Bọ́wọ́ Rẹ Ṣe Lè Tẹ Àwọn Àfojúsùn Rẹ Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìsìn Ọlọ́run
1. Kí ni àwọn nǹkan tí ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ tí wọ́n jẹ́ Kristẹni ń fojú sùn lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run?
1 Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́ tó jẹ́ Kristẹni, kò síyè méjì pé ìfẹ́ tó o ní sí Jèhófà àti bó o ṣe fẹ́ láti tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ Jésù pé kí gbogbo Kristẹni máa ‘wá Ìjọba Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́,’ ló mú ọ yan àwọn nǹkan tó o fi ṣe àfojúsùn nígbèésí ayé rẹ. (Mát. 6:33) Àfojúsùn rẹ lè jẹ́ láti ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ nípa sísìn bí aṣáájú-ọ̀nà tàbí láti lọ sìn níbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù tó pọ̀ sí i. Àwọn kan lè ní in lọ́kàn láti yọ̀ǹda ara wọn fún iṣẹ́ ìkọ́lé kárí ayé, láti sìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì, tàbí láti sìn bíi míṣọ́nnárì. Àwọn àfojúsùn tó ń múni láyọ̀ tó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà mà nìyẹn o!
2. Kí ló lè mú kí ọwọ́ rẹ tẹ àwọn nǹkan tó ò ń fojú sùn nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run?
2 Ohun kan tó lè jẹ́ kí ọwọ́ rẹ tẹ àwọn nǹkan tó o fojú sùn ni pé kó o kọ ọ́ sínú ìwé. Ilé Ìṣọ́ July 15, 2004, sọ pé: “Ìgbà [tó o] bá sọ èrò kan tó wà lọ́kàn [rẹ] jáde ni èrò ọ̀hún tó máa ṣe kedere táá sì ṣe pàtó. Nítorí náà, [o] lè fẹ́ láti jẹ́ kí àwọn ohun tó o fẹ́ máa lé àti ọ̀nà tó o fẹ́ gbé e gbà tí ọwọ́ rẹ fi máa tẹ̀ ẹ́ wà lákọọ́lẹ̀.” Láfikún síyẹn, àwọn àfojúsùn kan wà tó gba àkókò díẹ̀. Bó o bá ṣe ń lé àwọn wọ̀nyí bá, á jẹ́ kó o mọ bó o ṣe ń tẹ̀ síwájú tó, á sì jẹ́ kó o pọkàn pọ̀ sórí àwọn àfojúsùn tó gba àkókò tó pọ̀.
3. Mẹ́nu ba àwọn àfojúsùn tí kò gba àkókò tó lè mú kéèyàn yẹ láti ṣèrìbọmi.
3 Àwọn Àfojúsùn Tí Kò Gba Àkókò: Bó ò bá tíì ṣèrìbọmi, gbé ohun tó o ní láti ṣe tí wàá fi yẹ fún ìrìbọmi yẹ̀ wò. Ó lè jẹ́ pé ṣe lo ṣì ní láti túbọ̀ lóye àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì dáadáa. Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ohun tó yẹ kó o fi ṣe àfojúsùn rẹ ni kíkẹ́kọ̀ọ́ ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni kúnnákúnná kó o sì rí i pé o ka gbogbo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a fà yọ síbẹ̀. (1 Tím. 4:5) Ohun míì tó yẹ kó o fojú sùn ni bí wàá ṣe ka Bíbélì tán láti Jẹ́nẹ́sísì dé Ìṣípayá, bíi tàwọn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì àtàwọn akẹ́kọ̀ọ́ nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì. Lẹ́yìn tó o bá ti kà á tán, rí i pé o ṣètò tó fi jẹ́ pé ọjọ́ kan ò ní kọjá lọ láìjẹ́ pé o ka Bíbélì. (Sm. 1:2, 3) Wàá rí i pé kékeré kọ́ ni òye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó o máa ní! Ní gbogbo ìgbà tó o bá máa ka Bíbélì, rí i pé o gbàdúrà látọkànwá kó o tó bẹ̀rẹ̀ àti lẹ́yìn tó o bá parí rẹ̀. Tún máa rí i pé ò ń fi ohun tó o bá kọ́ ṣèwà hù.—Ják. 1:25.
4. Àwọn àfojúsùn tí kò gba àkókò wo ni Kristẹni kan lè máa lé, tọ́wọ́ ẹ̀ á fi tẹ àfojúsùn tó gba àkókò tó pọ̀, bí iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì tàbí dídi míṣọ́nnárì?
4 Bó o bá ti ṣèrìbọmi, nǹkan mìíràn wo lo tún lè fi ṣe àfojúsùn? Ǹjẹ́ kò ní í dára kó o túbọ̀ mọwọ́ iṣẹ́ ìwàásù sí i? Bí àpẹẹrẹ, o ò ṣe fi ṣe àfojúsùn rẹ láti di ọ̀jáfáfá nídìí lílo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá? (2 Tím. 2:15) Báwo lo ṣe lè ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà? Ní àwọn àfojúsùn tí kò gba àkókò tí ẹni tó wà lọ́jọ́ orí rẹ tó sì wà nírú ipò tó o wà lè máa lé, èyí tó máa jẹ́ kí ọwọ́ rẹ lè tẹ àfojúsùn tó gba àkókò tó pọ̀.
5. Báwo ni níní àfojúsùn tí kò gba àkókò ṣe ran arákùnrin kan lọ́wọ́ láti lọ sìn ní Bẹ́tẹ́lì?
5 Ẹnì Kan Tó Ṣàṣeyọrí: Látìgbà tí ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún kan tó ń jẹ́ Tony ti lọ wo ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ti bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa bóun á ṣe lọ sìn ní Bẹ́tẹ́lì. Ní àkókò yẹn, bó ṣe ń lo ìgbésí ayé rẹ̀ ò bójú mu rárá kò sì tíì ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Ọlọ́run. Ni Tony bá pinnu láti máa gbé níbàámu pẹ̀lú ìlànà Jèhófà, ó sì wo ìrìbọmi bí àfojúsùn kan tí ọwọ́ òun gbọ́dọ̀ tẹ̀. Ìgbà tí ọwọ́ rẹ̀ ti tẹ àfojúsùn yẹn, ó tún fi iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ṣe àfojúsùn, lẹ́yìn náà ó bẹ̀rẹ̀ sí í lé iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé, ó sì kọ déètì tó máa fẹ́ láti bẹ̀rẹ̀ sórí kàlẹ́ńdà rẹ̀. Wo bí inú ẹ̀ á ṣe dùn tó nígbà tí wọ́n pè é sí Bẹ́tẹ́lì lẹ́yìn tó ti ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà fún àwọn àkókò kan!
6. Kí ló lè mú kí ọwọ́ rẹ tẹ àwọn àfojúsùn rẹ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run?
6 Bí ìwọ náà ṣe ń sapá láti fi àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́, á jẹ́ kí ọwọ́ rẹ tẹ àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run tó ò ń fojú sùn. Fi “àwọn iṣẹ́ rẹ” síwájú Jèhófà nípasẹ̀ àdúrà kó o sì máa sapá gidigidi kí ọwọ́ rẹ lè tẹ̀ wọ́n.—Òwe 16:3; 21:5.