ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 5/00 ojú ìwé 1
  • Àǹfààní Tó Ṣí Sílẹ̀ fún Àwọn Èwe

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àǹfààní Tó Ṣí Sílẹ̀ fún Àwọn Èwe
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹ̀yin Òbí—Ẹ Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín Láti Wàásù
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Ran Àwọn Ọmọ Yín Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • Ẹ̀yin Òbí—ẹ Máa Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín Tìfẹ́tìfẹ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Múra Ìgbékalẹ̀ Tìrẹ fún Ìfilọni Ìwé Ìròyìn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
km 5/00 ojú ìwé 1

Àǹfààní Tó Ṣí Sílẹ̀ fún Àwọn Èwe

1 Ọ̀pọ̀ àwọn tó jẹ́ òbí lónìí ni inú wọn máa ń dùn bí wọ́n bá rántí àǹfààní tí wọ́n gbádùn nígbà tí wọ́n wà lọ́mọdé, bí wọ́n ti ń dàgbà nínú òtítọ́. Àǹfààní náà sì ni ìgbòkègbodò Ọjọ́ Ìwé Ìròyìn. Ọdún 1949 la dá iṣẹ́ yẹn sílẹ̀ nínú gbogbo ìjọ. Lọ́jọ́ kan lọ́sẹ̀, gbogbo akéde ní láti lọ pín Ilé Ìṣọ́ àti Jí! kiri ní òpópónà, láti ilé dé ilé, láti ilé ìtajà dé ilé ìtajà, àti ní àwọn ọ̀nà mìíràn. Ní pàtàkì, àwọn akéde tó jẹ́ èwe máa ń fojú sọ́nà láti kópa nínú iṣẹ́ yìí nítorí ó ń fún wọn láǹfààní láti kópa nínú iṣẹ́ kan náà táwọn àgbàlagbà nínú ìjọ ń ṣe. Ṣé bẹ́ẹ̀ lọ̀ràn ìwọ náà rí nígbà tóo wà lọ́mọdé?

2 Jẹ́ Káwọn Ọmọ Rẹ Ṣe É: Àwọn ọmọ kéékèèké tí kò lè bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò táa gbé karí Ìwé Mímọ́ lẹ́nu ọ̀nà ṣì lè fi ìwé ìròyìn lọni. Ó ń béèrè pé kí wọ́n wulẹ̀ kọ́ bí wọ́n ṣe lè gbé ọ̀rọ̀ kalẹ̀ lọ́nà rírọrùn nípa sísọ gbólóhùn mélòó kan. Àlàyé díẹ̀ tó lè dá lérí àwòrán tó wà lẹ́yìn ìwé náà ti tó. Ọ̀pọ̀ àwọn tí à ń bá sọ̀rọ̀ máa ń tètè gba àwọn ìwé ìròyìn wa lọ́wọ́ àwọn ọmọ kéékèèké, wọ́n sì sábà máa ń sọ̀rọ̀ ire lẹ́nu nípa bí ìwà àwọn èwe yẹn ṣe dáa tó, àti bí wọ́n ṣe jẹ́ olóòótọ́ ọkàn. Báa bá ran àwọn ọmọ lọ́wọ́ díẹ̀, wọ́n lè ṣe iṣẹ́ ìsìn yìí dáadáa, wọ́n á sì ṣe bẹbẹ nínú sísọ ìhìn Ìjọba náà fún àwọn èèyàn. Àmọ́ ṣá o, bí àwọn ọmọ ti ń dàgbà, àwọn òbí ní láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti máa tẹ̀ síwájú nínú mímú kí òye wọn nípa iṣẹ́ ìjẹ́rìí pọ̀ sí i.

3 Ọmọ ọdún mẹ́ta ni Manuel nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí wàásù láti ẹnu ọ̀nà dé ẹnu ọ̀nà. Àwọn òbí rẹ̀ fi ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ kan tí kò gùn kọ́ ọ, ó sì há a sórí. Tìtaratìtara ló máa ń wàásù bó ti ń bá wọn jáde, ó sì ń fi ọ̀pọ̀ ìwé ìròyìn, ìwé pẹlẹbẹ, àti ìwé àṣàrò kúkúrú sóde. Ó tún máa ń jẹ́rìí láìjẹ́ bí àṣà. Lákòókò kan, nígbà tí àwọn òbí rẹ̀ mú un lọ sí ọgbà ìṣeré kan láti ṣeré, ó lo ìdánúṣe láti lọ fún àwọn èèyàn tó wà níbẹ̀ ní ìwé àṣàrò kúkúrú. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọmọ kékeré gan-an ni Manuel, ìtara rẹ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ jẹ́ orísun ìṣírí gidi fún àwọn òbí rẹ̀ àti fún ìjọ lódindi.—Òwe 22:6.

4 Gbogbo ọjọ́ Sátidé la fi ṣe “Ọjọ́ Ìwé Ìròyìn” lórí kàlẹ́ńdà wa tọdún yìí, ìyẹn ni 2000 Calendar of Jehovah’s Witnesses. Ẹ̀yin òbí, a rọ̀ yín pé kí ẹ túbọ̀ mú iṣẹ́ yìí lọ́kùn-únkúndùn, kí ẹ sì ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti máa lo àǹfààní iṣẹ́ ìsìn yìí déédéé bó bá ti ṣeé ṣe tó.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́