Kọ́ Àwọn Ọmọ Rẹ Láti Máa Yin Jèhófà
1. Ǹjẹ́ àwọn ọ̀dọ́mọdé lè yin Jèhófà?
1 Sáàmù 148:12, 13, gba àwọn ọmọdé lọ́kùnrin àti lóbìnrin níyànjú láti “máa yin orúkọ Jèhófà.” Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àpẹẹrẹ àwọn ọ̀dọ́mọdé tó yin orúkọ Jèhófà kúnnú Ìwé Mímọ́. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé: “Sámúẹ́lì sì ń ṣe ìránṣẹ́ níwájú Jèhófà, gẹ́gẹ́ bí ọmọdékùnrin kan.” (1 Sám. 2:18) “Ọmọdébìnrin kékeré kan” ló sọ fún aya Náámánì pé wòlíì Jèhófà kan wà ní Ísírẹ́lì tó lè wo àrùn ẹ̀tẹ̀ Náámánì sàn. (2 Ọba 5:1-3) Nígbà tí Jésù wọ tẹ́ńpìlì tó sì ṣiṣẹ́ ìyanu, “àwọn ọmọdékùnrin” bẹ̀rẹ̀ sí í pariwo pé: “Gba Ọmọkùnrin Dáfídì là, ni àwa bẹ̀bẹ̀!” (Mát. 21:15) Báwo làwọn òbí ṣe lè kọ́ àwọn ọmọ wọn láti máa yin Jèhófà?
2. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì fáwọn òbí láti fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fáwọn ọmọ wọn?
2 Àpẹẹrẹ: Káwọn tó jẹ́ bàbá ní Ísírẹ́lì tó lè kọ́ àwọn ọmọ wọn ní òtítọ́ débi tó fi máa wọ̀ wọ́n lọ́kàn, Ọlọ́run pàṣẹ pé káwọn alára kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ná, kí wọ́n sì jẹ́ kí òfin rẹ̀ wà ní ọkàn àwọn fúnra wọn. (Diu. 6:5-9) Bó o bá ń sọ̀rọ̀ tó lè fúnni níṣìírí nípa iṣẹ́ ìwàásù, tó o sì rí i dájú pé ọ̀sẹ̀ kan ò kọjá láìlọ sóde ẹ̀rí, ó máa rọrùn fáwọn ọmọ rẹ láti ka iṣẹ́ ìwàásù sí iṣẹ́ pàtàkì tó ń fúnni láyọ̀.
3. Ìbùkún wo ni arábìnrin kan rí látinú àpẹẹrẹ táwọn òbí rẹ̀ fi lélẹ̀?
3 Ohun tí arábìnrin kan sọ rèé: “Nígbà tí mo wà lọ́mọdé, jíjáde òde ẹ̀rí ní gbogbo òpin ọ̀sẹ̀ wà lára ohun tí ìdílé wa kì í fi í ṣeré. Jíjáde tá a máa ń jáde yìí jẹ́ kó yé mi pé àwọn òbí mi fẹ́ràn iṣẹ́ ìwàásù. Ìgbà tá a fi máa dàgbà, iṣẹ́ ìwàásù ti wá gbádùn mọ́ wa gan-an.” Ẹni ọdún méje ni arábìnrin tó sọ ìrírí ara rẹ̀ yìí nígbà tó di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi, ọdún kẹtàlélọ́gbọ̀n ẹ̀ sì rèé lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún.
4. Ọ̀nà wo lèèyàn lè gbà tọ́ ọmọ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé?
4 Máa Kọ́ Wọn ní Ṣísẹ̀-N-Tẹ̀-Lé: Ẹ máa mú àwọn ọmọ yín dání bẹ́ ẹ bá ń lọ sóde ẹ̀rí. Ẹ lè sọ pé kí wọ́n máa báa yín kan ìlẹ̀kùn tàbí kí wọ́n máa tẹ aago ẹnu ọ̀nà, kí wọ́n máa fáwọn tẹ́ ẹ bá bá sọ̀rọ̀ ní ìwé àṣàrò kúkúrú, tàbí kí wọ́n bá yín ka Ìwé Mímọ́ pàápàá. Èyí á jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ gbádùn iṣẹ́ ìwàásù, á sì jẹ́ kí wọ́n nígboyà láti lè máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Bí wọ́n bá ṣe ń dàgbà sí i ni ìwọ̀n tí wọ́n ń ṣe nínú iṣẹ́ ìwàásù gbọ́dọ̀ máa gbé pẹ́ẹ́lí sí i. Nítorí náà, ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa tẹ̀ síwájú, kí wọ́n sì máa ronú lórí apá iṣẹ́ ìsìn tí wọ́n á fẹ́ láti fojú sùn.
5. Kí lọmọ kan ní láti ṣe kó tó lè tóótun gẹ́gẹ́ bí akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi?
5 Sọ fáwọn alàgbà ní gbàrà tó o bá ti róye pé àwọn ọmọ rẹ ti tó láti di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi, àmọ́ ìyẹn á jẹ́ lẹ́yìn tọ́mọ náà bá ti fẹnu ara ẹ̀ sọ pé ó wu òun. Wọ́n á túbọ̀ mọ̀ pé ojúṣe àwọn ni láti máa yin Jèhófà bí wọ́n bá di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi. Fi sọ́kàn pé kò dìgbà tọ́mọdé kan bá tó mọ gbogbo ohun tí àgbàlagbà tó ti ṣèrìbọmi mọ̀ kó tó lè yẹ lẹ́ni tó lè ṣèrìbọmi. Ṣé ọmọ rẹ lóye àwọn ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ inú Bíbélì? Ṣó máa ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì nípa ìwà tó yẹ ká máa hù? Ǹjẹ́ ó wù ú pé kóun náà máa wàásù, kóun sì di ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Bí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè wọ̀nyí bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, àwọn alàgbà lè pinnu pé ó ti yẹ láti di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi.—Wo ìwé A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà, ojú ìwé 79 sí 82.
6. Kí nìdí tó fi bójú mu pé káwọn òbí máa kọ́ àwọn ọmọ wọn?
6 Ó máa ń gba ìsapá láti kọ́ àwọn ọmọ débi tí wọ́n á fi lè dẹni tó ń yin Jèhófà látọkàn wá. Síbẹ̀ ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí nǹkan míì tó lè fún àwọn òbí láyọ̀ tó káwọn ọmọ wọn máa tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Èyí tó tiẹ̀ tún ṣe pàtàkì jù ni pé inú Jèhófà máa ń dùn láti rí báwọn ọmọ ṣe ń polongo àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀.