ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 1/11 ojú ìwé 7
  • Kọ́ Àwọn Ọmọ Rẹ Láti Di Òjíṣẹ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kọ́ Àwọn Ọmọ Rẹ Láti Di Òjíṣẹ́
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Gbígbé Ìdílé Tó Dúró Sán-ún Nípa Tẹ̀mí Ró
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Ẹ̀yin Òbí—Ẹ Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín Láti Ìgbà Ọmọdé Jòjòló
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
  • Àwọn Góńgó Wo Ni O Ti Gbé Kalẹ̀ fún Àwọn Ọmọ Rẹ?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1995
  • Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín Kí Wọ́n Lè Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
km 1/11 ojú ìwé 7

Kọ́ Àwọn Ọmọ Rẹ Láti Di Òjíṣẹ́

1. Kí ni Sáàmù 148:12, 13 rọ àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ Kristẹni láti ṣe?

1 Jèhófà ní kí àwọn ọ̀dọ́ máa yin òun. (Sm. 148:12, 13) Torí náà, àwọn òbí tí wọ́n jẹ́ Kristẹni ní láti kọ́ àwọn ọmọ wọn ní ẹ̀kọ́ òtítọ́ Bíbélì àti àwọn òfin Ọlọ́run nípa ìwà rere. Àmọ́, wọ́n tún ní láti kọ́ wọn láti jẹ́ òjíṣẹ́ ìhìn rere. Báwo ni wọ́n ṣe lè máa ṣe èyí ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé?

2. Báwo ni àpẹẹrẹ rere àwọn òbí ṣe lè ní ipa lórí àwọn ọmọ?

2 Àpẹẹrẹ Rere: Gídíónì tó jẹ́ adájọ́ sọ fún àwọn ọ̀ọ́dúnrún ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀ pé: “Ẹ kẹ́kọ̀ọ́ nípa wíwò mí.” (Oníd. 7:17) Àṣà àwọn ọmọdé ni láti máa wo àwọn òbí wọn, kí wọ́n sì máa fara wé wọn. Bàbá kan máa ń ṣe iṣẹ́ alẹ́, àmọ́ dípò tí ì bá fi lọ sùn nígbà tó bá dé láti ibi iṣẹ́ láàárọ̀ ọjọ́ Saturday, ńṣe ló máa ń kó àwọn ọmọ rẹ̀ lọ sí òde ẹ̀rí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti máa rẹ̀ ẹ́ tẹnutẹnu. Láìjẹ́ pé ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń sọ fún wọn, ńṣe ló ń fi ìwà rẹ̀ kọ́ àwọn ọmọ náà pé iṣẹ́ ìwàásù ló yẹ kó wà nípò àkọ́kọ́. (Mát. 6:33) Ǹjẹ́ àwọn ọmọ rẹ ń wò ẹ́ bó o ṣe ń lọ́wọ́ nínú gbogbo apá tí ìjọsìn wa pín sí tayọ̀tayọ̀, irú bíi gbígbàdúrà, kíka Bíbélì, dídáhùn ní ìpàdé àti wíwàásù? Ó lè má jẹ́ gbogbo nǹkan lo máa lè ṣe lọ́nà tó pé pérépéré. Àmọ́ á ṣeé ṣe fún àwọn ọmọ rẹ láti tẹ̀ lé ohun tó ò ń kọ́ wọn láti máa jọ́sìn Jèhófà bí wọ́n bá rí i pé ìwọ fúnra rẹ jẹ́ aláápọn lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.—Diu. 6:6, 7; Róòmù 2:21, 22.

3. Àwọn àfojúsùn tẹ̀mí wo ló yẹ káwọn òbí máa ran àwọn ọmọ lọ́wọ́ kí ọwọ́ wọn lè tẹ̀ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé?

3 Àwọn Àfojúsùn Tí Ọwọ́ Lè Tẹ̀ Ní Ṣísẹ̀-N-Tẹ̀lé: Iṣẹ́ kékeré kọ́ làwọn òbí máa ń ṣe láti kọ́ àwọn ọmọ láti rìn, láti sọ̀rọ̀, láti máa dá múra àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Bí àwọn ọmọ ṣe ń dàgbà, a tún máa ń fẹ́ gbé àwọn àfojúsùn míì ka iwájú wọn. Bí àwọn òbí bá jẹ́ Kristẹni, wọ́n tún máa ń ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti ní àwọn àfojúsùn tẹ̀mí, kí ọwọ́ wọn sì tẹ àwọn àfojúsùn náà. (1 Kọ́r. 9:26) Ṣé ò ń kọ́ àwọn ọmọ rẹ láti máa dáhùn lọ́rọ̀ ara wọn ní ìpàdé àti láti máa múra iṣẹ́ tí wọ́n bá ní ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run sílẹ̀ fúnra wọn? (Sm. 35:18) Ṣé ò ń kọ́ wọn láti máa lọ́wọ́ nínú onírúurú apá tí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa pín sí? Ṣé o ti jẹ́ kí wọ́n fi ṣíṣe ìrìbọmi àti iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ṣe àfojúsùn wọn? Ǹjẹ́ o ń mú wọn mọ àwọn ajíhìnrere tí wọ́n jẹ́ aláyọ̀ àti onítara tí wọ́n lè fún àwọn ọmọ rẹ ní ìṣírí?—Òwe 13:20.

4. Báwo ni àwọn ọmọ ṣe lè jàǹfààní bó bá jẹ́ pé àti kékeré ni àwọn òbí ti bẹ̀rẹ̀ sí í dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́?

4 Onísáàmù náà sọ pé: “Ọlọ́run, ìwọ ti kọ́ mi láti ìgbà èwe mi wá, títí di ìsinsìnyí, mo sì ń bá a nìṣó ní sísọ nípa àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ.” (Sm. 71:17) Látìgbà tí àwọn ọmọ rẹ ti wà ní kékeré ni kó o ti máa kọ́ wọn láti di òjíṣẹ́. Ó dájú pé bó o ṣe ń gbìyànjú láti fi ẹsẹ àwọn ọmọ rẹ lé ọ̀nà òtítọ́ máa ṣe wọ́n láǹfààní nígbà tí wọ́n bá dàgbà!—Òwe 22:6.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́