Àwọn Góńgó Wo Ni O Ti Gbé Kalẹ̀ fún Àwọn Ọmọ Rẹ?
1 Àṣeyọrí nínú ìgbésí ayé sinmi lórí gbígbé àti lílé àwọn góńgó tí ó níláárí bá. Àwọn wọnnì tí ń lépa àwọn góńgó tí kò ṣe pàtàkì tàbí tí kò ṣeé lé bá, ń ní ìjákulẹ̀ àti àìṣàṣeyọrí. Ó gba ọgbọ́n láti fi òye mọ àwọn góńgó ti ó yẹ kí a lépa, láti baà lè “di ìyè tòótọ́ gidi mú gírígírí.” (1 Tim. 6:19, NW) Ẹ wo bí a ti kún fún ọpẹ́ tó pé Jehofa, nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ àti ètò-àjọ rẹ̀, ń fi ọ̀nà gan-an tí a óò tọ̀ hàn wá!—Isa. 30:21.
2 Ní pípèsè irú ìdarísọ́nà onífẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀, Jehofa fi àpẹẹrẹ tí ó dára lélẹ̀ fún àwọn òbí. Dípò yíyọ̀ǹda fún àwọn ọmọ wọn tí kò ní ìrírí láti yan ọ̀nà tí ó dára jù lọ, àwọn òbí tí ó gbọ́n ń kọ́ wọn ní ọ̀nà tí ó yẹ kí wọ́n tọ̀, nígbà tí wọ́n bá sì dàgbà tán, wọn “kì yóò kúrò nínú rẹ̀.” (Owe 22:6) Àwọn Kristian tí wọ́n jẹ́ òbí mọ̀ láti inú ìrírí pé, àwọn kò lè gbẹ́kẹ̀ lé ìpinnu àwọn tìkálára wọn; àwọn gbọ́dọ̀ fọkàn tẹ Jehofa. (Owe 3:5, 6) Àìní yìí túbọ̀ ga fún àwọn ọmọ, àwọn tí ìmọ̀ wọn àti ìrírí wọn kò tó nǹkan.
3 Àwọn òbí lè gbé àwọn góńgó tí ó níláárí síwájú àwọn ọmọ wọn, tí yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti pọkàn pọ̀ sórí “awọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.” (Filip. 1:10, NW) Wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé, ní fífún àwọn ọmọ ní ìṣírí láti mọrírì ìjẹ́pàtàkì rẹ̀, kí wọ́n sì kẹ́kọ̀ọ́ láti inú rẹ̀. Ó dára kí àwọn ọmọ sọ ọ́ dàṣà láti máa múra sílẹ̀ fún àwọn ìpàdé ìjọ, kí wọ́n sì múra sílẹ̀ láti dáhùn ní ọ̀rọ̀ tiwọn fúnra wọn. Ṣíṣàjọpín déédéé nínú iṣẹ́ ìwàásù ṣe pàtàkì. Àwọn ọ̀dọ́ lè ṣàjọpín nípa fífi àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú lọni, kíka ìwé mímọ́, tàbí fífi ìwé ìròyìn lọni. Nígbà tí wọ́n bá ti lè kàwé, fíforúkọ wọn sílẹ̀ nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọrun lè mú ìtẹ̀síwájú wọn nípa tẹ̀mí yára kánkán. Títóótun gẹ́gẹ́ bí akéde tí kò tí ì batisí tàbí dídi ẹni tí a tẹ́wọ́ gbà fún ìbatisí jẹ́ ìtẹ̀síwájú ńlá kan.
4 Bí àwọn ọmọ wọn ti ń tó ọmọ ọdún mẹ́tàlá, tàbí ṣáájú ìgbà yẹn pàápàá, ó yẹ kí àwọn òbí bá wọn sọ̀ òkodoro ọ̀rọ̀ nípa àwọn góńgó ìgbésí ayé. Ó rọrùn fún àwọn agbaninímọ̀ràn ní ilé ẹ̀kọ́ àti àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn láti nípa lórí wọn, ní yíyan àwọn ìlépa ayé ti onífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì. Ó yẹ kí àwọn òbí ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti yan àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tí ń pèsè ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí ó wúlò, ní mímú wọn gbara dì láti bójú tó àwọn àìnì wọn ti ara, láìjẹ́ pé wọ́n fi àwọn ire Ìjọba rúbọ. (1 Tim. 6:6-10) A lè fún wọn ní ìṣírí láti lépa “ẹ̀bùn” wíwà ní àpọ́n, àti ní ọjọ́ iwájú, bí wọ́n bá pinnu láti ṣe ìgbéyàwó, yóò ṣeé ṣe fún wọn láti tẹ́rí gba àwọn ẹrù iṣẹ́ ìgbeyàwó tí ó wúwo. (Matt. 19:10, 11, NW; 1 Kor. 7:36-38) Nípa sísọ̀rọ̀ lọ́nà tí ń gbéni ró nípa iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà, ṣíṣiṣẹ́sìn níbi tí àìní ti pọ̀ jù, iṣẹ́ ìsìn Beteli, tàbí Ilé Ẹ̀kọ́ Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́, àwọn òbí lè gbin ìfẹ́ àtọkànwá láti lo ìgbésí ayé wọn ní ọ̀nà tí ń dùn mọ́ Jehofa nínú, tí ń ṣe àwọn ẹlòmíràn láǹfààní, tí sì ń mú ìbùkún wá fún àwọn alára, sọ́kàn àwọn ọmọdé, àní láti kékeré pàápàá.
5 Kì í ṣe nípa èèṣì ni a fi rí ọ̀pọ̀ jaburata ọ̀dọ́ nínú ètò àjọ lónìí, tí wọ́n rọ̀ mọ́ àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n gíga Kristian, tí wọ́n sì ń lépa góńgó ìṣàkóso Ọlọrun. Èyí tí ó pọ̀ jù lára àwọn àṣeyọrí wọn ní a lè sọ pé ó wáyé nítorí àwọn òbí onífẹ̀ẹ́. Bí ìwọ bá jẹ́ òbí kan, níbo ní ó dà bíi pé àwọn ọmọ rẹ forí lé? Wọ́n ha ń tẹ̀ síwájú ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé síhà ìgbésí ayé tí ó pọkàn pọ̀ sórí àwọn ire Ìjọba? Rántí pé ọ̀kan lára àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù lọ tí o lè ṣe ni láti gbin òtítọ́ sínú àwọn ọmọ rẹ, kí o sì máa sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ lójoojúmọ́. A lè fi agbo ilé tí ó jẹ́ olùṣòtítọ́ nínú ṣíṣiṣẹ́sin Jehofa bùkún ọ.—Deut. 6:6, 7; Joṣ. 24:15.