹ́ èyí tó rọrùn. Fún àwọn òbí níṣìírí pé kí wọ́n máa mú àwọn ọmọ wọn dání bí wọ́n bá ń lọ sẹ́nu iṣẹ́ ìwé ìròyìn lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.
15 min: “‘Kí A Dán Wọn Wò Ní Ti Bí Wọ́n Ti Yẹ Sí’—Lọ́nà Wo?” Àsọyé tí alàgbà sọ. Ṣàyẹ̀wò ètò tí Ìwé Mímọ́ fi lélẹ̀ fún níní àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nínú ìjọ. (Wo ìwé Insight, Apá Kejì, ojú ìwé 409.) Sọ bí wọn yóò ṣe tóótun sí kí a tó lè yàn wọ́n sípò. (Wo ìwé Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-ojiṣẹ Wa, ojú ìwé 55 sí 57.) Ṣàlàyé àwọn ọ̀nà tí àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ lè gbà sìn, kí o sì fún àwọn arákùnrin púpọ̀ sí i níṣìírí pé kí wọ́n nàgà fún àǹfààní yìí.
Orin 82 àti àdúrà ìparí.