Gbé Àwọn Góńgó Tí Wàá Lépa ní Ọdún Iṣẹ́ Ìsìn Tuntun Kalẹ̀
1 Ṣé inú rẹ ń dùn sí àwọn àṣeyọrí tó o ti ní nípa tẹ̀mí? Ohun tó dára ni pé ká máa tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, àmọ́ èyí gba ìsapá. Ohun tí yóò ràn wá lọ́wọ́ ni pé kí àwa àti ìdílé wa gbé àwọn góńgó tí a ó máa lépa kalẹ̀. Góńgó ni ohun tí ẹnì kan fojú sùn, tó wá ń sapá láti lé bá. Tá a bá fẹ́ kí inú Jèhófà dùn sí wa, ohun tá à ń lépa gbọ́dọ̀ bá ìfẹ́ rẹ̀ mu. Nítorí náà, ó yẹ ká máa ronú bí Jèhófà ṣe ń ronú, ká sì máa lépa àwọn nǹkan tẹ̀mí, gẹ́gẹ́ bí Jésù ti ṣe. (Jòh. 17:4) A ó lè wá ní ayọ̀ púpọ̀, a ó sì nítẹ̀ẹ́lọ́rùn nínú iṣẹ́ ìsìn wa sí Jèhófà.—Jòh. 15:10, 11.
2 Lọ́dún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá, àwọn góńgó wo lo ti lé bá láti lè mú kí ire Ìjọba Ọlọ́run tẹ̀ síwájú? Iye àwọn tó ṣèrìbọmi fi hàn pé lóòótọ́ ní ọ̀pọ̀ àwọn ará lé góńgó tí wọ́n gbé kalẹ̀ fúnra wọn bá. Bákan náà, ẹgbẹẹgbàárùn-ún àwọn ará ló bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà déédéé àti ti olùrànlọ́wọ́. Ọ̀pọ̀ ló sì lọ sìn ní àwọn ibi tí àìní gbé pọ̀. Ní ti àwọn arákùnrin kan, pípè tá a pè wọ́n sí Bẹ́tẹ́lì tàbí sí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ ti mú kí wọ́n lé góńgó wọn bá.
3 Àwọn Góńgó Tó O Lè Gbé Kalẹ̀: Kí làwọn góńgó yíyẹ tó o lè lé bá? Kí àwọn ẹni tuntun lè ní ìtẹ̀síwájú nípa tẹ̀mí, ohun tó dára kí wọ́n fi ṣe góńgó wọn ni láti máa lọ sípàdé déédéé, kí wọ́n sì máa ṣiṣẹ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Bí o ò bá tíì máa dáhùn nípàdé déédéé, o ò ṣe fìyẹn ṣe góńgó tí wàá máa lépa? Àwọn ẹlòmíràn á jàǹfààní látinú ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti ìwádìí tó o bá ṣe, òye rẹ nípa òtítọ́ á sì túbọ̀ jinlẹ̀ sí i.—Héb. 10:24, 25.
4 Ǹjẹ́ o ti tóótun láti máa jáde òde ẹ̀rí? Ṣé o sì máa ń jáde déédéé? Ṣé o máa ń ka àwọn ìtẹ̀jáde tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde bó o ṣe ń gbà wọ́n, kó o má bàa pàdánù èyíkéyìí nínú ìtọ́ni tó wúlò tí ẹrú olóòótọ́ ń fún wa? Bí ọwọ́ rẹ bá ti tẹ àwọn góńgó wọ̀nyí, nígbà náà ṣé o ò rò pé ohun tó dára jù kó o fi ṣe góńgó rẹ báyìí ni láti ya ara rẹ sí mímọ́, kó o sì ṣe ìrìbọmi?
5 Ǹjẹ́ o ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Ǹjẹ́ o ti gbàdúrà pé kó o lè ní ọ̀kan? Ǹjẹ́ ò ń sapá láti máa ṣe ìpadàbẹ̀wò, kó o sì ṣe tán láti máa kọ́ àwọn tó o bá bá pàdé tó fífẹ̀ hàn sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lẹ́kọ̀ọ́? Bí ẹnì kan tó ò ń bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ bá ti tóótun láti máa jáde òde ẹ̀rí, ṣé ò ń kọ́ ọ bá a ṣe ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà?
6 Ǹjẹ́ o níye wákàtí tó o fẹ́ máa lépa lóṣooṣù? Àbí o tiẹ̀ ti gbìyànjú iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ rí? Bóyá ipò rẹ tiẹ̀ lè fún ọ láyè láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà déédéé, kó o sì máa lo àádọ́rin wákàtí lóṣooṣù láti wàásù ìhìn rere náà fáwọn èèyàn. Nígbà tó bá yá, wàá lè láǹfààní láti gba ẹ̀kọ́ pàtàkì ní Ilé Ẹ̀kọ́ Aṣáájú Ọ̀nà. Ó yẹ kí àwọn arákùnrin máa nàgà fún àǹfààní àtisìn gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti alàgbà.—1 Tím. 3:1.
7 Ó yẹ kí góńgó tá a bá gbé kalẹ̀ fúnra wa túbọ̀ mú ká sún mọ́ Jèhófà, kó sì fún wa láyè láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀ ní kíkún. Pọ́ọ̀lù sọ pé òun ‘ń gbàgbé àwọn ohun tí ń bẹ lẹ́yìn òun sì ń nàgà sí àwọn ohun tí ń bẹ níwájú.’ Ó wá gbà wá níyànjú pé ká lérò tó dáa nípa àwọn nǹkan tẹ̀mí tí à ń lépa, kó lè jẹ́ pé “dé àyè tí a ti tẹ̀ síwájú dé,” a ó lè “máa bá a lọ ní rírìn létòletò nínú ọ̀nà ìgbàṣiṣẹ́ kan náà yìí.”—Fílí. 3:13, 16.