Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
Báwo Ni Ọwọ́ Mi Ṣe Lè Tẹ Àwọn Àfojúsùn Mi?
ÈWO nínú àwọn nǹkan yìí ló wù ẹ́?
● Mo fẹ́ túbọ̀ dá ara mi lójú
● Mo fẹ́ ní àwọn ọ̀rẹ́ púpọ̀ sí i
● Mo fẹ́ túbọ̀ láyọ̀
Ká sòótọ́, o lè ní àwọn nǹkan mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tá a mẹ́nu bà yìí. Báwo lo ṣe lè ní in? O lè ní àwọn nǹkan mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí tó o bá ní àfojúsùn, tó o sì sapá láti jẹ́ kí ọwọ́ rẹ tẹ̀ ẹ́. Wo àwọn ohun tá a sọ tẹ̀ lé e yìí.
O lè túbọ̀ dá ara rẹ lójú Tí ọwọ́ rẹ bá tẹ àwọn àfojúsùn tí kò fi bẹ́ẹ̀ tó nǹkan, ìyẹn á jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ọwọ́ rẹ máa tẹ àwọn àfojúsùn tó tún ju ìyẹn lọ. Á túbọ̀ dá ẹ lójú pé o lè kojú àwọn ìṣòro tó máa ń jẹ yọ lójoojúmọ́, irú bí ìgbà tí àwọn ojúgbà rẹ bá fẹ́ kó o ṣe ohun tí kò dáa. Èyí á jẹ́ kí àwọn ẹlòmíì kíyè sí pé o mọ ohun tó ò ń ṣe, wọ́n á sì máa bọ̀wọ̀ fún ẹ. Ó sì lè dín ìyọlẹ́nu tí àwọn kan ń fún ẹ kù. Wọ́n tiẹ̀ lè bẹ̀rẹ̀ sí í kan sárá sí ẹ pàápàá.—Fi wé Mátíù 5:14-16.
O lè ní àwọn ọ̀rẹ́ púpọ̀ sí i Àwọn èèyàn máa ń fẹ́ láti wà pẹ̀lú àwọn tó bá ní àfojúsùn, ìyẹn àwọn tó mọ ohun tí wọ́n ń fẹ́, tí wọ́n sì ṣe tán láti ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe kí ọwọ́ wọn lè tẹ àfojúsùn náà. Bí àwọn èèyàn bá sì sún mọ́ ẹ torí àwọn àfojúsùn tó o ní, lọ́pọ̀ ìgbà irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kí ọwọ́ rẹ lè tẹ àwọn àfojúsùn náà.—Oníwàásù 4:9, 10.
O lè túbọ̀ láyọ̀ Ká sòótọ́, inú èèyàn kò lè fi bẹ́ẹ̀ dùn tó bá kàn jókòó dẹngbẹrẹ tàbí tí kò ṣe àṣeyọrí kankan nígbèésí ayé rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, tó o bá ní àwọn àfojúsùn, tí ọwọ́ rẹ sì tẹ̀ wọ́n, inú rẹ máa dùn pé ò ń ṣàṣeyọrí. Abájọ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní fi sọ pé: ‘Eré tí èmi ń sá kì í ṣe láìní ète.’ (1 Kọ́ríńtì 9:26, Ìròhìn Ayọ̀) Má sì gbàgbé pé bí àwọn àfojúsùn rẹ bá ti ṣe pàtàkì tó, bẹ́ẹ̀ ni inú rẹ ṣe máa dùn tó nígbà tí ọwọ́ rẹ bá tẹ̀ wọ́n.
Ṣé o ti ṣe tán láti ní àwọn àfojúsùn kan? Gé ojú ìwé tó wà lápá ọ̀tún kó o sì ká a, lẹ́yìn náà ṣe àwọn ohun tá a kọ síbẹ̀.a
O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn àbá tó wà níbẹ̀ máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kí ọwọ́ rẹ lè tẹ àwọn àfojúsùn tó ṣeé lé bá láàárín ọ̀sẹ̀ tàbí oṣù mélòó kan, àmọ́ ìlànà tó wà níbẹ̀ wúlò fún àwọn àfojúsùn tó máa gba ọ̀pọ̀ àkókó pẹ̀lú.
OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ
● Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kí àwọn àfojúsùn téèyàn ń lé lẹ́ẹ̀kan náà pọ̀ ju bó ṣe yẹ lọ?—Fílípì 1:10.
● Ṣé ohun tó túmọ̀ sí láti ní àfojúsùn ni pé kó o ti pinnu gbogbo ohun tó o máa ṣe ní ìgbésí ayé rẹ?—Fílípì 4:5.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17, 18]
Bí ọwọ́ rẹ ṣe lè tẹ àwọn àfojúsùn rẹ
MỌ ÀFOJÚSÙN RẸ Òwe 4:25, 26 1
“Má bẹ̀rù láti ní àwọn àfojúsùn tí kò rọrùn láti lé bá. Bí ọwọ́ àwọn kan bá ti tẹ irú àfojúsùn bẹ́ẹ̀ rí, ọwọ́ tìẹ náà lè tẹ̀ wọ́n.”—Roben.
1. Ronú nípa àwọn ohun tó o lè fi ṣe àfojúsùn. Ṣe ni kó o kàn ronú nípa oríṣiríṣi nǹkan, kó o sì kọ wọ́n sílẹ̀. Má ṣe fún un láfiyèsí ju bó ṣe yẹ lọ, ṣáà ṣe àkọsílẹ̀ ohunkóhun tó o bá ronú kàn tó o lè fi ṣe àfojúsùn rẹ. Gbìyànjú láti ṣàkọsílẹ̀ ó kéré tán nǹkan mẹ́wàá tàbí ogún.
2. Fara balẹ̀ wo àwọn ohun tó o kọ sílẹ̀. Èwo ló ṣeé ṣe kó o gbádùn jù lọ? Èwo ló ṣeé ṣe kó fún ẹ níṣòro jù lọ? Èwo ló máa mú inú rẹ dùn jù lọ bí ọwọ́ rẹ bá tẹ̀ ẹ́? Rántí pé, àfojúsùn tó dáa jù lọ ni èyí tó bá ṣe pàtàkì sí ẹ jù lọ.
3. Tò wọ́n bí wọ́n ti ṣe pàtàkì tó. Kọ́kọ́ yan àwọn àfojúsùn tí ọwọ́ rẹ máa lè tẹ̀ láàárín ọjọ́ mélòó kan. Lẹ́yìn náà, yan àwọn àfojúsùn tó máa pẹ́ díẹ̀ kí ọwọ́ rẹ tó lè tẹ̀ (ìyẹn àwọn tó máa gba ọ̀sẹ̀ tàbí oṣù mélòó kan). To àwọn àfojúsùn yẹn tẹ̀ lé ara wọn bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú èyí tó o fẹ́ kí ọwọ́ rẹ kọ́kọ́ tẹ̀.
Àpẹẹrẹ Àwọn Ohun Tó O Lè Fi Ṣe Àfojúsùn
Ọ̀rẹ́ Mo fẹ́ ní ọ̀rẹ́ kan tí kì í ṣe ojúgbà mi. Mo túbọ̀ fẹ́ sún mọ́ ọ̀rẹ́ mi àtijọ́ kan.
Ìlera Máa ṣe eré ìmárale fún ó kéré tán àádọ́rùn-ún [90] ìṣẹ́jú lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Máa rí i pé ò ń sun oorun wákàtí mẹ́jọ mọ́jú.
Iléèwé Mo fẹ́ gba máàkì púpọ̀ sí i nínú ìmọ̀ ìṣirò. Mi ò fẹ́ jí ìwé wò táwọn ọmọ kíláàsì mi bá tiẹ̀ fẹ́ kí n ṣe bẹ́ẹ̀.
Ìjọsìn Mo fẹ́ máa ka Bíbélì fún ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lójoojúmọ́. Mo fẹ́ wàásù fún ọmọ kíláàsì mi kan lọ́sẹ̀ yìí.
Múra Sílẹ̀ Òwe 21:5 2
“Ó dáa kéèyàn ní àfojúsùn, àmọ́ èèyàn tún gbọ́dọ̀ múra sílẹ̀ kí ọwọ́ rẹ̀ lè tẹ àwọn àfojúsùn náà. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ọwọ́ ò ní lè tẹ nǹkan ọ̀hún.”—Derrick.
Ṣe àwọn ohun tó tẹ̀ lé e yìí sí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àfojúsùn rẹ:
1. Ṣàkọsílẹ̀ àwọn àfojúsùn rẹ.
2. Dá ìgbà tó o fẹ́ kí ọwọ́ rẹ tẹ̀ wọ́n. Béèyàn bá ní àfojúsùn àmọ́ tí kò dá ìgbà tó fẹ́ kọ́wọ́ òun tẹ̀ ẹ́, bí àlá lásán ló máa rí!
3. Ṣètò ohun tó o fẹ́ ṣe.
4. Fi sọ́kàn pé ìṣòro lè yọjú. Kó o sì ronú nípa bó o ṣe lè yanjú àwọn ìṣòro náà.
5. Pinnu pé o ò ní jẹ́ kó sú ẹ. Pinnu pé wàá ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe kí ọwọ́ rẹ lè tẹ àfojúsùn yìí. Buwọ́ lù ú, kó o sì kọ ọjọ́ tó o buwọ́ lù ú.
Mo fẹ́ kọ́ Èdè Àwọn Adití kí n lè máa wàásù fún àwọn adití Ó pẹ́ tán ní July 1
Ohun tí màá ṣe
1. Màá ra ìwé tó ń kọ́ni lédè náà.
2. Màá máa kọ́ ọ̀rọ̀ mẹ́wàá lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.
3. Nígbà táwọn èèyàn bá ń fi Èdè Àwọn Adití sọ̀rọ̀, máà máa wò wọ́n.
4. Màá ní kí ẹnì kan tó bá mọ èdè náà dáadáa máa sọ ibi tí mo bá ti ṣe àṣìṣe.
Àwọn ìṣòro tó lè yọjú
Kò sí ẹni tó mọ Èdè Àwọn Adití ní àdúgbò mi
Bí mo ṣe lè yanjú àwọn ìṣòro náà
Màá wa fídíò tí wọ́n ṣe ní Èdè Àwọn Adití jáde látorí ìkànnì www.jw.org.
․․․․․ ․․․․․
Ìbuwọ́lùwé Déètì
Dáwọ́ Lé E! Jòhánù 13:17 3
“Téèyàn bá ní ìpínyà ọkàn, ó rọrùn láti gbàgbé ohun téèyàn fojú sùn, àfi kó o fọkàn sí àfojúsùn rẹ, kó o sì máa sapá kọ́wọ́ rẹ bàa lè tẹ̀ ẹ́.”—Erika.
Tètè bẹ̀rẹ̀. Bi ara rẹ pé, ‘Kí ni mo lè ṣe lónìí láti fi hàn pé mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í lé àfojúsùn mi?’ Òótọ́ ibẹ̀ ni pé o lè máà tíì mọ gbogbo ọ̀nà tó o máa gbé e gbà o, àmọ́ ṣáà rí i pé o dáwọ́ lé e. Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń ṣọ́ ẹ̀fúùfù kì yóò fún irúgbìn; ẹni tí ó bá sì ń wo àwọsánmà kì yóò kárúgbìn.” (Oníwàásù 11:4) Ronú nípa nǹkan tó o lè ṣe lónìí kó o sì ṣe é, ì báà tiẹ̀ jẹ́ nǹkan kékeré.
Máa ṣàyẹ̀wò àfojúsùn rẹ lójoojúmọ́. Máa rán ara rẹ létí ìdí tí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àfojúsùn náà fi ṣe pàtàkì. Máa fi àmì ✔ (tàbí kó o kọ déètì tí ọwọ́ rẹ tẹ̀ ẹ́) síwájú èyí tí ọwọ́ rẹ bá ti tẹ̀ nínú àwọn àfojúsùn náà, èyí ló máa jẹ́ kó o mọ ibi tó o dé.
Múra tán láti ṣe ìyípadà. Bó ti wù kí àwọn ohun tó o ní lọ́kàn dáa tó, ó ṣì lè gba pé kó o ṣe àwọn ìyípadà kan. Kò sóhun tó burú nínú ìyẹn. Má ṣe rin kinkin mọ́ ohun tó o ti ní lọ́kàn tẹ́lẹ̀. Ṣáà rí i pé ò ń tẹ̀ síwájú débi tí ọwọ́ rẹ á fi tẹ àfojúsùn rẹ.
Fọkàn yàwòrán. Fojú inú wò ó pé ọwọ́ rẹ ti tẹ àfojúsùn rẹ. Wò ó bíi pé o ti ṣàṣeyọrí. Lẹ́yìn náà, ronú pa dà sẹ́yìn lórí àwọn ohun tó o gbọ́dọ̀ ṣe kí ọwọ́ rẹ bàa lè tẹ ohun tó ò ń lé yẹn, kó o sì fọkàn yàwòrán ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn. Wàyí o, wò ó bíi pé o ti ń ṣe àwọn ohun tó yẹ kó o ṣe, bíi pé o ti ń ṣàṣeyọrí bí o ṣe ń gbé ìgbésẹ̀ kọ̀ọ̀kan, kó o wá ronú nípa bí inú ẹ ṣe máa dùn tó nígbà tí ọwọ́ rẹ bá ti tẹ gbogbo àfojúsùn rẹ. Ó yá, bẹ̀rẹ̀ báyìí!
[Àwòrán]
Àfojúsùn dà bí àwòrán ilé tó o fẹ́ kọ́, o gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kára kí ọwọ́ rẹ tó lè tẹ̀ ẹ́.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
OHUN TÁWỌN OJÚGBÀ Ẹ SỌ 4
“Ìrẹ̀wẹ̀sì lè bá ẹ bí o kò bá ní ohun kan tó ò ń lé tàbí tó ò ń retí. Àmọ́ tó o bá ní àwọn ohun tó o fojú sùn, tí ọwọ́ rẹ sì ń tẹ̀ wọ́n, ìyẹn á jẹ́ kó o máa láyọ̀.”—Reed.
“Má ṣe dá ara rẹ lẹ́bi, bí ọwọ́ rẹ kò bá tẹ àwọn àfojúsùn rẹ bó o ṣe fẹ́ tàbí nígbà tó o fẹ́. Bó o bá ń dá ara rẹ lẹ́bi o kò ní lè ṣàṣeyọrí. Má ṣe jẹ́ kó sú ẹ!”—Cori.
“Sún mọ́ àwọn tí ọwọ́ wọn ti tẹ àfojúsùn tó ò ń lé yìí. Wọ́n lè jẹ́ kó túbọ̀ wù ẹ́ láti máa lé àfojúsùn yẹn, tàbí kí wọ́n sọ àwọn nǹkan gidi tó o lè ṣe tí ọwọ́ rẹ á fi tẹ̀ wọ́n. Ó tún máa dáa pé kó o sọ àwọn àfojúsùn rẹ fún ìdílé rẹ, kí àwọn náà lè ràn ẹ́ lọ́wọ́.”—Julia.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Gé e
Ká a