Ẹ̀yin Òbí—Ẹ Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín Láti Wàásù
1 Àwọn ìjọ wa kún fún ọ̀pọ̀ ọmọ tí wọ́n ní ìfẹ́ ọkàn aláìlábòsí láti ṣiṣẹ́ sin Ọlọ́run. (Oníw. 12:1) Wọ́n wà lára àwọn tí Jèhófà ké sí láti nípìn-ín nínú yíyin òun. (Orin Dá. 148:12-14) Nítorí náà, ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ojoojúmọ́ tí àwọn òbí ń fún àwọn ọmọ wọn gbọ́dọ̀ ní ìtọ́ni nínú nípa bí wọn yóò ṣe ṣàjọpín ìgbàgbọ́ wọn pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba.—Diu. 6:6, 7.
2 Dá Àwọn Ọmọ Lẹ́kọ̀ọ́ ní Ṣísẹ̀-N-Tẹ̀lé: Ó yẹ kí a dá àwọn ọmọ lẹ́kọ̀ọ́ láti ìgbà kékeré jòjòló láti bá àwọn òbí wọn lọ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ṣáájú kí ẹ tó lọ sẹ́nu iṣẹ́ ìsìn, múra àwọn ọmọ rẹ sílẹ̀ láti kópa lọ́nà tí ó nítumọ̀. Pinnu ṣáájú nípa ohun tí o retí pé kí wọ́n ṣe lẹ́nu ọ̀nà. Àwọn ọmọ tí wọ́n kéré jọjọ lè fi ìwé àṣàrò kúkúrú àti ìwé ìléwọ́ léni lọ́wọ́ kí wọ́n sì ké sí àwọn ènìyàn sí Gbọ̀ngàn Ìjọba. A lè ké sí àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n lè kàwé dáradára láti ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ lẹ́nu ọ̀nà. Wọ́n lè fi àwọn ìwé ìròyìn lọni nípa lílo ìgbékalẹ̀ ṣókí. Bí wọ́n ṣe ń jèrè ìrírí, dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ láti lo Bíbélì nínú ìgbékalẹ̀ wọn. Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ akéde ti bẹ̀rẹ̀ ipa ọ̀nà ìwé ìròyìn tiwọn, wọ́n sì ń ṣe ìpadàbẹ̀wò déédéé. Ó dára jù lọ pé kí ọmọdé kan bá àgbàlagbà ṣiṣẹ́ jù pé kí ó bá èwe mìíràn ṣiṣẹ́. Àgbàlagbà náà lè ṣàlàyé fún onílé pé a ń dá ọ̀dọ́ náà lẹ́kọ̀ọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ni.
3 Ọmọbìnrin kékeré kan béèrè ìrànwọ́ àwọn alàgbà kí òun baà lè tóótun gẹ́gẹ́ bí akéde Ìjọba. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ ọdún márùn-ún péré ni ní àkókò náà, tí kò sì mọ ìwé kà, òun lè gbé ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà kalẹ̀ dáradára lẹ́nu ọ̀nà. Ó kọ́ ibi tí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wà sórí, yóò ṣí wọn, yóò sì sọ fún onílé pé kí ó kà wọ́n lẹ́yìn náà yóò ṣàlàyé.
4 Nípasẹ̀ àpẹẹrẹ òbí, a tún gbọ́dọ̀ kọ́ àwọn ọmọ ní ìníyelórí níní ìṣètò rere fún nínípìn-ín déédéé nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Àwọn òbí gbọ́dọ̀ fìdí ipa ìṣiṣẹ́ déédéé ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ múlẹ̀ fún iṣẹ́ ìsìn, kí wọ́n sì rọ̀ mọ́ ọn kí àwọn ọmọ baà lè mọ apá tí a máa ń yà sọ́tọ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ fún iṣẹ́ ìwàásù.
5 Nígbà tí a bá dá àwọn ọmọ lẹ́kọ̀ọ́ láti ìgbà tí ọjọ́ orí wọn ṣì kéré, láti nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kí wọ́n sì gbádùn rẹ̀, a óò sún wọn láti nàgà fún àwọn àǹfààní títóbi jù ní ọjọ́ iwájú, bóyá títí kan iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà. (1 Kọ́r. 15:58) Gbogbo wa gbọ́dọ̀ fún àwọn ọmọdé tí ń bẹ láàárín wa níṣìírí láti tẹ̀ síwájú dáradára gẹ́gẹ́ bí olùyin Jèhófà.